Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kíróníkà 12:1-16

12  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ipò ọba Rèhóbóámù fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in,+ gbàrà tí ó sì di alágbára, ó fi òfin Jèhófà sílẹ̀,+ àti bákan náà, gbogbo Ísírẹ́lì+ pẹ̀lú rẹ̀.  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọdún karùn-ún Rèhóbóámù Ọba+ pé Ṣíṣákì+ ọba Íjíbítì gòkè wá gbéjà ko Jerusalẹmu, (nítorí tí wọ́n ti hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà,)+  pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún méjìlá kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ àti ọ̀kẹ́ mẹ́ta àwọn ẹlẹ́ṣin; àwọn ènìyàn tí ó bá a ti Íjíbítì wá kò sì níye+—àwọn ará Líbíà,+ Súkímù àti àwọn ará Etiópíà.+  Ó sì gba àwọn ìlú ńlá olódi tí ó jẹ́ ti Júdà,+ ó sì wá títí dé Jerúsálẹ́mù+ níkẹyìn.  Wàyí o, ní ti Ṣemáyà+ wòlíì, ó wá sọ́dọ̀ Rèhóbóámù àti àwọn ọmọ aládé Júdà tí wọ́n ti kó ara wọn jọ sí Jerúsálẹ́mù nítorí Ṣíṣákì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún wọn pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ẹ̀yin, ní tiyín, ti fi mí sílẹ̀,+ èmi náà, ní tèmi, sì ti fi yín sílẹ̀+ sí ọwọ́ Ṣíṣákì.’”  Látàrí ìyẹn, àwọn ọmọ aládé Ísírẹ́lì àti ọba rẹ ara wọn sílẹ̀,+ wọ́n sì wí pé: “Olódodo ni Jèhófà.”+  Nígbà tí Jèhófà sì rí+ i pé wọ́n rẹ ara wọn sílẹ̀, ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Ṣemáyà+ wá, pé: “Wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀. Èmi kì yóò run wọ́n, ní ìgbà díẹ̀ sí i, èmi yóò sì pèsè àsálà fún wọn dájúdájú,+ ìhónú mi kì yóò sì tú jáde sórí Jerúsálẹ́mù nípa ọwọ́ Ṣíṣákì.+  Ṣùgbọ́n wọn yóò di ìránṣẹ́ rẹ̀,+ kí wọ́n lè mọ ìyàtọ̀ láàárín iṣẹ́ ìsìn mi+ àti iṣẹ́ ìsìn àwọn ìjọba ilẹ̀ wọnnì.”+  Nítorí náà, Ṣíṣákì+ ọba Íjíbítì gòkè wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù, ó sì kó àwọn ìṣúra ilé Jèhófà+ àti àwọn ìṣúra ilé ọba.+ Ohun gbogbo ni ó kó; nípa báyìí, ó kó àwọn apata wúrà tí Sólómọ́nì ṣe.+ 10  Nítorí náà, Rèhóbóámù Ọba ṣe àwọn apata bàbà dípò wọn, ó sì fi wọ́n sí ìkáwọ́ àwọn olórí àwọn sárésáré,+ àwọn ẹ̀ṣọ́+ ẹnu ọ̀nà ilé ọba.+ 11  A sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbàkúùgbà tí ọba bá wá sí ilé Jèhófà, àwọn sárésáré a wọlé, wọn a sì gbé wọn, wọn a sì dá wọn padà sí ìyẹ̀wù ẹ̀ṣọ́ ti àwọn sárésáré.+ 12  Àti nítorí pé ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ìbínú Jèhófà yí padà kúrò lórí rẹ̀,+ kò sì ronú àtirun wọ́n pátápátá.+ Àti pé, ní àfikún, ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn ohun rere wà ní Júdà.+ 13  Rèhóbóámù Ọba sì ń bá a lọ láti mú ipò rẹ̀ lágbára ní Jerúsálẹ́mù, ó sì ń jọba nìṣó; nítorí Rèhóbóámù+ jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàn-lé-lógójì nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ó sì jọba fún ọdún mẹ́tàdínlógún ní Jerúsálẹ́mù, ìlú ńlá+ tí Jèhófà yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Náámà+ ọmọbìnrin Ámónì.+ 14  Ṣúgbọ̀n, ó ṣe ohun tí ó burú,+ nítorí pé kò fi ọkàn-àyà rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in láti wá Jèhófà.+ 15  Ní ti àwọn àlámọ̀rí Rèhóbóámù, ti àkọ́kọ́ àti ti ìkẹyìn,+ a kò ha kọ wọ́n sínú àwọn ọ̀rọ̀ Ṣemáyà+ wòlíì àti ti Ídò+ olùríran nípa àkọsílẹ̀ orúkọ ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn ìlà ìdílé? Ogun sì wà láàárín Rèhóbóámù+ àti Jèróbóámù+ ní gbogbo ìgbà. 16  Níkẹyìn, Rèhóbóámù dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ a sì sin ín sí Ìlú Ńlá Dáfídì;+ Ábíjà+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé