Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kíróníkà 25:1-28

25  Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni Amasááyà+ nígbà tí ó di ọba, ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jèhóádánì+ ti Jerúsálẹ́mù.  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà,+ kìkì pé kì í ṣe pẹ̀lú ọkàn-àyà pípé pérépéré.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ìjọba di alágbára lọ́wọ́ rẹ̀, ní kánmọ́kánmọ́, ó pa+ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀+ tí ó ṣá baba rẹ̀ ọba balẹ̀.+  Kò sì fi ikú pa àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n ó ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú òfin, sínú ìwé Mósè,+ èyí tí Jèhófà pa láṣẹ, pé: “Àwọn baba kì yóò kú nítorí àwọn ọmọ,+ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ kì yóò kú nítorí àwọn baba;+ ṣùgbọ́n kí wọ́n kú, olúkúlùkù nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀.”+  Amasááyà sì tẹ̀ síwájú láti kó Júdà jọpọ̀, ó sì mú kí wọ́n dúró ní ìbámu pẹ̀lú ilé àwọn baba ńlá,+ sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún+ àti sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ fún gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí forúkọ wọn sílẹ̀ láti ẹni ogún+ ọdún sókè, níkẹyìn, ó rí i pé wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ààyò ọkùnrin tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun, tí ń lo aṣóró+ àti apata ńlá.+  Síwájú sí i, ó fi ọgọ́rùn-ún tálẹ́ńtì fàdákà háyà ọ̀kẹ́ márùn-ún akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin láti Ísírẹ́lì.  Ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́+ kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé: “Ọba, má ṣe jẹ́ kí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ísírẹ́lì bá ọ lọ, nítorí Jèhófà kò wà pẹ̀lú Ísírẹ́lì,+ èyíinì ni, gbogbo ọmọ Éfúráímù.  Ṣùgbọ́n kí ìwọ fúnra rẹ lọ, kí o gbé ìgbésẹ̀, kí o sì jẹ́ onígboyà fún ogun náà.+ Ọlọ́run tòótọ́ lè mú kí o kọsẹ̀ níwájú ọ̀tá; nítorí agbára ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run láti ranni lọ́wọ́+ àti láti múni kọsẹ̀.”+  Látàrí èyí, Amasááyà+ wí fún ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà pé: “Ṣùgbọ́n kí wá ni ṣíṣe nípa ọgọ́rùn-ún tálẹ́ńtì tí mo ti fi fún ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì?”+ Ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà fèsì pé: “Ọ̀nà àtifún ọ ní púpọ̀púpọ̀ ju èyí ń bẹ lọ́wọ́ Jèhófà.”+ 10  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Amasááyà yà wọ́n sọ́tọ̀, èyíinì ni, ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun tí ó tọ̀ ọ́ wá láti Éfúráímù, pé kí wọ́n máa lọ sí ipò wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, ìbínú wọn wá gbóná gidigidi sí Júdà, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi padà sí ipò wọn nínú ìgbóná ìbínú.+ 11  Amasááyà, ní tirẹ̀, mọ́kànle, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣíwájú àwọn ènìyàn tirẹ̀, ó sì lọ sí Àfonífojì Iyọ̀;+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá àwọn ọmọ Séírì balẹ̀,+ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lára wọn.+ 12  Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì ni àwọn ọmọ Júdà mú ní ààyè. Nítorí náà, wọ́n mú wọn wá sí orí àpáta gàǹgà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jù wọ́n láti orí àpáta gàǹgà náà; gbogbo wọn, lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, sì bẹ́ jálajàla.+ 13  Ní ti àwọn mẹ́ńbà ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun tí Amasááyà dá padà lẹ́nu bíbá a lọ sínú ogun náà,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbé sùnmọ̀mí wá sí àwọn ìlú ńlá Júdà, láti Samáríà+ títí lọ dé Bẹti-hórónì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá ẹgbẹ̀ẹ́dógún balẹ̀ lára wọn, wọ́n sì piyẹ́ ohun púpọ̀. 14  Ṣùgbọ́n ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Amasááyà dé láti ẹnu ṣíṣá àwọn ọmọ Édómù balẹ̀, pé ó mú àwọn ọlọ́run+ àwọn ọmọ Séírì wá wàyí, ó sì gbé wọn kalẹ̀ fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọ́run,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹrí ba+ níwájú wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rú èéfín ẹbọ sí wọn.+ 15  Nítorí náà, ìbínú Jèhófà wá gbóná sí Amasááyà, nítorí náà, ó rán wòlíì kan sí i, ó sì wí fún un pé: “Èé ṣe tí o fi wá+ àwọn ọlọ́run+ àwọn ènìyàn náà tí kò dá àwọn ènìyàn tiwọn nídè kúrò ní ọwọ́ rẹ?”+ 16  Ó sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí ó bá a sọ̀rọ̀, pé ọba wí fún un lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé: “Ṣé agbani-nímọ̀ràn ọba ni a fi ọ́ ṣe ni?+ Jáwọ́ fún ire ara rẹ.+ Èé ṣe tí wọn yóò fi ṣá ọ balẹ̀?” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wòlíì náà jáwọ́, ṣùgbọ́n ó wí pé: “Mo mọ̀ dájú pé Ọlọ́run ti pinnu láti run ọ́,+ nítorí pé ìwọ ṣe èyí,+ tí o kò sì fetí sí ìmọ̀ràn mi.”+ 17  Nígbà náà ni Amasááyà ọba Júdà gbìmọ̀, ó sì ránṣẹ́ sí Jèhóáṣì ọmọkùnrin Jèhóáhásì ọmọkùnrin Jéhù ọba Ísírẹ́lì,+ pé: “Wá! Jẹ́ kí a wo ara wa lójú.”+ 18  Látàrí ìyẹn, Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì ránṣẹ́ sí Amasááyà ọba Júdà, pé:+ “Èpò ẹlẹ́gùn-ún tí ó wà ní Lẹ́bánónì ránṣẹ́ sí kédárì tí ó wà ní Lẹ́bánónì,+ pé, ‘Fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi kí ó fi ṣe aya.’+ Bí ó ti wù kí ó rí, ẹranko ẹhànnà+ kan láti inú pápá tí ó wà ní Lẹ́bánónì kọjá, ó sì tẹ èpò ẹlẹ́gùn-ún náà mọ́lẹ̀. 19  Ìwọ ti wí fún ara rẹ pé, Kíyè sí i, ìwọ ti ṣá Édómù+ balẹ̀. Ọkàn-àyà+ rẹ sì ti gbé ọ ga láti di ẹni tí a ṣe lógo.+ Wàyí o, máa bá a nìṣó ní gbígbé ilé tìrẹ.+ Èé ṣe tí ìwọ yóò fi kó wọnú gbọ́nmi-si omi-ò-to nínú ipò tí ó burú,+ tí ìwọ yóò sì fi ṣubú, ìwọ àti Júdà pẹ̀lú rẹ?”+ 20  Ṣùgbọ́n Amasááyà kò fetí sílẹ̀; nítorí pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́+ ni, fún ète fífi wọ́n lé e lọ́wọ́, nítorí pé wọ́n ti wá àwọn ọlọ́run Édómù.+ 21  Nítorí náà, Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì gòkè lọ,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lójú,+ òun àti Amasááyà ọba Júdà, ní Bẹti-ṣémẹ́ṣì,+ tí í ṣe ti Júdà. 22  A sì wá ṣẹ́gun Júdà níwájú Ísírẹ́lì,+ tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi fẹsẹ̀ fẹ, olúkúlùkù sí àgọ́ rẹ̀.+ 23  Amasááyà ọba Júdà, ọmọkùnrin Jèhóáṣì ọmọkùnrin Jèhóáhásì, sì ni Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì gbá mú+ ní Bẹti-ṣémẹ́ṣì, lẹ́yìn èyí tí ó mú un wá sí Jerúsálẹ́mù,+ ó sì ṣe àlàfo sára ògiri Jerúsálẹ́mù, láti Ẹnubodè Éfúráímù+ títí lọ dé Ẹnubodè Igun,+ irínwó ìgbọ̀nwọ́. 24  Ó sì kó gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò tí a rí ní ilé Ọlọ́run tòótọ́ lọ́dọ̀ Obedi-édómù+ àti àwọn ìṣúra ilé ọba+ àti àwọn ẹni àfidógò, lẹ́yìn náà, ó padà lọ sí Samáríà.+ 25  Amasááyà+ ọmọkùnrin Jèhóáṣì ọba Júdà sì ń bá a lọ láti wà láàyè fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún+ lẹ́yìn ikú Jèhóáṣì+ ọmọkùnrin Jèhóáhásì ọba Ísírẹ́lì. 26  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Amasááyà, ti àkọ́kọ́ àti ti ìkẹyìn,+ wò ó! a kò ha kọ wọ́n sínú Ìwé+ Àwọn Ọba Júdà àti Ísírẹ́lì?+ 27  Láti ìgbà tí Amasááyà sì ti yà kúrò nínú títọ Jèhófà lẹ́yìn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun+ sí i ní Jerúsálẹ́mù. Níkẹyìn, ó sá lọ sí Lákíṣì;+ ṣùgbọ́n wọ́n ránṣẹ́ tẹ̀ lé e lọ sí Lákíṣì, wọ́n sì fi ikú pa á níbẹ̀.+ 28  Nítorí náà, wọ́n gbé e sórí àwọn ẹṣin,+ wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí ìlú ńlá Júdà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé