Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kíróníkà 11:1-23

11  Nígbà tí Rèhóbóámù dé Jerúsálẹ́mù,+ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó pe ilé Júdà àti Bẹ́ńjámínì+ jọpọ̀, ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ààyò abarapá ọkùnrin fún ogun,+ láti bá Ísírẹ́lì jà láti lè mú ìjọba padà wá fún Rèhóbóámù.  Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Jehofa tọ Ṣemáyà+ ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ wá, pé:  “Sọ fún Rèhóbóámù ọmọkùnrin Sólómọ́nì ọba Júdà+ àti fún gbogbo Ísírẹ́lì ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì pé,  ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ gòkè lọ bá àwọn arákùnrin yín jà.+ Kí olúkúlùkù padà sí ilé rẹ̀, nítorí èmi ni ó mú kí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀.”’”+ Nítorí náà, wọ́n ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ Jèhófà, wọ́n sì padà lẹ́nu lílọ gbéjà ko Jèróbóámù.+  Rèhóbóámù sì ń bá a lọ ní gbígbé Jerúsálẹ́mù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn ìlú ńlá olódi sí Júdà.  Nípa báyìí, ó tún Bẹ́tílẹ́hẹ́mù kọ́+ àti Étámì+ àti Tékóà,+  àti Bẹti-súrì+ àti Sókò+ àti Ádúlámù,+  àti Gátì+ àti Máréṣà+ àti Sífù,+  àti Ádóráímù àti Lákíṣì+ àti Ásékà,+ 10  àti Sórà+ àti Áíjálónì+ àti Hébúrónì,+ àwọn ìlú ńlá olódi, tí ń bẹ ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì. 11  Síwájú sí i, ó mú àwọn ibi olódi túbọ̀ lágbára,+ ó sì fi àwọn aṣáájú+ sínú wọn àti àwọn ìpèsè oúnjẹ àti òróró àti wáìnì, 12  ó sì fi àwọn apata ńlá+ àti aṣóró+ sí gbogbo onírúurú ìlú ńlá; ó sì ń bá a lọ ní títúbọ̀ mú wọn lágbára dé ìwọ̀n púpọ̀ gan-an. Júdà àti Bẹ́ńjámínì sì ń bá a lọ láti jẹ́ tirẹ̀. 13  Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì tí ń bẹ ní gbogbo Ísírẹ́lì sì mú ìdúró wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ láti inú gbogbo àwọn ìpínlẹ̀ wọn. 14  Nítorí pé àwọn ọmọ Léfì fi àwọn ilẹ̀ ìjẹko+ wọn àti ohun ìní+ wọn sílẹ̀, nígbà náà, wọ́n wá sí Júdà àti Jerúsálẹ́mù,+ nítorí pé Jèróbóámù+ àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti yọ+ wọ́n kúrò nínú ṣíṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà Jèhófà. 15  Àwọn àlùfáà fún àwọn ibi gíga+ àti fún àwọn ẹ̀mí èṣù onírìísí ewúrẹ́+ àti fún àwọn ọmọ màlúù tí ó ṣe+ ni ó tẹ̀ síwájú láti fi sẹ́nu iṣẹ́ fún ara rẹ̀. 16  Ní títẹ̀lé wọn láti inú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, àwọn tí ó fi ọkàn-àyà wọn fún àtiwá Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì fúnra wọn wá sí Jerúsálẹ́mù+ láti rúbọ+ sí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn. 17  Wọ́n sì ń bá a nìṣó ní fífún ipò ọba Júdà+ lókun, wọ́n sì fìdí ipò Rèhóbóámù ọmọkùnrin Sólómọ́nì múlẹ̀ fún ọdún mẹ́ta, nítorí tí wọ́n rìn ní ọ̀nà Dáfídì àti Sólómọ́nì fún ọdún mẹ́ta.+ 18  Nígbà náà ni Rèhóbóámù fẹ́ Máhálátì ọmọbìnrin Jérímótì ọmọkùnrin Dáfídì, àti ti Ábíháílì ọmọbìnrin Élíábù+ ọmọkùnrin Jésè ṣe aya rẹ̀. 19  Nígbà tí ó ṣe, ó bí àwọn ọmọkùnrin fún un, Jéúṣì àti Ṣemaráyà àti Sáhámù. 20  Lẹ́yìn rẹ̀, ó fẹ́ Máákà+ ọmọ-ọmọ Ábúsálómù.+ Nígbà tí ó ṣe, ó bí Ábíjà+ àti Átáì àti Sísà àti Ṣẹ́lómítì fún un. 21  Rèhóbóámù sì nífẹ̀ẹ́ Máákà ọmọ-ọmọ Ábúsálómù gidigidi ju gbogbo àwọn aya+ rẹ̀ yòókù àti àwọn wáhàrì rẹ̀; nítorí pé aya méjìdínlógún ni ó fẹ́, àti ọgọ́ta wáhàrì pẹ̀lú, tí ó fi bí ọmọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n àti ọgọ́ta ọmọbìnrin. 22  Nítorí náà, Rèhóbóámù fi Ábíjà ọmọkùnrin Máákà sẹ́nu iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olórí, gẹ́gẹ́ bí aṣáájú láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀, nítorí ó ronú nípa fífi í jẹ ọba. 23  Bí ó ti wù kí ó rí, ó hùwà lọ́nà òye,+ ó sì pín lára gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ sí gbogbo ilẹ̀ Júdà àti ti Bẹ́ńjámínì,+ sí gbogbo ìlú ńlá olódi,+ ó sì fún wọn ní oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu,+ ó sì wá ògìdìgbó àwọn aya fún wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé