Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kíróníkà 18:1-34

18  Jèhóṣáfátì sì wá ní ọrọ̀ àti ògo ní ọ̀pọ̀ yanturu;+ ṣùgbọ́n ó bá Áhábù+ dána.+  Nítorí náà, ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Áhábù ní Samáríà;+ Áhábù sì tẹ̀ síwájú láti fi ọ̀pọ̀ yanturu àgùntàn+ àti màlúù rúbọ fún un àti fún àwọn ènìyàn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dẹ ẹ́ lọ+ láti gòkè lọ gbéjà ko Ramoti-gílíádì.+  Áhábù ọba Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ láti sọ fún Jèhóṣáfátì ọba Júdà pé: “Ìwọ yóò ha bá mi lọ sí Ramoti-gílíádì bí?”+ Látàrí èyí, ó wí fún un pé: “Èmi jẹ́ bákan náà gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti jẹ́, àwọn ènìyàn mi sì dà bí àwọn ènìyàn rẹ, a sì wà pẹ̀lú rẹ nínú ogun náà.”+  Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhóṣáfátì wí fún ọba Ísírẹ́lì pé: “Jọ̀wọ́, kọ́kọ́ wádìí+ nípa ọ̀rọ̀ Jèhófà.”  Nítorí náà, ọba Ísírẹ́lì kó àwọn wòlíì+ jọpọ̀, irínwó ọkùnrin, ó sì wí fún wọn pé: “Ṣé kí a lọ bá Ramoti-gílíádì ja ogun, tàbí kí n fà sẹ́yìn?”+ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Gòkè lọ, Ọlọ́run tòótọ́ yóò sì fi í lé ọba lọ́wọ́.”  Ṣùgbọ́n Jèhóṣáfátì wí pé: “Ṣé kò sí wòlíì Jèhófà níbí mọ́ ni?+ Nígbà náà, ẹ jẹ́ kí a tipasẹ̀ rẹ̀ wádìí.”+  Látàrí ìyẹn, ọba Ísírẹ́lì wí fún Jèhóṣáfátì+ pé: “Ọkùnrin kan+ ṣì wà tí a lè tipasẹ̀ rẹ̀ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ṣùgbọ́n èmi tìkára mi kórìíra rẹ̀+ dájúdájú, nítorí, ní gbogbo ọjọ́ rẹ̀, kì í sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi, bí kò ṣe búburú.+ Mikáyà ọmọkùnrin Ímílà+ ni.” Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhóṣáfátì wí pé: “Kí ọba má sọ ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ọba Ísírẹ́lì pe òṣìṣẹ́ kan láàfin,+ ó sì wí pé: “Mú Mikáyà ọmọkùnrin Ímílà wá kíákíá.”+  Wàyí o, ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì ọba Júdà jókòó, olúkúlùkù lórí ìtẹ́ tirẹ̀, wọ́n wọ ẹ̀wù,+ wọ́n sì jókòó ní ilẹ̀ ìpakà tí ó wà ní ibi àtiwọ ẹnubodè Samáríà; gbogbo àwọn wòlíì sì ń ṣe bí wòlíì níwájú wọn.+ 10  Nígbà náà ni Sedekáyà ọmọkùnrin Kénáánà ṣe àwọn ìwo+ irin fún ara rẹ̀, ó sì wí pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí,+ ‘Ìwọ̀nyí ni ìwọ yóò fi ti àwọn ará Síríà títí ìwọ yóò fi pa wọ́n run pátápátá.’”+ 11  Gbogbo àwọn wòlíì yòókù sì ń sọ tẹ́lẹ̀ bákan náà pé: “Gòkè lọ sí Ramoti-gílíádì kí o sì ṣe àṣeyọrí sí rere,+ dájúdájú, Jèhófà yóò sì fi í lé ọba lọ́wọ́.”+ 12  Ońṣẹ́ tí ó lọ pe Mikáyà sì bá a sọ̀rọ̀, pé: “Wò ó! Ohun rere ni àwọn wòlíì ń sọ ní ìfìmọ̀ṣọ̀kan fún ọba; jọ̀wọ́, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ dà bí ọ̀kan lára tiwọn+ kí o sì sọ ohun rere.”+ 13  Ṣùgbọ́n Mikáyà wí pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ,+ ohun tí Ọlọ́run mi bá wí, ìyẹn ni ohun tí èmi yóò sọ.”+ 14  Nígbà náà ni ó wọlé tọ ọba lọ, ọba sì tẹ̀ síwájú láti wí fún un pé: “Mikáyà, ṣé kí a lọ sí Ramoti-gílíádì láti jagun, tàbí kí n fà sẹ́yìn?” Lójú ẹsẹ̀, ó wí pé: “Gòkè lọ kí o sì ṣe àṣeyọrí sí rere; a ó sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.”+ 15  Látàrí ìyẹn, ọba wí fún un pé: “Ìgbà mélòó ni èmi yóò mú kí o wá sábẹ́ ìbúra+ pé kí o má sọ ohunkóhun fún mi bí kò ṣe òtítọ́ ní orúkọ Jèhófà?”+ 16  Nítorí náà, ó wí pé: “Dájúdájú, mo rí i tí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tú ká lórí àwọn òkè ńlá, bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.+ Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ pé: ‘Àwọn wọ̀nyí kò ní ọ̀gá.+ Kí wọ́n padà, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.’”+ 17  Nígbà náà ni ọba Ísírẹ́lì wí fún Jèhóṣáfátì pé: “Èmi kò ha sọ fún ọ pé, ‘Kò ní sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun rere nípa mi, bí kò ṣe búburú’?”+ 18  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà:+ Dájúdájú, mo rí i tí Jèhófà jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀,+ gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun+ ọ̀run sì dúró síhà ọ̀tún rẹ̀ àti òsì rẹ̀.+ 19  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, ‘Ta ni yóò tan Áhábù ọba Ísírẹ́lì, kí ó lè gòkè lọ, kí ó sì ṣubú ní Ramoti-gílíádì?’ Ìjíròrò sì wáyé, ẹni yìí ń sọ báyìí, ẹni yẹn ń sọ báyẹn.+ 20  Níkẹyìn, ẹ̀mí+ kan jáde wá, ó sì dúró níwájú Jèhófà, ó sì wí pé, ‘Èmi yóò tàn án.’ Látàrí ìyẹn, Jèhófà wí fún un pé, ‘Nípasẹ̀ kí ni?’+ 21  Ó fèsì pé, ‘Èmi yóò jáde lọ, èmi yóò sì di ẹ̀mí ìtannijẹ ní ẹnu gbogbo wòlíì rẹ̀ dájúdájú.’+ Nítorí náà, ó wí pé, ‘Ìwọ yóò tàn án, àti pé, jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìwọ yóò mókè.+ Jáde lọ kí o sì ṣe bẹ́ẹ̀.’+ 22  Wàyí o, kíyè sí i, Jèhófà ti fi ẹ̀mí ìtannijẹ sí ẹnu gbogbo wòlíì rẹ wọ̀nyí;+ ṣùgbọ́n Jèhófà fúnra rẹ̀ ti sọ ìyọnu àjálù nípa rẹ.”+ 23  Sedekáyà+ ọmọkùnrin Kénáánà+ sún mọ́ tòsí wàyí, ó sì gbá Mikáyà+ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́,+ ó sì wí pé: “Ọ̀nà wo gan-an ni ẹ̀mí Jèhófà gbà kọjá lọ lọ́dọ̀ mi láti bá ọ sọ̀rọ̀?”+ 24  Látàrí ìyẹn, Mikáyà wí pé: “Wò ó! Ìwọ yóò rí ọ̀nà náà ní ọjọ́ yẹn+ nígbà tí ìwọ yóò wọ ìyẹ̀wù inú pátápátá láti fi ara rẹ pa mọ́.”+ 25  Nígbà náà ni ọba Ísírẹ́lì wí pé: “Ẹ mú Mikáyà kí ẹ sì mú un padà lọ sọ́dọ̀ Ámọ́nì olórí ìlú ńlá àti sọ́dọ̀ Jóáṣì ọmọkùnrin ọba.+ 26  Kí ẹ sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí ọba wí: “Ẹ fi àwé yìí sí àtìmọ́lé,+ kí ẹ sì máa fi ìwọ̀n oúnjẹ tí a dín kù+ àti ìwọ̀n omi tí a dín kù+ bọ́ ọ títí èmi yóò fi padà dé ní àlàáfíà.”’” 27  Látàrí èyíinì, Mikáyà wí pé: “Bí o bá padà dé rárá ní àlàáfíà, a jẹ́ pé Jèhófà kò bá mi sọ̀rọ̀.”+ Ó sì fi kún un pé: “Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn.”+ 28  Ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì ọba Júdà sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ sí Ramoti-gílíádì.+ 29  Wàyí o, ọba Ísírẹ́lì wí fún Jèhóṣáfátì pé: “Píparadà+ àti wíwọnú ìjà ogun yóò wà fún mi, ṣùgbọ́n ìwọ, ní tìrẹ, gbé ẹ̀wù rẹ wọ̀.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ọba Ísírẹ́lì para dà, lẹ́yìn èyí tí wọ́n wọnú ìjà ogun.+ 30  Ní ti ọba Síríà, ó ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí ó jẹ́ tirẹ̀, pé: “Kí ẹ má ṣe bá ẹni kékeré tàbí ẹni ńlá jà, bí kò ṣe ọba Ísírẹ́lì nìkan.”+ 31  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rí Jèhóṣáfátì, àwọn, ní tiwọn, wí fún ara wọn pé: “Ọba Ísírẹ́lì ni.”+ Nítorí náà, wọ́n yí padà sí i láti bá a jà; Jèhóṣáfátì sì bẹ̀rẹ̀ sí kígbe fún ìrànlọ́wọ́,+ Jèhófà fúnra rẹ̀ sì ràn án lọ́wọ́,+ Ọlọ́run sì dẹ wọ́n lọ kíákíá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.+ 32  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rí i pé kì í ṣe ọba Ísírẹ́lì, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n padà lẹ́yìn rẹ̀.+ 33  Ọkùnrin kan sì wà tí ó fa ọrun ní àìpète, ṣùgbọ́n ó wá ba+ ọba Ísírẹ́lì láàárín àwọn àsokọ́ àti ẹ̀wù tí a fi àdàrọ irin ṣe, tó bẹ́ẹ̀ tí ó wí fún ẹni tí ń wa kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀+ pé: “Yí ọwọ́ rẹ padà, kí o sì gbé mi jáde kúrò nínú ibùdó, nítorí tí mo ti gbọgbẹ́ burúkú-burúkú.”+ 34  Ìjà ogun náà sì ń gbóná janjan sí i ní ọjọ́ yẹn, ṣe ni a sì mú kí ọba Ísírẹ́lì fúnra rẹ̀ wà ní ipò ìdúró nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin ní ìdojúkọ àwọn ará Síríà títí di ìrọ̀lẹ́; ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó kú ní àkókò wíwọ̀ oòrùn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé