Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kíróníkà 23:1-21

23  Ní ọdún keje, Jèhóádà+ sì fi ara rẹ̀ hàn ní onígboyà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún,+ èyíinì ni, Asaráyà ọmọkùnrin Jéróhámù, àti Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Jèhóhánánì àti Asaráyà ọmọkùnrin Óbédì àti Maaseáyà ọmọkùnrin Ádáyà àti Élíṣáfátì ọmọkùnrin Síkírì, wọnú májẹ̀mú pẹ̀lú ara rẹ̀.  Lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n lọ yí ká jákèjádò Júdà, wọ́n sì kó àwọn ọmọ Léfì+ jọpọ̀ láti inú gbogbo àwọn ìlú ńlá Júdà àti àwọn olórí+ àwọn ìdí ilé baba+ ní Ísírẹ́lì. Nítorí náà, wọ́n wá sí Jerúsálẹ́mù.  Nígbà náà ni gbogbo ìjọ bá ọba dá májẹ̀mú+ nínú ilé+ Ọlọ́run tòótọ́, lẹ́yìn èyí tí ó wí fún wọn pé: “Wò ó! Ọmọkùnrin+ ọba yóò jọba,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti ṣèlérí nípa àwọn ọmọ Dáfídì.+  Èyí ni ohun tí ẹ ó ṣe: ìdá mẹ́ta ẹ̀yin tí ẹ ń wọlé wá ní sábáàtì,+ lára àwọn àlùfáà+ àti lára àwọn ọmọ Léfì,+ yóò jẹ́ olùṣọ́nà;+  ìdá mẹ́ta yóò sì wà ní ilé ọba;+ ìdá mẹ́ta yóò sì wà ní Ẹnubodè Ìpìlẹ̀;+ gbogbo àwọn ènìyàn yóò sì wà ní àwọn àgbàlá+ ilé Jèhófà.  Ẹ má sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọ ilé Jèhófà+ bí kò ṣe àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì tí ń ṣe ìránṣẹ́.+ Àwọn wọ̀nyí ni yóò wọlé, nítorí pé wọ́n jẹ́ àwùjọ mímọ́,+ gbogbo àwọn ènìyàn náà yóò sì pa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe mọ́ sí Jèhófà.  Kí àwọn ọmọ Léfì sì pagbo yí ọba ká ní ìhà gbogbo,+ olúkúlùkù ti òun ti àwọn ohun ìjà tirẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀; ní ti ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń wọ ilé bọ̀, kí a fi ikú pa á. Kí ẹ sì máa wà pẹ̀lú ọba nígbà tí ó bá ń wọlé àti nígbà tí ó bá ń jáde.”  Àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo Júdà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Jèhóádà+ àlùfáà pa láṣẹ.+ Nítorí náà, olúkúlùkù mú àwọn ọkùnrin tirẹ̀ tí ń wọlé bọ̀ ní sábáàtì pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ń jáde lọ ní sábáàtì,+ nítorí pé Jèhóádà àlùfáà kò tíì dá ìpín+ náà sílẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́.  Síwájú sí i, Jèhóádà àlùfáà fún àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ ní àwọn ọ̀kọ̀ àti apata àti apata bìrìkìtì+ tí ó jẹ́ ti Dáfídì Ọba,+ èyí tí ó wà nínú ilé Ọlọ́run+ tòótọ́. 10  Ó sì ń bá a lọ láti yan gbogbo àwọn ènìyàn náà sípò,+ àní olúkúlùkù ti òun ti ohun ọṣẹ́ tirẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, láti ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ilé náà títí lọ dé ẹ̀gbẹ́ òsì ilé náà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé náà, ní gbogbo àyíká nítòsí ọba. 11  Nígbà náà ni wọ́n mú ọmọkùnrin ọba jáde,+ wọ́n sì fi adé dáyádémà+ àti Gbólóhùn Ẹ̀rí+ sí i lórí, wọ́n sì fi í jẹ ọba, bẹ́ẹ̀ sì ni Jèhóádà àti àwọn ọmọ rẹ̀ fòróró yàn án,+ wọ́n sì wí pé: “Kí ọba kí ó pẹ́!”+ 12  Nígbà tí Ataláyà gbọ́ ìró àwọn ènìyàn tí ń sáré tí wọ́n sì ń yin ọba,+ ní kíá, ó wá bá àwọn ènìyàn náà ní ilé Jèhófà. 13  Nígbà náà ni ó rí i, ọba rèé tí ó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọwọ̀n+ rẹ̀ ní ibi àbáwọlé, àti àwọn ọmọ aládé+ àti àwọn kàkàkí+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọba, gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì ń yọ̀,+ wọ́n sì ń fun+ kàkàkí, àti àwọn akọrin+ pẹ̀lú àwọn ohun èlò orin àti àwọn tí ń fúnni ní àmì àfiyèsí fún mímú ìyìn wá. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Ataláyà gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya, ó sì wí pé: “Tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun! Tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun!”+ 14  Ṣùgbọ́n Jèhóádà àlùfáà mú àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún jáde, àwọn tí a yàn sípò nínú ẹgbẹ́ ológun, ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ mú un jáde kúrò nínú àwọn ìlà;+ ní ti ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, kí a fi idà pa á!” Nítorí àlùfáà ti sọ pé: “Kí ẹ má fi ikú pa á ní ilé Jèhófà.” 15  Nítorí náà, wọ́n gbé ọwọ́ wọn lé e. Nígbà tí ó dé ibi àbáwọ ẹnubodè ẹṣin ti ilé ọba, wọ́n fi ikú pa á níbẹ̀ lójú-ẹsẹ̀.+ 16  Nígbà náà ni Jèhóádà dá májẹ̀mú kan láàárín òun fúnra rẹ̀ àti gbogbo àwọn ènìyàn náà àti ọba pé wọn yóò máa wà nìṣó gẹ́gẹ́ bí ènìyàn+ Jèhófà. 17  Lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo àwọn ènìyàn náà wá sí ilé Báálì, wọ́n sì bì í wó;+ àwọn pẹpẹ+ rẹ̀ àti àwọn ère rẹ̀ ni wọ́n sì fọ́ túútúú,+ Mátánì+ àlùfáà Báálì ni wọ́n sì pa+ níwájú àwọn pẹpẹ náà. 18  Síwájú sí i, Jèhóádà fi àwọn ipò iṣẹ́ nínú ilé Jèhófà sí ọwọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, àwọn tí Dáfídì+ ti fi sí àwọn ìpín lórí ilé Jèhófà láti máa rú àwọn ẹbọ sísun Jèhófà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ sínú òfin Mósè,+ pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀ àti pẹ̀lú orin láti ọwọ́ Dáfídì. 19  Nítorí náà, ó yan àwọn aṣọ́bodè+ sẹ́bàá àwọn ẹnubodè+ ilé Jèhófà kí ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìmọ́ lọ́nàkọnà má bàa wọlé. 20  Wàyí o, ó kó àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ àti àwọn ẹni-bí-olúwa àti àwọn olùṣàkóso lé àwọn ènìyàn náà lórí àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, ó sì mú ọba sọ̀ kalẹ̀ wá láti ilé Jèhófà.+ Nígbà náà ni wọ́n gba ẹnubodè apá òkè gan-an kọjá wá sí ilé ọba, wọ́n sì mú ọba jókòó sórí ìtẹ́+ ìjọba. 21  Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì ń bá a lọ ní yíyọ̀;+ ìlú ńlá náà gan-an kò sì ní ìyọlẹ́nu, Ataláyà ni wọ́n sì ti fi idà pa.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé