Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kíróníkà 22:1-12

22  Nígbà náà ni àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù fi Ahasáyà+ ọmọkùnrin rẹ̀ àbíkẹ́yìn jẹ ọba ní ipò rẹ̀, (nítorí ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí tí ó bá àwọn ará Arébíà+ wá sí ibùdó ti pa gbogbo àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀,)+ Ahasáyà ọmọkùnrin Jèhórámù sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba gẹ́gẹ́ bí ọba Júdà.  Ẹni ọdún méjìlélógún ni Ahasáyà nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba,+ ọdún kan sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Ataláyà+ ọmọ-ọmọ Ómírì.+  Òun pẹ̀lú rìn ní àwọn ọ̀nà ilé Áhábù,+ nítorí ìyá+ rẹ̀ alára di agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ nínú ṣíṣe burúkú.  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, lọ́nà kan náà gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù, nítorí àwọn gan-an di agbani-nímọ̀ràn+ rẹ̀ lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, sí ìparun rẹ̀.  Inú ìmọ̀ràn wọn pẹ̀lú ni ó ti rìn,+ tí ó fi bá Jèhórámù+ ọmọkùnrin Áhábù ọba Ísírẹ́lì lọ láti bá Hásáélì+ ọba Síríà jagun ní Ramoti-gílíádì,+ níbi tí àwọn ọ̀tafà ti kọlu Jèhórámù.+  Nítorí náà, ó padà láti gba ìmúláradá ní Jésíréélì+ kúrò nínú ọgbẹ́ tí wọ́n dá sí i lára ní Rámà+ nígbà tí ó bá Hásáélì ọba Síríà jà. Ní ti Asaráyà+ ọmọkùnrin Jèhórámù+ ọba Júdà, ó sọ̀ kalẹ̀ lọ wo Jèhórámù+ ọmọkùnrin Áhábù ní Jésíréélì, nítorí pé ó ń ṣàìsàn.+  Ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run+ ni ìṣubú+ Ahasáyà ti ṣẹlẹ̀ nípa wíwá tí ó wá sọ́dọ̀ Jèhórámù; nígbà tí ó sì dé, ó bá Jèhórámù jáde lọ+ sọ́dọ̀ Jéhù+ ọmọ-ọmọ Nímúṣì,+ ẹni tí Jèhófà ti fòróró yàn+ láti ké ilé Áhábù+ kúrò.  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Jéhù kó wọnú ìjà pẹ̀lú ilé Áhábù,+ ó wá rí àwọn ọmọ aládé Júdà àti àwọn ọmọ àwọn arákùnrin Ahasáyà,+ àwọn òjíṣẹ́ Ahasáyà, ó sì tẹ̀ síwájú láti pa wọ́n.+  Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí wá Ahasáyà, wọ́n sì mú un+ níkẹyìn, bí ó ti ń fara pa mọ́ sí Samáríà,+ wọ́n sì mú un tọ Jéhù wá. Nígbà náà ni wọ́n fi ikú pa á, wọ́n sì sin ín,+ nítorí wọ́n wí pé: “Ọmọ-ọmọ Jèhóṣáfátì+ ni, ẹni tí ó fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀ wá Jèhófà.”+ Kò sì sí ẹnì kankan nínú ilé Ahasáyà tí ó ní agbára fún ìjọba náà. 10  Ní ti Ataláyà ìyá Ahasáyà,+ ó rí i pé ọmọkùnrin òun ti kú. Nítorí náà, ó dìde, ó sì pa gbogbo ọmọ ọba ilé Júdà run.+ 11  Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhóṣábéátì+ ọmọbìnrin ọba gbé Jéhóáṣì+ ọmọkùnrin Ahasáyà, ó sì jí i gbé kúrò láàárín àwọn ọmọkùnrin ọba tí a fẹ́ fi ikú pa, ó sì fi òun àti obìnrin olùṣètọ́jú rẹ̀ sínú yàrá inú lọ́hùn-ún níbi tí a ń kó àwọn àga ìrọ̀gbọ̀kú sí. Jèhóṣábéátì ọmọbìnrin Jèhórámù Ọba,+ aya Jèhóádà+ àlùfáà, (nítorí pé òun alára jẹ́ arábìnrin Ahasáyà,) sì gbé e pa mọ́ nítorí Ataláyà, kò sì fi ikú pa á.+ 12  Ó sì ń bá a lọ ní wíwà pẹ̀lú wọn nínú ilé Ọlọ́run tòótọ́ ní ìfipamọ́ fún ọdún mẹ́fà,+ nígbà tí Ataláyà ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọbabìnrin+ lórí ilẹ̀ náà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé