Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Kíróníkà 21:1-20

21  Níkẹyìn, Jèhóṣáfátì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀+ sí Ìlú Ńlá Dáfídì; Jèhórámù+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.  Ó sì ní àwọn arákùnrin, àwọn ọmọkùnrin Jèhóṣáfátì, Asaráyà àti Jéhíélì àti Sekaráyà àti Asaráyà àti Máíkẹ́lì àti Ṣẹfatáyà, gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọmọkùnrin Jèhóṣáfátì ọba Ísírẹ́lì.  Nítorí náà, baba wọn fún wọn ní ẹ̀bùn púpọ̀+ tí ó jẹ́ fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun ààyò pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìlú ńlá olódi ní Júdà;+ ṣùgbọ́n Jèhórámù+ ni ó fi ìjọba fún, nítorí òun ni àkọ́bí.+  Nígbà tí Jèhórámù dìde sórí ìjọba baba rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí mú ipò rẹ̀ lágbára, nítorí náà, ó fi idà pa gbogbo àwọn arákùnrin+ rẹ̀ àti àwọn kan lára àwọn ọmọ aládé Ísírẹ́lì pẹ̀lú.  Ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ni Jèhórámù nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mẹ́jọ sì ni ó fi jọba+ ní Jerúsálẹ́mù.  Ó sì ń bá a lọ ní rírìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ará ilé Áhábù ti ṣe; nítorí ọmọbìnrin Áhábù ni ó di aya rẹ̀,+ ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.+  Jèhófà kò sì fẹ́ run ilé Dáfídì,+ nítorí májẹ̀mú+ tí ó ti bá Dáfídì dá, àti gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ pé òun yóò fún òun+ àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní fìtílà nígbà gbogbo.+  Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, Édómù+ dìtẹ̀ kúrò lábẹ́ ọwọ́ Júdà,+ wọ́n sì wá fi ọba jẹ lé ara wọn lórí.+  Nítorí náà, Jèhórámù pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí rẹ̀ ré kọjá àti bákan náà gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin pẹ̀lú rẹ̀. Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, ó dìde ní òru, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá àwọn ọmọ Édómù tí ó yí i ká balẹ̀ àti àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin pẹ̀lú. 10  Ṣùgbọ́n Édómù ń bá ìdìtẹ̀ rẹ̀ nìṣó kúrò lábẹ́ ọwọ́ Júdà títí di òní yìí. Ìgbà náà ni Líbínà+ bẹ̀rẹ̀ sí dìtẹ̀ ní àkókò kan náà kúrò lábẹ́ ọwọ́ rẹ̀, nítorí tí ó ti fi Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀ sílẹ̀.+ 11  Òun fúnra rẹ̀ pẹ̀lú ṣe àwọn ibi gíga+ lórí àwọn òkè ńlá Júdà, kí ó lè mú kí àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù ní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe,+ kí ó sì lè lé Júdà lọ.+ 12  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ìwé kan+ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Èlíjà+ wòlíì, pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ wí, ‘Nítorí òtítọ́ náà pé ìwọ kò rìn ní àwọn ọ̀nà Jèhóṣáfátì+ baba rẹ tàbí ní àwọn ọ̀nà Ásà+ ọba Júdà, 13  ṣùgbọ́n ìwọ ń rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì,+ o sì mú kí Júdà àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù ní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe+ ní ọ̀nà kan náà tí ilé Áhábù fi ṣokùnfa níní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe,+ àwọn arákùnrin tìrẹ pàápàá, agbo ilé baba rẹ, àwọn tí ó sàn jù ọ́ lọ, ni o sì ti pa;+ 14  wò ó! Jèhófà yóò mú ìyọnu àgbálù ńlá+ bá àwọn ènìyàn rẹ+ àti àwọn ọmọ rẹ+ àti àwọn aya rẹ àti gbogbo ẹrù rẹ. 15  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìsàn yóò sì ṣe ọ́, pẹ̀lú àrùn+ kan nínú àwọn ìfun rẹ, títí àwọn ìfun rẹ yóò fi tú jáde nítorí àìsàn náà ní ọjọ́ dé ọjọ́.’”+ 16  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jèhófà ru ẹ̀mí+ àwọn Filísínì+ àti ti àwọn ará Arébíà+ tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ará Etiópíà+ dìde sí Jèhórámù. 17  Nítorí náà, wọ́n gòkè wá sí Júdà, wọ́n sì fi ipá wọ inú rẹ̀, wọ́n sì kó gbogbo ẹrù tí ó wà nínú ilé+ ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn aya rẹ̀+ pẹ̀lú ní òǹdè, wọn kò sì ṣẹ́ ọmọkùnrin kan kù fún un bí kò ṣe Jèhóáhásì,+ ọmọkùnrin rẹ̀ àbíkẹ́yìn. 18  Lẹ́yìn gbogbo èyí, Jèhófà fi àìsàn kan tí kò ṣeé wò sàn mú ìyọnu àjàkálẹ̀ bá a nínú àwọn ìfun rẹ̀.+ 19  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, ní àwọn ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e, àní nígbà tí sáà ọdún méjì gbáko parí, ìfun+ rẹ̀ tú jáde nígbà àìsàn rẹ̀, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó kú nínú àwọn àrùn búburú rẹ̀; àwọn ènìyàn rẹ̀ kò sì ṣe ìfinásun fún un bí ìfinásun+ tí wọ́n ṣe fún àwọn baba ńlá rẹ̀. 20  Ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ni ó jẹ́ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mẹ́jọ sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Níkẹyìn, ó lọ láìdunni.+ Nítorí náà, wọ́n sin ín sí Ìlú Ńlá Dáfídì,+ ṣùgbọ́n kì í ṣe sí àwọn ibi ìsìnkú àwọn ọba.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé