Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Kíróníkà 14:1-15

14  Níkẹyìn, Ábíjà dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ wọ́n sì sin ín sí Ìlú Ńlá Dáfídì;+ Ásà+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀. Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, ilẹ̀ náà kò ní ìyọlẹ́nu+ fún ọdún mẹ́wàá.  Ásà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.  Nítorí náà, ó mú àwọn pẹpẹ ilẹ̀ òkèèrè+ àti àwọn ibi gíga+ kúrò, ó sì fọ́ àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ túútúú,+ ó sì ké àwọn òpó ọlọ́wọ̀ lulẹ̀.+  Síwájú sí i, ó sọ fún Júdà pé kí wọ́n wá+ Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn, kí wọ́n sì pa òfin+ àti àṣẹ+ mọ́.  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó mú àwọn ibi gíga àti àwọn pẹpẹ tùràrí+ kúrò ní gbogbo àwọn ìlú ńlá Júdà; ìjọba náà sì ń bá a lọ láìsí ìyọlẹ́nu+ níwájú rẹ̀.  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn ìlú ńlá olódi sí Júdà,+ nítorí pé ilẹ̀ náà kò ní ìyọlẹ́nu; kò sì sí ogun lòdì sí i ní ọdún wọ̀nyí, nítorí pé Jèhófà fún un ní ìsinmi.+  Nítorí náà, ó wí fún Júdà pé: “Ẹ jẹ́ kí a kọ́ ìlú ńlá wọ̀nyí kí a sì mọ ògiri+ yí wọn ká àti àwọn ilé gogoro,+ àwọn ilẹ̀kùn aláwẹ́ méjì àti àwọn ọ̀pá ìdábùú.+ Ilẹ̀ náà ṣì wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa, nítorí pé a ti wá Jèhófà Ọlọ́run wa.+ A ti wá a, ó sì fún wa ní ìsinmi yí ká.”+ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn, wọ́n sì ṣe àṣeyọrí sí rere.+  Ásà sì wá ní ẹgbẹ́ ológun tí ń gbé apata ńlá+ àti aṣóró,+ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún láti inú Júdà.+ Láti inú Bẹ́ńjámínì, àwọn tí ń gbé asà tí wọ́n sì ń fa ọrun+ sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá.+ Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin.  Lẹ́yìn náà, Síírà ará Etiópíà+ jáde lọ láti gbéjà kò wọ́n pẹ̀lú ẹgbẹ́ ológun tí ó jẹ́ àádọ́ta ọ̀kẹ́ ọkùnrin+ àti ọ̀ọ́dúnrún kẹ̀kẹ́ ẹṣin, ó sì wá títí dé Máréṣà.+ 10  Nígbà náà ni Ásà jáde lọ láti gbéjà kò ó, wọ́n sì tẹ́ ìtẹ́gun ní àfonífojì Séfátà àti Máréṣà. 11  Ásà sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀,+ ó sì wí pé: “Jèhófà, ní ti rírannilọ́wọ́, kò jámọ́ nǹkan kan lọ́dọ̀ rẹ yálà àwọn ènìyàn púpọ̀ ní ń bẹ tàbí àwọn tí kò ní agbára.+ Ràn wá lọ́wọ́, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa, nítorí ìwọ ni a gbára lé,+ orúkọ+ rẹ sì ni a fi dojú kọ ogunlọ́gọ̀ yìí. Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run+ wa. Má ṣe jẹ́ kí ẹni kíkú ní okun láti dojú kọ ọ́.”+ 12  Látàrí ìyẹn, Jèhófà ṣẹ́gun+ àwọn ará Etiópíà níwájú Ásà àti níwájú Júdà, àwọn ará Etiópíà sì fẹsẹ̀ fẹ. 13  Ásà àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì ń bá a nìṣó ní lílépa wọn títí dé Gérárì,+ àwọn tí ó sì jẹ́ ará Etiópíà ń ṣubú lulẹ̀ títí kò fi sí ẹnì kankan lára wọn tí ó wà láàyè; nítorí pé a fọ́ wọ́n sí wẹ́wẹ́ níwájú Jèhófà+ àti níwájú ibùdó rẹ̀.+ Lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n kó ohun ìfiṣèjẹ púpọ̀ gan-an lọ.+ 14  Síwájú sí i, wọ́n kọlu gbogbo àwọn ìlú ńlá tí ó yí Gérárì ká, nítorí pé ìbẹ̀rùbojo+ Jèhófà ti wá wà lára wọn; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí piyẹ́ gbogbo àwọn ìlú ńlá náà, nítorí tí ó ṣẹlẹ̀ pé ohun púpọ̀ láti piyẹ́ wà nínú wọn.+ 15  Àní àwọn àgọ́+ tí ó ní ohun ọ̀sìn ni wọ́n kọlù tí ó fi jẹ́ pé wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbo ẹran ní òǹdè+ àti ràkúnmí,+ lẹ́yìn èyí tí wọ́n padà sí Jerúsálẹ́mù.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé