Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kíróníkà 27:1-9

27  Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni Jótámù+ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jérúṣà+ ọmọbìnrin Sádókù.  Ó sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà,+ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Ùsáyà baba rẹ̀ ṣe.+ Kìkì pé kò gbógun ti tẹ́ńpìlì Jèhófà.+ Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ènìyàn náà ṣì ń gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun.+  Òun ni ó kọ́ ẹnubodè+ apá òkè ti ilé Jèhófà, àti sórí ògiri Ófélì,+ ó kọ́ púpọ̀ gan-an.  Ó sì kọ́ àwọn ìlú ńlá+ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Júdà,+ ó sì kọ́ àwọn ibi olódi+ àti àwọn ilé gogoro+ sínú àwọn igbó igi.+  Òun alára sì bá ọba àwọn ọmọ Ámónì+ jagun, ó sì lágbára jù wọ́n lọ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ní ọdún yẹn, àwọn ọmọ Ámónì fún un ní ọgọ́rùn-ún tálẹ́ńtì fàdákà àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá òṣùwọ̀n kọ́ọ̀+ àlìkámà+ àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ti ọkà bálì.+ Èyí ni ohun tí àwọn ọmọ Ámónì san fún un, ní ọdún kejì àti ìkẹta pẹ̀lú.+  Bẹ́ẹ̀ ni Jótámù ń bá a nìṣó ní fífún ara rẹ̀ lókun, nítorí ó pèsè àwọn ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.+  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Jótámù+ àti gbogbo àwọn ogun rẹ̀ àti àwọn ọ̀nà rẹ̀, ibẹ̀ ni a kọ wọ́n sí nínú Ìwé+ Àwọn Ọba Ísírẹ́lì àti ti Júdà.  Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni ó jẹ́ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù.+  Níkẹyìn, Jótámù dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ wọ́n sì sin ín sí Ìlú Ńlá Dáfídì.+ Áhásì+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé