Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kíróníkà 28:1-27

28  Ẹni ogún ọdún ni Áhásì+ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù,+ kò sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀.+  Ṣùgbọ́n ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì,+ ó tilẹ̀ ṣe ère dídà+ àwọn Báálì.+  Òun fúnra rẹ̀ sì rú èéfín ẹbọ+ ní àfonífojì ọmọ Hínómù,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sun àwọn ọmọ+ tirẹ̀ nínú iná, gẹ́gẹ́ bí àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí+ ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+  Ó sì ń rúbọ déédéé,+ ó sì ń rú èéfín ẹbọ lórí àwọn ibi gíga+ àti lórí àwọn òkè kéékèèké+ àti lábẹ́ gbogbo onírúurú igi tí ó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀.+  Nítorí náà, Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ fi í lé ọba Síríà+ lọ́wọ́,+ tí ó fi jẹ́ pé wọ́n kọlù ú, wọ́n sì kó iye àwọn òǹdè púpọ̀ rẹpẹtẹ lọ lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá sí Damásíkù.+ A sì tún fi í lé ọba Ísírẹ́lì+ lọ́wọ́, tí ó fi jẹ́ pé ó fi ìpakúpa rẹpẹtẹ kọlù ú.  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Pékà+ ọmọkùnrin Remaláyà+ pa ọ̀kẹ́ mẹ́fà ní Júdà ní ọjọ́ kan, gbogbo akíkanjú ọkùnrin, nítorí fífi tí wọ́n fi Jèhófà+ Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn sílẹ̀.  Síwájú sí i, Síkírì, alágbára ńlá ọkùnrin, láti inú Éfúráímù,+ pa Maaseáyà ọmọkùnrin ọba àti Ásíríkámù aṣáájú agbo ilé àti Ẹlikánà ẹni tí ó tẹ̀ lé ọba.  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá lára àwọn arákùnrin wọn ní òǹdè, àwọn obìnrin, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin; pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìfiṣèjẹ lọ́dọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí ohun tí a piyẹ́, lẹ́yìn èyí tí wọ́n kó àwọn ohun ìfiṣèjẹ náà wá sí Samáríà.+  Wòlíì kan báyìí tí ó jẹ́ ti Jèhófà sì wà níbẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ódédì. Nítorí náà, ó jáde lọ síwájú ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń bọ̀ ní Samáríà, ó sì wí fún wọn pé: “Wò ó! Nítorí ìhónú+ Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín sí Júdà ni ó ṣe fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, tí ó fi jẹ́ pé ẹ fi ìhónú+ tí ó lọ títí dé ọ̀run+ ṣe pípa láàárín wọn. 10  Wàyí o, àwọn ọmọ Júdà àti ti Jerúsálẹ́mù ni ẹ ń ronú láti rẹ̀ sílẹ̀ di ìránṣẹ́kùnrin+ àti ìránṣẹ́bìnrin fún ara yín. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀ràn ẹ̀bi lòdì sí Jèhófà Ọlọ́run yín kò ha sí lọ́rùn ẹ̀yin fúnra yín bí? 11  Wàyí o, ẹ fetí sí mi kí ẹ sì dá àwọn òǹdè tí ẹ kó láti inú àwọn arákùnrin+ yín padà, nítorí ìbínú jíjófòfò Jèhófà ń bẹ lòdì sí yín.”+ 12  Látàrí ìyẹn, àwọn ọkùnrin kan lára àwọn olórí+ àwọn ọmọ Éfúráímù,+ Asaráyà ọmọkùnrin Jèhóhánánì, Berekáyà ọmọkùnrin Méṣílémótì àti Jehisikáyà ọmọkùnrin Ṣálúmù àti Ámásà ọmọkùnrin Hádíláì, dìde sí àwọn tí ń wọlé bọ̀ láti ibi ìgbétáásì ológun náà, 13  wọ́n sì wí fún wọn pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ kó àwọn òǹdè náà wọ ìhín, nítorí yóò yọrí sí ẹ̀bi lòdì sí Jèhófà ní ìhà ọ̀dọ̀ wa. Ẹ ń ronú àtifikún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti ẹ̀bi wa, nítorí ọ̀pọ̀ yanturu ni ẹ̀bi wa,+ ìbínú jíjófòfò+ sì ń bẹ lòdì sí Ísírẹ́lì.” 14  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ọkùnrin tí ó dìhámọ́ra+ fi àwọn òǹdè+ náà àti àwọn ohun tí a piyẹ́ sílẹ̀ níwájú àwọn ọmọ aládé+ àti gbogbo ìjọ. 15  Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin tí a tọ́ka sí nípa orúkọ+ wọn dìde, wọ́n sì mú àwọn òǹdè náà, wọ́n sì fi aṣọ wọ gbogbo àwọn tí ó wà ní ìhòòhò nínú wọn láti inú àwọn ohun ìfiṣèjẹ náà. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi aṣọ wọ̀ wọ́n,+ wọ́n sì fún wọn ní sálúbàtà, wọ́n sì bọ́ wọn,+ wọ́n sì fún wọn ní ohun mímu,+ wọ́n sì fi gírísì pa wọ́n lára. Síwájú sí i, ní ti ẹnikẹ́ni tí ń ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n, wọ́n fi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gbé+ wọn, wọ́n sì gbé wọn wá sí Jẹ́ríkò,+ ìlú ńlá onígi ọ̀pẹ,+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin wọn. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n padà sí Samáríà.+ 16  Àkókò yẹn ni Áhásì Ọba+ ránṣẹ́ sí àwọn ọba Ásíríà+ pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́. 17  Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn ọmọ Édómù+ wọlé wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá Júdà balẹ̀, wọ́n sì kó àwọn òǹdè lọ. 18  Ní ti àwọn Filísínì,+ wọ́n gbé sùnmọ̀mí wá sí àwọn ìlú ńlá Ṣẹ́fẹ́là+ àti Négébù+ ti Júdà, wọ́n sì gba Bẹti-ṣémẹ́ṣì+ àti Áíjálónì+ àti Gédérótì+ àti Sókò+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti Tímúnà+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti Gímúsò àti àwọn àrọko rẹ̀; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé níbẹ̀. 19  Nítorí Jèhófà rẹ Júdà sílẹ̀+ ní tìtorí Áhásì ọba Ísírẹ́lì, nítorí tí ó jẹ́ kí àìníjàánu gbèèràn ní Júdà,+ híhu ìwà àìṣòótọ́ ńláǹlà sí Jèhófà sì ń bẹ. 20  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Tiliga-pílínésà+ ọba Ásíríà wá láti gbéjà kò ó, ó sì kó wàhálà+ bá a, kò sì fún un lókun. 21  Nítorí tí Áhásì kó àwọn ohun ìní ilé Jèhófà+ àti ilé ọba+ àti ti àwọn ọmọ aládé,+ ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ẹ̀bùn fún ọba Ásíríà;+ ṣùgbọ́n èyí kò ṣe ìrànwọ́ kankan fún un. 22  Bí ó ti wù kí ó rí, ní àkókò tí ó ń kó wàhálà bá a, ṣe ni ó tún túbọ̀ ń ṣe àìṣòótọ́ sí Jèhófà, èyíinì ni pé, Áhásì Ọba ṣe bẹ́ẹ̀.+ 23  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rúbọ sí àwọn ọlọ́run+ Damásíkù+ tí ń kọlù ú, ó sì tẹ̀ síwájú láti wí pé: “Nítorí pé àwọn ọlọ́run àwọn ọba Síríà ń ràn wọ́n lọ́wọ́,+ àwọn ni èmi yóò rúbọ sí kí wọ́n lè ràn mí lọ́wọ́.”+ Okùnfà fún mímú kí òun àti gbogbo Ísírẹ́lì kọsẹ̀ sì ni wọ́n dà fún un.+ 24  Síwájú sí i, Áhásì kó àwọn nǹkan èlò+ ilé Ọlọ́run tòótọ́ jọpọ̀, ó sì ké àwọn nǹkan èlò ilé Ọlọ́run tòótọ́+ sí wẹ́wẹ́, ó sì ti àwọn ilẹ̀kùn+ ilé Jèhófà, ó sì ṣe àwọn pẹpẹ fún ara rẹ̀ ní gbogbo igun ọ̀nà ní Jerúsálẹ́mù.+ 25  Ó sì ṣe àwọn ibi gíga+ fún rírú èéfín ẹbọ sí àwọn ọlọ́run mìíràn+ sí gbogbo àwọn ìlú ńlá, àní àwọn ìlú ńlá Júdà, tí ó fi jẹ́ pé ó mú Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀ bínú.+ 26  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí rẹ̀+ àti gbogbo àwọn ọ̀nà rẹ̀, ti àkọ́kọ́ àti ti ìkẹyìn, ibẹ̀ ni a kọ wọ́n sí nínú Ìwé+ Àwọn Ọba Júdà àti ti Ísírẹ́lì. 27  Níkẹyìn, Áhásì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí ìlú ńlá náà, sí Jerúsálẹ́mù, nítorí wọn kò gbé e wá sínú àwọn ibi ìsìnkú àwọn ọba Ísírẹ́lì.+ Hesekáyà ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé