Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kíróníkà 19:1-11

19  Lẹ́yìn náà, Jèhóṣáfátì ọba Júdà padà ní àlàáfíà+ sí ilé tirẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù.  Jéhù+ ọmọkùnrin Hánáánì+ olùríran+ jáde lọ síwájú rẹ̀ wàyí, ó sì wí fún Jèhóṣáfátì Ọba pé: “Ṣé ènìyàn burúkú ni ó yẹ kí a ṣe ìrànlọ́wọ́ fún,+ ṣé àwọn tí ó kórìíra+ Jèhófà sì ni ó yẹ kí o nífẹ̀ẹ́?+ Ǹjẹ́ nítorí èyí, ìkannú+ wà sí ọ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀.  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a rí àwọn ohun rere+ pẹ̀lú rẹ, nítorí pé o ti mú àwọn òpó ọlọ́wọ̀ kúrò ní ilẹ̀ yìí,+ o sì múra ọkàn-àyà rẹ sílẹ̀ láti wá Ọlọ́run tòótọ́.”+  Jèhóṣáfátì sì ń bá a lọ ní gbígbé Jerúsálẹ́mù; ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ láàárín àwọn ènìyàn náà láti Bíá-ṣébà+ dé ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù,+ kí ó lè mú wọn padà wá sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn.+  Ó sì tẹ̀ síwájú láti yan àwọn onídàájọ́ sípò jákèjádò gbogbo ilẹ̀ náà ní gbogbo àwọn ìlú ńlá olódi Júdà, ní ìlú ńlá dé ìlú ńlá.+  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn onídàájọ́ náà pé: “Ẹ kíyè sí ohun tí ẹ ń ṣe,+ nítorí pé kì í ṣe ènìyàn ni ẹ ń ṣe ìdájọ́ fún bí kò ṣe Jèhófà;+ ó sì wà pẹ̀lú yín nínú ọ̀ràn ìdájọ́.+  Wàyí o, ẹ jẹ́ kí ìbẹ̀rùbojo+ Jèhófà wá wà lára yín.+ Ẹ kíyè sára, kí ẹ sì gbé ìgbésẹ̀,+ nítorí pé kò sí àìṣòdodo+ tàbí ojúsàájú+ tàbí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀+ lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa.”  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ní Jerúsálẹ́mù, Jèhóṣáfátì yan àwọn kan lára àwọn ọmọ Léfì+ àti àwọn àlùfáà+ àti àwọn kan lára àwọn olórí àwọn ìdí ilé baba+ ní Ísírẹ́lì sípò fún ìdájọ́+ ti Jèhófà àti fún àwọn ẹjọ́+ fún àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù.  Síwájú sí i, ó gbé àṣẹ kan kalẹ̀ lórí wọn, pé: “Bí ẹ ó ti ṣe nìyí nínú ìbẹ̀rù+ Jèhófà pẹ̀lú ìṣòtítọ́ àti pẹ̀lú ọkàn-àyà pípé pérépéré. 10  Ní ti gbogbo ẹjọ́ tí ó bá wá sọ́dọ̀ yín láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin yín tí ń gbé inú ìlú ńlá wọn, èyí tí ó kan ìtàjẹ̀sílẹ̀,+ èyí tí ó kan òfin+ àti àṣẹ+ àti àwọn ìlànà+ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́,+ kí ẹ kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má bàa ṣe àìtọ́ sí Jèhófà, kí ìkannú+ má bàa sì dé bá ẹ̀yin àti àwọn arákùnrin yín. Bí ẹ ó ti ṣe nìyí kí ẹ má bàa jẹ̀bi. 11  Amaráyà olórí àlùfáà sì rèé lórí yín fún gbogbo ọ̀ràn Jèhófà;+ àti Sebadáyà ọmọkùnrin Íṣímáẹ́lì aṣáájú ilé Júdà fún gbogbo ọ̀ràn ọba; àwọn ọmọ Léfì sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó yín gẹ́gẹ́ bí àwọn onípò àṣẹ. Ẹ jẹ́ alágbára+ kí ẹ sì gbé ìgbésẹ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí Jèhófà+ wà pẹ̀lú ohun tí ó bá jẹ́ rere.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé