Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kíróníkà 10:1-19

10  Rèhóbóámù+ sì tẹ̀ síwájú láti lọ sí Ṣékémù,+ nítorí Ṣékémù ni gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá láti fi í jẹ ọba.  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Jèróbóámù+ ọmọkùnrin Nébátì gbọ́ nípa èyí nígbà tí ó ṣì wà ní Íjíbítì,+ (nítorí pé ó sá lọ ní tìtorí Sólómọ́nì Ọba,) lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèróbóámù padà wá láti Íjíbítì.+  Nítorí náà, wọ́n ránṣẹ́ pè é, Jèróbóámù àti gbogbo Ísírẹ́lì sì wá, wọ́n sì bá Rèhóbóámù sọ̀rọ̀ pé:+  “Baba rẹ, ní tirẹ̀, mú kí àjàgà wa nira;+ wàyí o, mú kí iṣẹ́ ìsìn nínira ti baba rẹ àti àjàgà wíwúwo+ tí ó fi bọ̀ wá lọ́rùn fúyẹ́, àwa yóò sì máa sìn ọ́.”+  Látàrí èyí, ó wí fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ kí ó di ọjọ́ mẹ́ta òní. Nígbà náà ni kí ẹ padà wá sọ́dọ̀ mi.” Nítorí náà, àwọn ènìyàn náà lọ.  Rèhóbóámù Ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ̀ràn lọ+ àwọn àgbà ọkùnrin tí ń ṣe ìránṣẹ́ nígbà gbogbo fún Sólómọ́nì baba rẹ̀ nígbà tí ó ṣì wà láàyè, pé: “Àmọ̀ràn wo ni ẹ óò fúnni láti fi fèsì fún àwọn ènìyàn yìí?”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n bá a sọ̀rọ̀ pé: “Bí ìwọ yóò bá fi ara rẹ hàn ní ẹni rere sí àwọn ènìyàn yìí, tí o sì ṣe ohun tí ó wù wọ́n ní ti gidi, tí o sì sọ ọ̀rọ̀ rere fún wọn ní tòótọ́,+ dájúdájú, àwọn pẹ̀lú yóò di ìránṣẹ́ rẹ títí lọ.”+  Àmọ́ ṣá o, ó fi ìmọ̀ràn+ tí àwọn àgbà ọkùnrin gbà á sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ̀ràn lọ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jọ dàgbà pọ̀,+ àwọn ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.+  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún wọn pé: “Kí ni ìmọ̀ràn tí ẹ ó gbani,+ kí a lè fèsì fún àwọn ènìyàn yìí tí ó bá mi sọ̀rọ̀ pé, ‘Mú kí àjàgà tí baba rẹ fi bọ̀ wá lọ́rùn fúyẹ́’?”+ 10  Ẹ̀wẹ̀, àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jọ dàgbà pọ̀ bá a sọ̀rọ̀ pé: “Èyí ni ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ènìyàn tí ó bá ọ sọ̀rọ̀ pé, ‘Baba rẹ, ní tirẹ̀, mú kí àjàgà wa wúwo, ṣùgbọ́n ní tìrẹ, mú kí ó fúyẹ́ lọ́rùn wa’; èyí ni ohun tí ìwọ yóò sọ fún wọn,+ ‘Dájúdájú, ọmọńdinrín mi yóò nípọn ju ìgbáròkó baba mi.+ 11  Wàyí o, baba mi, ní tirẹ̀, gbé ẹrù àjàgà wíwúwo bọ̀ yín lọ́rùn, ṣùgbọ́n èmi, ní tèmi, yóò fi kún àjàgà yín.+ Baba mi, ní tirẹ̀, fi pàṣán nà yín, ṣùgbọ́n èmi, ní tèmi, yóò lo bílálà oníkókó.’”+ 12  Jèróbóámù àti gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí wá sọ́dọ̀ Rèhóbóámù ní ọjọ́ kẹta,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ọba ti sọ, pé: “Ẹ padà wá sọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ kẹta.” 13  Ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí dá wọn lóhùn lọ́nà lílekoko.+ Bí Rèhóbóámù Ọba ṣe fi ìmọ̀ràn+ àwọn àgbà ọkùnrin+ sílẹ̀ nìyẹn, 14  ó sì ń bá a lọ láti bá wọn sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́kùnrin,+ pé: “Èmi yóò mú kí àjàgà yín túbọ̀ wúwo sí i, àti pé èmi, ní tèmi, yóò fi kún un. Baba mi, ní tirẹ̀, fi pàṣán nà yín, ṣùgbọ́n èmi, ní tèmi, yóò lo bílálà oníkókó.”+ 15  Ọba kò sì fetí sí àwọn ènìyàn náà; nítorí ó wá jẹ́ ìyípadà àwọn àlámọ̀rí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́,+ kí Jèhófà lè mú ọ̀rọ̀+ rẹ̀ ṣẹ, èyí tí ó sọ nípasẹ̀ Áhíjà+ ọmọ Ṣílò+ fún Jèróbóámù ọmọkùnrin Nébátì.+ 16  Ní ti gbogbo Ísírẹ́lì, nítorí pé ọba kò fetí sí wọn, àwọn ènìyàn náà fún ọba lésì wàyí, pé: “Ìpín wo ni àwa ní nínú Dáfídì?+ Kò sì sí ogún kankan nínú ọmọkùnrin Jésè.+ Olúkúlùkù, lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run rẹ,+ ìwọ Ísírẹ́lì! Wàyí o, máa bójú tó ilé tìrẹ, ìwọ Dáfídì.”+ Látàrí ìyẹn, gbogbo Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí àgọ́ tiwọn. 17  Ní ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ń gbé ní àwọn ìlú ńlá Júdà, Rèhóbóámù ń bá a lọ láti jọba lé wọn lórí.+ 18  Lẹ́yìn náà, Rèhóbóámù Ọba rán Hádórámù,+ ẹni tí ó wà lórí àwọn tí a ń fi túláàsì mú sìn nínú òpò àfipámúniṣe, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ ọ́ ní òkúta,+ bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú. Agbára káká sì ni Rèhóbóámù Ọba alára fi ṣàṣeyọrí láti gòkè wọnú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ kí ó lè sá lọ sí Jerúsálẹ́mù.+ 19  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń bá ìdìtẹ̀+ wọn sí ilé Dáfídì nìṣó títí di òní yìí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé