Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kíróníkà 30:1-27

30  Hesekáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí ránṣẹ́ sí gbogbo Ísírẹ́lì+ àti Júdà, ó tilẹ̀ kọ lẹ́tà sí Éfúráímù+ àti Mánásè,+ pé kí wọ́n wá sí ilé Jèhófà+ ní Jerúsálẹ́mù láti wá ṣe ìrékọjá+ sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.  Àmọ́ ṣá o, ọba àti àwọn ọmọ aládé+ rẹ̀ àti gbogbo ìjọ+ ní Jerúsálẹ́mù pinnu láti ṣe ìrékọjá náà ní oṣù kejì;+  nítorí wọ́n kò tíì lè ṣe é ní àkókò yẹn,+ nítorí pé ní ọwọ́ kan, iye àwọn àlùfáà+ tí ó ti sọ ara wọn di mímọ́ kò tó, ní ọwọ́ kejì, àwọn ènìyàn náà kò tíì kó ara wọn jọ sí Jerúsálẹ́mù.  Ohun náà sì tọ̀nà ní ojú ọba àti ní ojú gbogbo ìjọ.+  Nítorí náà, wọ́n pinnu láti mú kí ìpè+ náà la gbogbo Ísírẹ́lì já, láti Bíá-ṣébà+ dé Dánì,+ pé kí wọ́n wá ṣe ìrékọjá sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ní Jerúsálẹ́mù; nítorí wọn kò tíì ṣe bẹ́ẹ̀+ gẹ́gẹ́ bí ògìdìgbó ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ̀wé rẹ̀.+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn sárésáré+ lọ jákèjádò gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà pẹ̀lú àwọn lẹ́tà láti ọwọ́ ọba àti àwọn ọmọ aládé+ rẹ̀, àní ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ ọba, wí pé: “Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ padà+ sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run+ Ábúráhámù, Ísákì àti Ísírẹ́lì, kí ó lè padà sọ́dọ̀ àwọn olùsálà+ tí ó ṣẹ́ kù lára yín láti inú àtẹ́lẹwọ́ àwọn ọba Ásíríà.+  Ẹ má sì dà bí àwọn baba ńlá+ yín àti bí àwọn arákùnrin yín tí ó ṣe àìṣòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn, tí ó fi jẹ́ pé ó sọ wọ́n di ohun ìyàlẹ́nu,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń rí i.  Wàyí o, ẹ má ṣe mú ọrùn+ yín le gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá yín ti ṣe. Ẹ fi àyè fún Jèhófà,+ ẹ sì wá sínú ibùjọsìn+ rẹ̀, èyí tí ó ti sọ di mímọ́+ fún àkókò tí ó lọ kánrin kí ẹ sì máa sin+ Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ìbínú rẹ̀ jíjófòfò+ lè yí padà kúrò lọ́dọ̀ yín.  Nítorí pé nígbà tí ẹ bá padà+ sọ́dọ̀ Jèhófà, àwọn arákùnrin yín àti àwọn ọmọ yín yóò jẹ́ àwọn tí a fi àánú+ hàn sí níwájú àwọn tí ó mú wọn ní òǹdè, a ó sì yọ̀ǹda fún wọn láti padà sí ilẹ̀ yìí;+ nítorí Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ olóore ọ̀fẹ́+ àti aláàánú,+ òun kì yóò sì yí ojú kúrò lọ́dọ̀ yín bí ẹ̀yin bá padà sọ́dọ̀ rẹ̀.”+ 10  Bẹ́ẹ̀ ni àwọn sárésáré+ ń bá a lọ, tí wọ́n ń kọjá lọ láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá jákèjádò ilẹ̀ Éfúráímù+ àti Mánásè, àní dé Sébúlúnì; ṣùgbọ́n wọ́n ń sọ̀rọ̀ sí wọn ṣáá lọ́nà ìfiniṣẹlẹ́yà, wọ́n sì ń fi wọ́n ṣẹ̀sín.+ 11  Kìkì àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan+ láti Áṣérì àti Mánásè àti láti Sébúlúnì ni ó rẹ ara wọn sílẹ̀+ tí wọ́n fi wá sí Jerúsálẹ́mù. 12  Ọwọ́ Ọlọ́run tòótọ́ sì wà ní Júdà pẹ̀lú láti fún wọn ní ọkàn-àyà+ kan ṣoṣo láti pa àṣẹ+ ọba àti ti àwọn ọmọ aládé mọ́ nínú ọ̀ràn Jèhófà.+ 13  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kó ara wọn jọpọ̀ sí Jerúsálẹ́mù,+ àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ níye, láti ṣe àjọyọ̀+ àwọn àkàrà aláìwú ní oṣù kejì,+ ìjọ tí ó jẹ́ ògìdìgbó púpọ̀ gan-an. 14  Nígbà náà ni wọ́n dìde, wọ́n sì mú àwọn pẹpẹ+ tí ń bẹ ní Jerúsálẹ́mù kúrò, gbogbo àwọn pẹpẹ tùràrí+ sì ni wọ́n mú kúrò lẹ́yìn náà, wọ́n sì sọ wọ́n sínú àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kídírónì.+ 15  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n pa ẹran ẹbọ ìrékọjá+ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì; àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì pàápàá ni a sì ti tẹ́ lógo, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n sọ ara wọn di mímọ́,+ wọ́n sì mú àwọn ọrẹ ẹbọ sísun wá sí ilé Jèhófà. 16  Wọ́n sì ń bá a nìṣó ní dídúró+ ní ipò wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àfilélẹ̀ wọn, ní ìbámu pẹ̀lú òfin Mósè ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́, àwọn àlùfáà+ ń wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà tí wọ́n gbà ní ọwọ́ àwọn ọmọ Léfì. 17  Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó wà nínú ìjọ náà tí kò tíì sọ ara wọn di mímọ́; àwọn ọmọ Léfì+ sì ni ó wà ní àbójútó pípa àwọn ẹran ẹbọ ìrékọjá+ fún gbogbo àwọn tí kò mọ́, láti sọ wọ́n di mímọ́ fún Jèhófà. 18  Nítorí iye àwọn ènìyàn púpọ̀ ní ń bẹ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti inú Éfúráímù+ àti Mánásè,+ Ísákárì àti Sébúlúnì,+ tí kò tíì wẹ ara wọn mọ́,+ nítorí wọn kò jẹ ìrékọjá ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ̀wé rẹ̀;+ ṣùgbọ́n Hesekáyà gbàdúrà fún wọn+ pé: “Kí Jèhófà olóore+ fi àyè ìyọ̀ǹda sílẹ̀ fún 19  olúkúlùkù tí ó ti múra ọkàn-àyà+ rẹ̀ sílẹ̀ láti wá Ọlọ́run tòótọ́, Jèhófà, Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láìsí ìwẹ̀mọ́gaara fún ohun tí ó jẹ́ mímọ́.”+ 20  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jèhófà fetí sí Hesekáyà, ó sì mú àwọn ènìyàn náà lára dá.+ 21  Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí a rí ní Jerúsálẹ́mù fi ayọ̀ yíyọ̀+ ńláǹlà ṣe àjọyọ̀+ àwọn àkàrà aláìwú ní ọjọ́ méje; àwọn ọmọ Léfì+ àti àwọn àlùfáà+ sì ń fi àwọn ohun èlò orin olóhùn gooro mú ìyìn wá fún Jèhófà lójoojúmọ́, àní fún Jèhófà.+ 22  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Hesekáyà bá ọkàn-àyà+ gbogbo àwọn ọmọ Léfì tí ń fi ọgbọ́n inú tí ó dára púpọ̀ gbé ìgbésẹ̀ fún Jèhófà sọ̀rọ̀.+ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ àsè tí a yàn kalẹ̀ náà fún ọjọ́ méje,+ wọ́n ń rú àwọn ẹbọ ìdàpọ̀,+ wọ́n sì ń ṣe ìjẹ́wọ́+ fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn. 23  Nígbà náà ni gbogbo ìjọ pinnu+ láti ṣe é fún ọjọ́ méje sí i,+ bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ṣe é fún ọjọ́ méje pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀. 24  Nítorí Hesekáyà ọba Júdà alára fi ẹgbẹ̀rún akọ màlúù àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin àgùntàn ṣe ìtọrẹ+ fún ìjọ náà, àwọn ọmọ aládé+ alára sì fi ẹgbẹ̀rún akọ màlúù àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àgùntàn ṣe ìtọrẹ fún ìjọ náà; iye púpọ̀ àwọn àlùfáà+ sì ń bá a nìṣó ní sísọ ara wọn di mímọ́. 25  Gbogbo ìjọ Júdà+ àti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì+ àti gbogbo ìjọ tí ó wá láti Ísírẹ́lì+ àti àwọn àtìpó+ tí ó wá láti ilẹ̀ Ísírẹ́lì+ àti àwọn tí ń gbé ní Júdà sì ń bá a lọ ní yíyọ̀.+ 26  Ayọ̀ yíyọ̀ ńláǹlà sì wá wà ní Jerúsálẹ́mù, nítorí pé láti ọjọ́ Sólómọ́nì+ ọmọkùnrin Dáfídì ọba Ísírẹ́lì kò sí ọ̀kan bí èyí ní Jerúsálẹ́mù.+ 27  Níkẹyìn, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, dìde dúró, wọ́n sì súre+ fún àwọn ènìyàn náà; a sì fetí sí ohùn wọn, tí ó fi jẹ́ pé àdúrà wọ́n dé ibùgbé rẹ̀ mímọ́, ní ọ̀run.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé