Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kíróníkà 17:1-19

17  Jèhóṣáfátì+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀, ó sì mú ipò rẹ̀ lágbára lórí Ísírẹ́lì.  Ó sì tẹ̀ síwájú láti fi àwọn ẹgbẹ́ ológun sínú gbogbo ìlú ńlá olódi ti Júdà, ó sì fi àwọn ẹgbẹ́ ogun sí ilẹ̀ Júdà àti sínú àwọn ìlú ńlá Éfúráímù tí Ásà baba rẹ̀ ti gbà.+  Jèhófà sì ń bá a lọ ní wíwà pẹ̀lú Jèhóṣáfátì,+ nítorí pé ó rìn ní àwọn ọ̀nà àtijọ́ ti Dáfídì baba ńlá rẹ̀,+ kò sì wá àwọn Báálì.+  Nítorí pé Ọlọ́run baba rẹ̀ ni ó wá+ àti pé inú àṣẹ rẹ̀ ni ó ti rìn,+ kì í sì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìṣe Ísírẹ́lì.+  Jèhófà sì fìdí ìjọba náà múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in ní ọwọ́ rẹ̀;+ gbogbo Júdà sì ń bá a lọ láti fi ẹ̀bùn+ fún Jèhóṣáfátì, ó sì wá ní ọrọ̀ àti ògo ní ọ̀pọ̀ yanturu.+  Ọkàn-àyà rẹ̀ sì di aláìṣojo ní àwọn ọ̀nà+ Jèhófà, ó tilẹ̀ mú àwọn ibi gíga+ àti àwọn òpó ọlọ́wọ̀+ kúrò ní Júdà.  Ní ọdún kẹta ìgbà ìjọba rẹ̀, ó ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ aládé rẹ̀, èyíinì ni, Bẹni-háílì àti Ọbadáyà àti Sekaráyà àti Nétánélì àti Mikáyà, pé kí wọ́n máa kọ́ni ní àwọn ìlú ńlá Júdà,  àti pẹ̀lú wọn àwọn ọmọ Léfì náà, Ṣemáyà àti Netanáyà àti Sebadáyà àti Ásáhélì àti Ṣẹ́mírámótì àti Jèhónátánì àti Ádóníjà àti Tóbíjà àti Tobu-ádóníjà àwọn ọmọ Léfì, àti pẹ̀lú wọn Élíṣámà àti Jèhórámù àwọn àlùfáà.+  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ni+ ní Júdà, ìwé òfin Jèhófà+ sì wà pẹ̀lú wọn; wọ́n sì ń bá a nìṣó ní lílọ yí ká gbogbo àwọn ìlú ńlá Júdà, wọ́n sì ń kọ́ni láàárín àwọn ènìyàn náà. 10  Ìbẹ̀rùbojo+ Jèhófà sì wá wà lára gbogbo ìjọba àwọn ilẹ̀ tí ó wà yí ká Júdà, wọn kò sì bá Jèhóṣáfátì+ jà. 11  Wọ́n sì ń mú ẹ̀bùn+ àti owó gẹ́gẹ́ bí owó òde+ wá fún Jèhóṣáfátì láti ọ̀dọ̀ àwọn Filísínì. Àwọn ará Arébíà+ pẹ̀lú ń mú àwọn agbo ẹran wá fún un, ẹgbàárin àgbò ó dín ọ̀ọ́dúnrún àti ẹgbàárin òbúkọ ó dín ọ̀ọ́dúnrún.+ 12  Jèhóṣáfátì sì ń bá a lọ ní títẹ̀síwájú, ó sì di ẹni ńlá+ dé ìwọ̀n gíga lọ́lá; ó sì ń bá a lọ ní kíkọ́ àwọn ibi olódi+ àti àwọn ìlú ńlá ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí+ ní Júdà. 13  Ọ̀pọ̀ sì ni ìpín ìṣúra tí ó di tirẹ̀ ní àwọn ìlú ńlá Júdà; àwọn jagunjagun,+ akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin,+ sì wà ní Jerúsálẹ́mù. 14  Ìwọ̀nyí sì ni ipò iṣẹ́ wọn ní ìbámu pẹ̀lú ilé àwọn baba ńlá wọn: Ti Júdà àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, Ádínáhì olórí, ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀.+ 15  Lábẹ́ ìdarí rẹ̀ sì ni Jèhóhánánì olórí, ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀. 16  Lábẹ́ ìdarí rẹ̀ sì ni Amasáyà ọmọkùnrin Síkírì tí ó fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda+ ara rẹ̀ fún Jèhófà, ọ̀kẹ́ mẹ́wàá akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀. 17  Láti inú Bẹ́ńjámínì,+ Élíádà akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin sì ń bẹ, ọ̀kẹ́ mẹ́wàá ọkùnrin tí wọ́n fi ọrun àti apata gbára dì sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀.+ 18  Lábẹ́ ìdarí rẹ̀ sì ni Jèhósábádì, ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ọkùnrin tí wọ́n ti dira láti wọ ẹgbẹ́ ọmọ ogun sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀. 19  Ìwọ̀nyí ni àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún ọba, yàtọ̀ sí àwọn tí ọba fi sínú àwọn ìlú ńlá olódi+ jákèjádò gbogbo Júdà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé