Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kíróníkà 29:1-36

29  Hesekáyà+ di ọba ní ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Ábíjà ọmọbìnrin Sekaráyà.+  Ó sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà,+ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ṣe.+  Òun fúnra rẹ̀, ní ọdún kìíní ìgbà ìjọba rẹ̀, ní oṣù kìíní ni ó ṣí àwọn ilẹ̀kùn ilé Jèhófà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tún wọn ṣe.+  Nígbà náà ni ó mú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì wá, ó sì kó wọn jọ sí ibi gbayawu+ ní ìhà ìlà-oòrùn.  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún wọn pé: “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin ọmọ Léfì. Nísinsìnyí, ẹ sọ ara yín di mímọ́,+ ẹ sì sọ ilé Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín di mímọ́, ẹ sì mú ohun ìdọ̀tí jáde kúrò nínú ibi mímọ́.+  Nítorí àwọn baba wa ti ṣe àìṣòótọ́,+ wọ́n sì ti ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà Ọlọ́run wa,+ tí ó fi jẹ́ pé wọ́n fi í sílẹ̀+ tí wọ́n sì yí ojú wọn kúrò níbi àgọ́ ìjọsìn Jèhófà+ tí wọ́n sì kọ ẹ̀yìn ọrùn sí i.  Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n ti àwọn ilẹ̀kùn gọ̀bì,+ wọ́n sì mú àwọn fìtílà wà ní pípa,+ wọn kò sì sun tùràrí,+ wọn kò si rú ẹbọ sísun ní ibi mímọ́ sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+  Ìkannú Jèhófà+ sì wá wà sí Júdà àti Jerúsálẹ́mù, tí ó fi jẹ́ pé ó sọ wọ́n di ohun amúniwárìrì,+ ohun ìyàlẹ́nu+ àti okùnfà fún sísúfèé,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń fi ojú ara yín rí i.  Sì kíyè sí i, àwọn baba ńlá wa ti ipa idà ṣubú,+ àwọn ọmọkùnrin wa àti ọmọbìnrin wa àti aya wa sì wà ní oko òǹdè nítorí èyí.+ 10  Wàyí o, ó wà ní góńgó ọkàn-àyà mi láti bá Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú,+ kí ìbínú rẹ̀ jíjófòfò lè yí padà kúrò lọ́dọ̀ wa. 11  Wàyí o, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má jọ̀wọ́ ara yín fún ìsinmi,+ nítorí ẹ̀yin ni Jèhófà ti yàn láti máa dúró níwájú rẹ̀ láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un+ àti láti máa bá a lọ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ rẹ̀+ àti olùrú èéfín ẹbọ.”+ 12  Látàrí ìyẹn, àwọn ọmọ Léfì+ dìde, Máhátì ọmọkùnrin Ámásáì àti Jóẹ́lì ọmọkùnrin Asaráyà, láti inú àwọn ọmọkùnrin lára àwọn ọmọ Kóhátì;+ àti láti inú àwọn ọmọ Mérárì,+ Kíṣì ọmọkùnrin Ábídì àti Asaráyà ọmọkùnrin Jéhálélélì; àti láti inú àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì,+ Jóà ọmọkùnrin Símà àti Édẹ́nì ọmọkùnrin Jóà; 13  àti láti inú àwọn ọmọ Élísáfánì,+ Ṣímúrì àti Júẹ́lì; àti láti inú àwọn ọmọ Ásáfù,+ Sekaráyà àti Matanáyà; 14  àti láti inú àwọn ọmọ Hémánì,+ Jéhíélì àti Ṣíméì; àti láti inú àwọn ọmọ Jédútúnì,+ Ṣemáyà àti Úsíélì. 15  Nígbà náà ni wọ́n kó àwọn arákùnrin wọn jọpọ̀, wọ́n sì sọ ara wọn di mímọ́,+ wọ́n sì wá ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ ọba nípa ọ̀rọ̀+ Jèhófà, láti fọ+ ilé Jèhófà mọ́. 16  Wàyí o, àwọn àlùfáà wá sínú ilé Jèhófà láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́, wọ́n sì kó gbogbo ohun àìmọ́ tí wọ́n rí nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà jáde sí àgbàlá+ ilé Jèhófà. Ẹ̀wẹ̀, àwọn ọmọ Léfì gbà á láti kó o jáde lọ sí àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kídírónì+ lóde. 17  Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ ìsọdimímọ́ nìyẹn ní ọjọ́ kìíní oṣù kìíní, àti ní ọjọ́ kẹjọ oṣù náà, wọ́n dé ibi gọ̀bì+ Jèhófà; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi ọjọ́ mẹ́jọ sọ ilé Jèhófà di mímọ́, wọ́n sì ṣe tán ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kìíní.+ 18  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n wọlé tọ Hesekáyà Ọba wá, wọ́n sì wí pé: “A ti fọ gbogbo ilé Jèhófà mọ́, pẹpẹ+ ọrẹ ẹbọ sísun àti gbogbo nǹkan èlò+ rẹ̀, àti tábìlì+ búrẹ́dì onípele àti gbogbo nǹkan èlò rẹ̀.+ 19  Gbogbo nǹkan èlò+ tí Áhásì Ọba+ ti kó kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ní ìgbà ìjọba rẹ̀ nínú ìwà àìṣòótọ́+ rẹ̀, ni a ti pèsè sílẹ̀, a sì ti sọ wọ́n di mímọ́;+ sì kíyè sí i, wọ́n ń bẹ níwájú pẹpẹ Jèhófà.” 20  Hesekáyà Ọba+ sì bẹ̀rẹ̀ sí dìde ní kùtùkùtù,+ ó sì kó àwọn ọmọ aládé+ ìlú ńlá náà jọpọ̀, ó sì gòkè lọ sí ilé Jèhófà. 21  Wọ́n sì mú akọ màlúù méje+ àti àgbò méje àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje àti akọ ewúrẹ́ méje wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ fún ìjọba náà àti fún ibùjọsìn àti fún Júdà. Nítorí náà, ó sọ fún àwọn ọmọ Áárónì àwọn àlùfáà+ pé kí wọ́n fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ Jèhófà. 22  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n pa+ àwọn màlúù náà, àwọn àlùfáà sì gba ẹ̀jẹ̀+ wọn, wọ́n sì wọ́n+ ọn sórí pẹpẹ; lẹ́yìn èyí tí wọ́n pa àwọn àgbò náà,+ wọ́n sì wọ́n ẹ̀jẹ̀+ wọn sórí pẹpẹ, wọ́n sì pa àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn náà, wọ́n sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn sórí pẹpẹ. 23  Nígbà náà ni wọ́n mú àwọn akọ ewúrẹ́+ ti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ sún mọ́ iwájú ọba àti ìjọ, wọ́n sì gbé ọwọ́ wọn lé wọn.+ 24  Wàyí o, àwọn àlùfáà pa wọ́n, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lórí pẹpẹ, láti ṣe ètùtù fún gbogbo Ísírẹ́lì;+ nítorí pé gbogbo Ísírẹ́lì+ ni ọba sọ pé kí+ ọrẹ ẹbọ sísun náà àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà wà fún. 25  Láàárín àkókò náà, ó mú kí a yan àwọn ọmọ Léfì+ sí ilé Jèhófà, pẹ̀lú aro,+ pẹ̀lú àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín+ àti pẹ̀lú háàpù,+ nípa àṣẹ Dáfídì+ àti ti Gádì+ olùríran fún ọba àti ti Nátánì+ wòlíì, nítorí pé àṣẹ náà jẹ́ láti ọwọ́ Jèhófà nípasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀.+ 26  Nítorí náà, àwọn ọmọ Léfì ń bá a nìṣó ní dídúró ti àwọn ti àwọn ohun èlò orin+ ti Dáfídì, àti àwọn àlùfáà bákan náà ti àwọn ti kàkàkí.+ 27  Nígbà náà ni Hesekáyà sọ pé kí a rú ẹbọ sísun náà lórí pẹpẹ; ní àkókò tí ọrẹ ẹbọ sísun náà sì bẹ̀rẹ̀, orin+ Jèhófà bẹ̀rẹ̀ àti kàkàkí pẹ̀lú, àní lábẹ́ ìdarí àwọn ohun èlò orin ti Dáfídì ọba Ísírẹ́lì. 28  Gbogbo ìjọ sì ń tẹrí ba+ bí orin náà ti ń dún lọ rére,+ tí àwọn kàkàkí sì ń ró kíkankíkan—gbogbo èyí ń ṣẹlẹ̀ títí ọrẹ ẹbọ sísun náà fi parí. 29  Gbàrà tí wọ́n sì parí fífi í rúbọ, ọba àti gbogbo àwọn tí a rí pẹ̀lú rẹ̀ tẹrí ba mọ́lẹ̀, wọ́n sì wólẹ̀.+ 30  Wàyí o, Hesekáyà Ọba àti àwọn ọmọ aládé+ sọ fún àwọn ọmọ Léfì pé kí wọ́n fi àwọn ọ̀rọ̀ Dáfídì+ àti ti Ásáfù+ olùríran yin Jèhófà. Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bu ìyìn, àní pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀,+ wọ́n sì ń tẹ̀ ba, wọ́n sì ń wólẹ̀.+ 31  Níkẹyìn, Hesekáyà dáhùn, ó sì wí pé: “Wàyí o, ẹ ti fi agbára kún+ ọwọ́ yín fún Jèhófà. Ẹ sún mọ́ tòsí, ẹ sì mú àwọn ẹbọ+ àti àwọn ẹbọ ìdúpẹ́+ wá sí ilé Jèhófà.” Ìjọ sì bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ẹbọ àti àwọn ẹbọ ìdúpẹ́ wá, olúkúlùkù tí ọkàn-àyà rẹ̀ múra tán sì mú àwọn ọrẹ ẹbọ+ sísun wá pẹ̀lú. 32  Iye ọrẹ ẹbọ sísun tí ìjọ mú wá sì jẹ́ àádọ́rin màlúù, ọgọ́rùn-ún àgbò, igba akọ ọ̀dọ́ àgùntàn—gbogbo ìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Jèhófà;+ 33  àti ọrẹ ẹbọ mímọ́ pẹ̀lú, ẹgbẹ̀ta màlúù àti ẹgbẹ̀ẹ́dógún agbo ẹran. 34  Kìkì pé àwọn àlùfáà+ kéré jù níye, wọn kò sì lè bó gbogbo ọrẹ ẹbọ sísun náà láwọ.+ Nítorí náà, àwọn arákùnrin+ wọn tí í ṣe àwọn ọmọ Léfì ràn wọ́n lọ́wọ́ títí iṣẹ́ náà fi parí+ àti títí àwọn àlùfáà fi lè sọ ara wọn di mímọ́, nítorí àwọn ọmọ Léfì jẹ́ adúróṣánṣán+ ní ọkàn-àyà ju àwọn àlùfáà lọ ní ti sísọ ara wọn di mímọ́.+ 35  Àti, pẹ̀lú, àwọn ọrẹ ẹbọ sísun+ náà jẹ́ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pẹ̀lú àwọn ibi ọlọ́ràá+ ti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀+ àti pẹ̀lú àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ fún àwọn ọrẹ ẹbọ sísun. Bí a ṣe múra iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà sílẹ̀ nìyẹn.+ 36  Nítorí náà, Hesekáyà àti gbogbo àwọn ènìyàn náà yọ̀ lórí òtítọ́ náà pé Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe ìpèsèsílẹ̀ fún àwọn ènìyàn náà,+ nítorí pé lójijì ni nǹkan náà ṣẹlẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé