Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kíróníkà 2:1-18

2  Wàyí o, Sólómọ́nì sọ ọ̀rọ̀ náà pé kí wọ́n kọ́ ilé+ fún orúkọ+ Jèhófà àti ilé fún ipò ọba+ òun.  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Sólómọ́nì ka ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ ọkùnrin sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí arẹrù àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin ọkùnrin gẹ́gẹ́ bí agékùúta ní òkè ńlá,+ àti egbèjìdínlógún gẹ́gẹ́ bí alábòójútó lórí wọn.+  Síwájú sí i, Sólómọ́nì ránṣẹ́ sí Hírámù+ ọba Tírè pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí o ti bá Dáfídì+ baba mi lò, tí o sì ń kó igi kédárì ránṣẹ́ sí i láti fi kọ́ ilé fún ara rẹ̀ tí yóò máa gbé,—  kíyè sí i, mo ń kọ́+ ilé fún orúkọ+ Jèhófà Ọlọ́run mi láti sọ ọ́ di mímọ́+ fún un, láti máa sun tùràrí onílọ́fínńdà+ níwájú rẹ̀, pẹ̀lú búrẹ́dì onípele+ ìgbà gbogbo àti àwọn ọrẹ ẹbọ sísun ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́,+ ní àwọn sábáàtì+ àti ní àwọn òṣùpá tuntun+ àti ní àwọn àsìkò àjọyọ̀+ Jèhófà Ọlọ́run wa. Fún àkókò tí ó lọ kánrin+ ni èyí yóò fi wà lórí Ísírẹ́lì.  Ilé tí mo ń kọ́ yóò sì tóbi,+ nítorí Ọlọ́run wa tóbi ju gbogbo àwọn ọlọ́run mìíràn.+  Ta sì ni ó lè ní agbára láti fi kọ́ ilé fún un?+ Nítorí tí àwọn ọ̀run àti ọ̀run àwọn ọ̀run kò gbà á,+ ta sì ni èmi+ tí èmi yóò fi kọ́ ilé fún un bí kò ṣe láti máa rú èéfín ẹbọ níwájú rẹ̀?+  Wàyí o, fi ọkùnrin jíjáfáfá kan ránṣẹ́ sí mi, kí ó lè máa ṣiṣẹ́ ọnà wúrà àti fàdákà àti bàbà+ àti irin àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa àti pípọ́n dòdò pa láró àti fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, tí ó sì mọ bí a ti ń fín àwọn iṣẹ́ ọnà fífín, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀jáfáfá tí ó wà pẹ̀lú mi ní Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù, àwọn tí Dáfídì baba mi ti pèsè sílẹ̀.+  Kí o sì kó àwọn ẹ̀là gẹdú kédárì,+ júnípà+ àti igi álígúmù+ tí ó wá láti Lẹ́bánónì+ ránṣẹ́ sí mi, nítorí èmi mọ̀ ní àmọ̀dunjú pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ ní ìrírí nínú gígé àwọn igi Lẹ́bánónì,+ (sì kíyè sí i, àwọn ìránṣẹ́ mi wà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ,)  àní fún pípèsè àwọn ẹ̀là gẹdú sílẹ̀ fún mi ní iye púpọ̀, nítorí ilé tí èmi yóò kọ́ yóò tóbi, bẹ́ẹ̀ ni, ní ọ̀nà àgbàyanu. 10  Sì wò ó! èmi yóò fi àlìkámà, ọ̀kẹ́ kan òṣùwọ̀n kọ́ọ̀,+ àti ọkà bálì ọ̀kẹ́ kan òṣùwọ̀n kọ́ọ̀, àti wáìnì+ ọ̀kẹ́ kan òṣùwọ̀n báàfù, àti òróró ọ̀kẹ́ kan òṣùwọ̀n báàfù fún àwọn aṣẹ́gi, àwọn agégi, àwọn ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ.” 11  Látàrí ìyẹn, Hírámù ọba Tírè+ sọ ọ̀rọ̀ náà nínú ìwé kíkọ, ó sì fi ránṣẹ́ sí Sólómọ́nì pé: “Nítorí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́+ àwọn ènìyàn rẹ̀ ni ó fi sọ ọ́ di ọba lórí wọn.”+ 12  Hírámù sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ ẹni tí ó ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé,+ nítorí pé ó ti fún Dáfídì Ọba ní ọmọkùnrin tí ó gbọ́n, tí ó ní ìrírí nínú ọgbọ́n inú àti òye,+ ẹni tí yóò kọ́ ilé fún Jèhófà àti ilé fún ipò ọba rẹ̀.+ 13  Wàyí o, èmi rán ọkùnrin kan tí ó jáfáfá, tí ó ní ìrírí nínú òye, tí ó jẹ́ ti Hiramu-ábì,+ 14  ọmọkùnrin obìnrin kan láti inú àwọn ọmọ Dánì ṣùgbọ́n ẹni tí baba rẹ̀ jẹ́ ará Tírè, ẹni tí ó ní ìrírí, kí ó lè máa ṣiṣẹ́ ọnà wúrà àti fàdákà, bàbà,+ irin, òkúta+ àti ẹ̀là gẹdú, irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró,+ fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù+ àti aṣọ híhun àtàtà+ àti pípọ́n dòdò+ àti fífín gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà fífín+ àti ṣíṣe iṣẹ́ ọnà gbogbo onírúurú nǹkan àfọgbọ́nrọ+ tí a lè fi fún un pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀jáfáfá ọkùnrin tìrẹ àti àwọn ọ̀jáfáfá ọkùnrin ti olúwa mi Dáfídì baba rẹ. 15  Wàyí o, àlìkámà àti ọkà bálì, òróró àti wáìnì tí olúwa mi ti ṣèlérí, kí ó fi ránṣẹ́ sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+ 16  Ní ti àwa, a óò gé àwọn igi+ láti Lẹ́bánónì ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí o nílò,+ a ó sì gbé wọn wá fún ọ gẹ́gẹ́ bí àwọn àdìlù igi àmúléfòó gba ti orí òkun+ wá sí Jópà,+ ìwọ, ní tìrẹ, yóò sì gbé wọn gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù.” 17  Nígbà náà ni Sólómọ́nì ka iye gbogbo ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ àtìpó, tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì,+ lẹ́yìn ìkànìyàn tí Dáfídì baba rẹ̀ ṣe;+ a sì wá rí ọ̀kẹ́ mẹ́jọ ó dín egbèjìlélọ́gbọ̀n. 18  Nítorí náà, ó sọ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ lára wọn di arẹrù+ àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin di agékùúta+ ní òkè ńlá àti egbèjìdínlógún di alábòójútó fún mímú àwọn ènìyàn náà wà lẹ́nu ìṣiṣẹ́sìn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé