Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kíróníkà 13:1-22

13  Ní ọdún kejìdínlógún Jèróbóámù Ọba ni Ábíjà bẹ̀rẹ̀ sí jọba lórí Júdà.+  Ọdún mẹ́ta ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù, orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Mikáyà+ ọmọbìnrin Úríélì ti Gíbíà.+ Ogun sì ṣẹlẹ̀ láàárín Ábíjà àti Jèróbóámù.+  Nítorí náà, Ábíjà fi ẹgbẹ́ ológun tí ó jẹ́ ogún ọ̀kẹ́ àwọn alágbára ńlá ọkùnrin ogun,+ àwọn àṣàyàn ọkùnrin kó wọnú ogun. Jèróbóámù alára sì fi ogójì ọ̀kẹ́ àwọn àṣàyàn ọkùnrin, akíkanjú, alágbára ńlá+ tẹ́ ìtẹ́gun lòdì sí i.  Ábíjà dìde wàyí lórí Òkè Ńlá Sémáráímù, èyí tí ó wà ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù,+ ó sì wí pé: “Ẹ gbọ́ mi, ìwọ Jèróbóámù àti gbogbo Ísírẹ́lì.  Kì í ha ṣe fún yín láti mọ̀ pé Jèhófà Ọlọrun Ísírẹ́lì tìkára rẹ̀ fi ìjọba fún Dáfídì+ lórí Ísírẹ́lì fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ fún òun àti fún àwọn ọmọ rẹ̀,+ nípasẹ̀ májẹ̀mú iyọ̀?+  Jèróbóámù+ ọmọkùnrin Nébátì, ìránṣẹ́+ Sólómọ́nì ọmọkùnrin Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí dìde, ó sì ṣọ̀tẹ̀+ sí olúwa rẹ̀.+  Àwọn ọkùnrin aláìríkan-ṣèkan,+ àwọn ènìyàn tí kò dára fún ohunkóhun,+ sì ń kó ara wọn jọpọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀. Níkẹyìn, wọ́n ta Rèhóbóámù+ ọmọkùnrin Sólómọ́nì yọ, nígbà tí Rèhóbóámù alára jẹ́ ọ̀dọ́ àti ọlọ́kàn ojo,+ kò sì lè dúró lòdì sí wọn.  “Nísinsìnyí, ẹ̀yin ń ronú àtidúró lòdì sí ìjọba Jèhófà ní ọwọ́ àwọn ọmọkùnrin Dáfídì,+ nígbà tí ẹ jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá+ tí àwọn ọmọ màlúù wúrà tí Jèróbóámù ṣe fún yín gẹ́gẹ́ bí ọlọ́run+ sì wà pẹ̀lú yín.  Ẹ kò ha ti lé àwọn àlùfáà Jèhófà+ jáde, àwọn ọmọ Áárónì, àti àwọn ọmọ Léfì, ẹ kò ha sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣe àwọn àlùfáà fún ara yín bí ti àwọn ènìyàn ilẹ̀ wọnnì?+ Ní ti ẹnikẹ́ni tí ó bá wá, tí ó sì fi agbára kún ọwọ́ ara rẹ̀ nípasẹ̀ ẹgbọrọ akọ màlúù kan àti àgbò méje, òun a di àlùfáà àwọn ohun tí kì í ṣe ọlọ́run.+ 10  Ní ti àwa, Jèhófà ni Ọlọ́run wa,+ àwa kò sì fi í sílẹ̀; ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà ń ṣe ìránṣẹ́ fún Jèhófà, àwọn ọmọ Áárónì, àti àwọn ọmọ Léfì pẹ̀lú lẹ́nu iṣẹ́.+ 11  Wọ́n sì ń mú kí èéfín àwọn ọrẹ ẹbọ sísun máa rú sí Jèhófà ní òròòwúrọ̀ àti ní alaalẹ́+ àti tùràrí onílọ́fínńdà+ pẹ̀lú; àwọn ipele búrẹ́dì sì ń bẹ lórí tábìlì ògidì wúrà,+ ọ̀pá fìtílà wúrà+ sì ń bẹ àti àwọn fìtílà rẹ̀ láti máa tàn ní alaalẹ́;+ nítorí pé àwa ń pa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe+ fún Jèhófà Ọlọ́run wa mọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀yin fúnra yín ti fi í sílẹ̀.+ 12  Sì wò ó! Ọlọ́run tòótọ́+ ń bẹ pẹ̀lú wa ní iwájú wa pẹ̀lú àwọn àlùfáà+ rẹ̀ àti àwọn kàkàkí+ afúnni-lámì-àfiyèsí fún mímú igbe ìdágìrì ogun dún jáde sí yín. Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ má ṣe bá Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá+ yín jà, nítorí pé ẹ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere.”+ 13  Jèróbóámù, ní tirẹ̀, sì rán ibùba lọ yí ká láti yọ sí wọn láti ẹ̀yìn, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n wà ní iwájú Júdà, ibùba náà sì wà lẹ́yìn wọn.+ 14  Nígbà tí àwọn ti Júdà yí padà, họ́wù, ìjà ogun rèé níwájú àti lẹ́yìn wọn.+ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde sí Jèhófà,+ bí àwọn àlùfáà ti ń fun kàkàkí kíkankíkan. 15  Àwọn ọkùnrin Júdà sì bú sí igbe ogun.+ Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí àwọn ọkùnrin Júdà kígbe ogun, nígbà náà ni Ọlọ́run tòótọ́ fúnra rẹ̀ ṣẹ́gun+ Jèróbóámù àti gbogbo Ísírẹ́lì níwájú Ábíjà+ àti Júdà. 16  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì fẹsẹ̀ fẹ kúrò níwájú Júdà, nígbà náà ni Ọlọ́run sì fi wọ́n lé wọn lọ́wọ́.+ 17  Ábíjà àti àwọn ènìyàn rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìpakúpa púpọ̀ jaburata ṣá wọn balẹ̀; àwọn tí a pa lára Ísírẹ́lì sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣubú lulẹ̀, ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n àwọn àṣàyàn ọkùnrin. 18  Bí a ṣe rẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ nìyẹn ní àkókò náà, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Júdà ta wọ́n yọ nítorí pé wọ́n gbára lé+ Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn. 19  Ábíjà sì ń bá a nìṣó ní lílépa Jèróbóámù, ó sì wá gba àwọn ìlú ńlá lọ́wọ́ rẹ̀, Bẹ́tẹ́lì+ àti àwọn àrọko rẹ̀, àti Jẹ́ṣánà àti àwọn àrọko rẹ̀, àti Éfúráínì àti àwọn àrọko rẹ̀.+ 20  Jèróbóámù kò sì ní agbára kankan mọ́+ ní àwọn ọjọ́ Ábíjà; ṣùgbọ́n Jèhófà mú ìyọnu àgbálù bá a,+ bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú. 21  Ábíjà sì ń bá a lọ láti fún ara rẹ̀ lókun.+ Nígbà tí ó ṣe, ó fẹ́ aya mẹ́rìnlá fún ara rẹ̀,+ ó sì bí ọmọkùnrin méjìlélógún+ àti ọmọbìnrin mẹ́rìndínlógún. 22  Ìyókù àlámọ̀rí Ábíjà, àní àwọn ọ̀nà rẹ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, ni a kọ sínú ìgbékalẹ̀ àlàyé wòlíì Ídò.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé