Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kíróníkà 3:1-17

3  Níkẹyìn, Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé Jèhófà+ sí Jerúsálẹ́mù, sórí Òkè Ńlá Móráyà,+ níbi tí [Jèhófà] ti fara han Dáfídì baba rẹ̀,+ ní ibi tí Dáfídì ti pèsè sílẹ̀ ní ilẹ̀ ìpakà Ọ́nánì+ ará Jébúsì.  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́lé ní oṣù kejì ní ọjọ́ kejì, ní ọdún kẹrin ìgbà ìjọba rẹ̀.+  Nǹkan wọ̀nyí sì ni Sólómọ́nì fi lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún kíkọ́ ilé Ọlọ́run tòótọ́, gígùn rẹ̀ ní ìgbọ̀nwọ́-ìgbọ̀nwọ́, ní ìbámu pẹ̀lú ìwọ̀n àtijọ́ jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́.+  Gọ̀bì+ tí ó sì wà ní iwájú gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní iwájú fífẹ̀ ilé náà, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́fà; ó sì tẹ̀ síwájú láti fi ògidì wúrà bò ó nínú.  Ó sì fi igi júnípà bo ilé ńlá+ náà, lẹ́yìn èyí tí ó fi wúrà+ dáradára bò ó, lẹ́yìn náà ni ó mú àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ+ àti ẹ̀wọ̀n+ wá sára rẹ̀.  Síwájú sí i, ó fi òkúta iyebíye bo ilé náà fún ẹwà;+ wúrà+ náà sì jẹ́ wúrà láti ilẹ̀ wúrà.  Ó sì ń bá a lọ láti fi wúrà+ bo ilé náà, àwọn igi ìrólé, àwọn ibi àbáwọlé àti àwọn ògiri rẹ̀ àti àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀; ó sì fín àwọn kérúbù sára àwọn ògiri+ náà.  Ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣe ilé Ibi Mímọ́ Jù Lọ,+ gígùn rẹ̀ ní ìfiwéra pẹ̀lú fífẹ̀ ilé náà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ òun tìkára rẹ̀ sì jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́;+ lẹ́yìn náà ni ó fi wúrà dáradára bò ó tí ó tó ẹgbẹ̀ta tálẹ́ńtì.  Ìwọ̀n àwọn ìṣó+ sì jẹ́ àádọ́ta ṣékélì wúrà; ó sì fi wúrà bo àwọn ìyẹ̀wù òrùlé. 10  Lẹ́yìn náà, ó ṣe kérúbù méjì+ sínú ilé Ibi Mímọ́ Jù Lọ ní iṣẹ́ ọnà ère, ó sì fi wúrà+ bò wọ́n. 11  Ní ti ìyẹ́ apá àwọn kérúbù+ náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ìyẹ́ apá kan tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún kan ògiri ilé náà, ìyẹ́ apá kejì tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún sì kan ìyẹ́ apá kérúbù kejì.+ 12  Ìyẹ́ apá kérúbù kan tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún kan ògiri ilé náà, ìyẹ́ apá kejì tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún sì wà ní ìfarakanra pẹ̀lú ìyẹ́ apá kérúbù+ kejì. 13  Ìyẹ́ apá kérúbù wọ̀nyí nà jáde ní ogún ìgbọ̀nwọ́; wọ́n sì dúró lórí ẹsẹ̀ wọn ní dídojúkọ ìhà inú. 14  Síwájú sí i, ó ṣe aṣọ ìkélé+ fọ́nrán òwú+ aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa àti pípọ́n dòdò pa láró àti aṣọ híhun àtàtà, ó sì ṣiṣẹ́ ọnà àwọn kérúbù sí i lára.+ 15  Lẹ́yìn náà ni ó ṣe ọwọ̀n méjì,+ tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùndínlógójì ní gígùn síwájú ilé náà, ọpọ́n+ tí ó wà ní orí ọ̀kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. 16  Síwájú sí i, ó ṣe àwọn ẹ̀wọ̀n+ ní àrà ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn, ó sì fi wọ́n sí orí àwọn ọwọ̀n náà, ó sì ṣe ọgọ́rùn-ún pómégíránétì,+ ó sì fi wọ́n sára àwọn ẹ̀wọ̀n náà. 17  Ó sì tẹ̀ síwájú láti gbé àwọn ọwọ̀n náà ró ní iwájú tẹ́ńpìlì, ọ̀kan sí ọ̀tún àti ọ̀kan sí òsì, lẹ́yìn èyí tí ó pe orúkọ ti apá ọ̀tún ní Jákínì àti orúkọ ti apá òsì ní Bóásì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé