Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kíróníkà 16:1-14

16  Ní ọdún kẹrìndínlógójì ìgbà ìjọba Ásà, Bááṣà+ ọba Ísírẹ́lì gòkè wá gbéjà ko Júdà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ Rámà,+ kí ó má bàa jẹ́ kí ẹnikẹ́ni jáde lọ tàbí kí ó wọlé wá sọ́dọ̀ Ásà ọba Júdà.+  Wàyí o, Ásà kó fàdákà àti wúrà jáde láti inú àwọn ìṣúra ilé Jèhófà+ àti ilé ọba,+ ó sì ránṣẹ́ sí Bẹni-hádádì+ ọba Síríà,+ ẹni tí ń gbé ní Damásíkù,+ pé:  “Májẹ̀mú kan wà láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín baba mi àti baba rẹ. Kíyè sí i, mo fi fàdákà àti wúrà ránṣẹ́ sí ọ. Lọ, ba májẹ̀mú rẹ pẹ̀lú Bááṣà+ ọba Ísírẹ́lì jẹ́, kí ó lè fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi.”+  Nítorí náà, Bẹni-hádádì fetí sí Ásà Ọba, ó sì rán àwọn olórí ẹgbẹ́ ológun tí ó jẹ́ tirẹ̀ lọ gbéjà ko àwọn ìlú ńlá Ísírẹ́lì, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì kọlu Íjónì+ àti Dánì+ àti Ebẹli-máímù+ àti gbogbo ibi ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí+ àwọn ìlú ńlá Náfútálì.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Bááṣà gbọ́ nípa èyí, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó jáwọ́ nínú kíkọ́ Rámà, ó sì dá iṣẹ́ rẹ̀ dúró.+  Ní ti Ásà Ọba, ó kó gbogbo Júdà,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn òkúta Rámà+ lọ àti àwọn ẹ̀là gẹdú rẹ̀, èyí tí Bááṣà fi kọ́ ọ,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n kọ́ Gébà+ àti Mísípà.+  Ní àkókò yẹn, Hánáánì+ aríran wá bá Ásà ọba Júdà, ó sì wí fún un nígbà náà pé: “Nítorí tí ìwọ gbára lé ọba Síríà,+ tí o kò sì gbára lé Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, fún ìdí yẹn, ẹgbẹ́ ológun ọba Síríà ti lọ mọ́ ọ lọ́wọ́.  Àwọn ará Etiópíà+ àti àwọn ará Líbíà+ kì í ha ṣe ẹgbẹ́ ológun tí ó pọ̀ gan-an ní ti jíjẹ́ ògìdìgbó, nínú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti nínú àwọn ẹlẹ́ṣin;+ nítorí gbígbé tí o gbára lé Jèhófà, òun kò ha sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́?+  Nítorí, ní ti Jèhófà, ojú+ rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé+ láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà+ wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ìwọ ti hùwà òmùgọ̀+ nípa èyí, nítorí, láti ìsinsìnyí lọ ogun yóò máa jà ọ́.”+ 10  Àmọ́ ṣá o, Ásà fara ya sí aríran náà, ó sì fi í sínú ilé àbà,+ nítorí tí ó wà nínú ìhónú sí i lórí èyí.+ Ásà sì bẹ̀rẹ̀ sí ni àwọn mìíràn lára+ nínú àwọn ènìyàn náà ní àkókò yẹn gan-an. 11  Sì wò ó! àwọn àlámọ̀rí Ásà, ti àkọ́kọ́ àti ti ìkẹyìn, ibẹ̀ ni a kọ wọ́n sí nínú Ìwé+ Àwọn Ọba Júdà àti ti Ísírẹ́lì. 12  Ní ọdún kọkàn-dín-lógójì ìgbà ìjọba rẹ̀, Ásà sì ní òjòjò kan ní ẹsẹ̀ rẹ̀ títí ó fi ṣàìsàn gidigidi;+ àti pé, nínú àìsàn rẹ̀ pàápàá, kò wá Jèhófà+ ṣùgbọ́n àwọn amúniláradá ni ó ń wá.+ 13  Níkẹyìn, Ásà dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ ó sì kú ní ọdún kọkàn-lé-lógójì ìgbà ìjọba rẹ̀. 14  Nítorí náà, wọ́n sin ín sí ibi ìsìnkú rẹ̀ títóbi lọ́lá,+ èyí tí ó ti gbẹ́ fún ara rẹ̀ sí Ìlú Ńlá Dáfídì;+ wọ́n sì tẹ́ ẹ sórí ibùsùn tí ó kún fún òróró básámù+ àti oríṣiríṣi òróró ìkunra+ tí a pò pọ̀ nínú òróró ìkunra tí ó jẹ́ àkànṣe.+ Síwájú sí i, wọ́n ṣe ìfinásun fún ààtò ìsìnkú títóbi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀+ fún un.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé