Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kíróníkà 31:1-21

31  Gbàrà tí wọ́n sì parí gbogbo èyí, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ tí a rí níbẹ̀ jáde lọ sí àwọn ìlú ńlá Júdà,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀+ túútúú, wọ́n sì ké àwọn òpó ọlọ́wọ̀+ lulẹ̀, wọ́n sì bi àwọn ibi gíga+ àti àwọn pẹpẹ+ wó nínú gbogbo Júdà+ àti Bẹ́ńjámínì àti ní Éfúráímù+ àti Mánásè+ títí wọ́n fi parí; lẹ́yìn èyí tí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà sí àwọn ìlú ńlá wọn, olúkúlùkù sí ohun ìní tirẹ̀.  Nígbà náà ni Hesekáyà yan ìpín+ àwọn àlùfáà àti ti àwọn ọmọ Léfì+ sí ìpín wọn, ìkọ̀ọ̀kan ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ fún àwọn àlùfáà+ àti fún àwọn ọmọ Léfì+ ní ti ọrẹ ẹbọ sísun+ àti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀+ láti máa ṣe ìránṣẹ́+ àti láti máa dúpẹ́+ àti láti máa bùyìn+ ní àwọn ẹnubodè àwọn ibùdó Jèhófà.  Ìpín kan sì wà tí ó jẹ́ ti ọba láti inú àwọn ẹrù tirẹ̀+ fún àwọn ọrẹ ẹbọ sísun,+ fún àwọn ọrẹ ẹbọ sísun ti òwúrọ̀+ àti ti ìrọ̀lẹ́, àti àwọn ọrẹ ẹbọ sísun fún àwọn sábáàtì+ pẹ̀lú àti fún àwọn òṣùpá tuntun+ àti fún àwọn àsìkò àjọyọ̀,+ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ sínú òfin Jèhófà.+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó wí fún àwọn ènìyàn náà, àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù, pé kí wọ́n pèsè ìpín àwọn àlùfáà+ àti ti àwọn ọmọ Léfì,+ kí wọ́n lè rọ̀ mọ́+ òfin Jèhófà.+  Gbàrà tí ọ̀rọ̀ náà sì jáde lọ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ mú àkọ́so ọkà,+ wáìnì tuntun,+ àti òróró+ àti oyin+ àti gbogbo èso pápá+ pọ̀ sí i, wọ́n sì mú ìdá mẹ́wàá ohun gbogbo wá lọ́pọ̀ yanturu.+  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti ti Júdà tí ń gbé àwọn ìlú ńlá Júdà,+ àní àwọn fúnra wọn mú ìdá mẹ́wàá àwọn màlúù àti àgùntàn àti ìdá mẹ́wàá àwọn ohun mímọ́ wá,+ àwọn ohun tí a sọ di mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run wọn. Wọ́n mú wọn wá, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ pèsè wọn ní òkìtì-òkìtì.  Oṣù kẹta+ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ àwọn òkìtì náà nípa fífi ipele ìsàlẹ̀ pátápátá lélẹ̀, wọ́n sì parí rẹ̀ ní oṣù keje.+  Nígbà tí Hesekáyà àti àwọn ọmọ aládé+ wá, tí wọ́n sì rí àwọn òkìtì náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi ìbùkún+ fún Jèhófà àti àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì.+  Nígbà tí ó ṣe, Hesekáyà wádìí lọ́dọ̀ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì nípa àwọn òkìtì náà.+ 10  Nígbà náà ni Asaráyà+ olórí àlùfáà tí í ṣe ará ilé Sádókù+ wí fún un, bẹ́ẹ̀ ni, ó wí pé: “Láti ìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí mú ọrẹ+ wá sínú ilé Jèhófà ni jíjẹ àjẹyó+ àti níní àṣẹ́kùsílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu ti wà;+ nítorí Jèhófà alára ti bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀,+ ohun tí ó sì ṣẹ́ kù ni ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ yìí.” 11  Látàrí èyí, Hesekáyà sọ pé kí a pèsè àwọn yàrá ìjẹun+ sílẹ̀ nínú ilé Jèhófà. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n pèsè wọn sílẹ̀. 12  Wọ́n sì ń bá a nìṣó ní mímú ọrẹ+ àti ìdá mẹ́wàá+ àti àwọn ohun mímọ́ wá nínú ìṣòtítọ́;+ Konanáyà ọmọ Léfì sì ni ó wà ní àbójútó wọn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú, Ṣíméì arákùnrin rẹ̀ sì ni igbá-kejì. 13  Jéhíélì àti Asasáyà àti Náhátì àti Ásáhélì àti Jérímótì àti Jósábádì àti Élíélì àti Isimákáyà àti Máhátì àti Bẹnáyà sì ni kọmíṣọ́nnà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Konanáyà àti Ṣíméì arákùnrin rẹ̀, nípa àṣẹ ìtọ́ni Hesekáyà Ọba, Asaráyà+ sì ni ẹni tí ń mú ipò iwájú ní ilé Ọlọ́run tòótọ́. 14  Kórè ọmọkùnrin Ímúnà ọmọ Léfì sì ni aṣọ́bodè+ níhà ìlà-oòrùn,+ òun ni ó wà ní àbójútó àwọn ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe+ ti Ọlọ́run tòótọ́, láti máa fúnni ní ọrẹ Jèhófà+ àti àwọn ohun mímọ́ jù lọ.+ 15  Abẹ́ ìdarí rẹ̀ sì ni Édẹ́nì àti Míníámínì àti Jéṣúà àti Ṣemáyà, Amaráyà àti Ṣẹkanáyà wà, nínú àwọn ìlú ńlá àwọn àlùfáà,+ ní ipò iṣẹ́ ìfọkàntánni,+ láti máa fi fún àwọn arákùnrin wọn nínú àwọn ìpín,+ lọ́gbọọgba fún ẹni ńlá àti ẹni kékeré;+ 16  yàtọ̀ sí àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọkùnrin lára wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn ìlà ìdílé+ láti ẹni ọdún mẹ́ta sókè,+ lára gbogbo àwọn tí ń wá sí ilé Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìṣe ojoojúmọ́, fún iṣẹ́ ìsìn wọn nípa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìpín wọn. 17  Èyí ni àkọsílẹ̀ orúkọ ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn ìlà ìdílé ti àwọn àlùfáà nípa ilé àwọn baba wọn+ àti ti àwọn ọmọ Léfì+ pẹ̀lú, láti ẹni ogún+ ọdún sókè, nípa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe wọn nínú ìpín wọn;+ 18  fún àkọsílẹ̀ orúkọ ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn ìlà ìdílé nínú gbogbo àwọn ọmọ wọn kéékèèké, aya wọn àti àwọn ọmọkùnrin wọn àti ọmọbìnrin wọn, fún gbogbo ìjọ, nítorí pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ ara wọn di mímọ́+ fún ohun tí ó jẹ́ mímọ́ nínú ipò iṣẹ́ ìfọkàntánni+ wọn; 19  àti fún àwọn ọmọ Áárónì,+ àwọn àlùfáà, ní àwọn pápá+ ilẹ̀ ìjẹko ti àwọn ìlú ńlá wọn. Nínú gbogbo ìlú ńlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn ọkùnrin wà tí a ti yàn nípa orúkọ wọn, láti máa fi àwọn ìpín fún olúkúlùkù ọkùnrin nínú àwọn àlùfáà àti fún gbogbo àkọsílẹ̀ orúkọ pátá ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn ìlà ìdílé nínú àwọn ọmọ Léfì. 20  Hesekáyà sì tẹ̀ síwájú láti ṣe báyìí ní gbogbo Júdà, ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó dára+ tí ó sì tọ̀nà+ tí ó sì jẹ́ òótọ́+ níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀. 21  Nínú gbogbo iṣẹ́ tí ó sì bẹ̀rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn+ ilé Ọlọ́run tòótọ́ àti nínú òfin+ àti nínú àṣẹ láti wá+ Ọlọ́run rẹ̀, gbogbo ọkàn-àyà+ rẹ̀ ni ó fi gbé ìgbésẹ̀, ó sì ṣe àṣeyọrí sí rere.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé