Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kíróníkà 1:1-17

1  Sólómọ́nì ọmọkùnrin Dáfídì sì ń bá a lọ láti rí okun gbà nínú ipò ọba rẹ̀,+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀,+ ó sì ń mú kí ó di ńlá lọ́nà títayọ ré kọjá.+  Sólómọ́nì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ fún gbogbo Ísírẹ́lì, fún àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún+ àti ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ àti fún àwọn onídàájọ́+ àti fún gbogbo ìjòyè gbogbo Ísírẹ́lì,+ olórí àwọn ìdí ilé baba.+  Nígbà náà, Sólómọ́nì àti gbogbo ìjọ tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ lọ sí ibi gíga tí ó wà ní Gíbéónì;+ nítorí pé ibẹ̀ ni àgọ́ ìpàdé+ Ọlọ́run tòótọ́, èyí tí Mósè ìránṣẹ́+ Jèhófà pa ní aginjù, wà.  Bí ó ti wù kí ó rí, Dáfídì ti gbé àpótí+ Ọlọ́run tòótọ́ gòkè wá láti Kiriati-jéárímù+ sí ibi tí Dáfídì pèsè sílẹ̀ fún un,+ nítorí tí ó pa àgọ́ fún un ní Jerúsálẹ́mù.+  A sì ti gbé pẹpẹ+ bàbà tí Bẹ́sálẹ́lì+ ọmọkùnrin Úráì ọmọkùnrin Húrì+ ṣe síwájú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà; Sólómọ́nì àti ìjọ sì ń béèrè fún nǹkan níbẹ̀ bí ti tẹ́lẹ̀ rí.  Wàyí o, Sólómọ́nì rú àwọn ọrẹ ẹbọ níbẹ̀ níwájú Jèhófà lórí pẹpẹ bàbà tí ó jẹ́ ti àgọ́ ìpàdé, ó sì tẹ̀ síwájú láti fi ẹgbẹ̀rún ọrẹ ẹbọ sísun+ rúbọ lórí rẹ̀.  Ní òru yẹn, Ọlọ́run fara han Sólómọ́nì, ó sì wí fún un nígbà náà pé: “Béèrè! Kí ni kí n fún ọ?”+  Látàrí ìyẹn, Sólómọ́nì wí fún Ọlọ́run pé: “Ìwọ ni Ẹni tí ó ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ńláǹlà sí Dáfídì baba mi,+ ìwọ sì ni ó fi mí jẹ ọba ní ipò rẹ̀.+  Wàyí o, Jèhófà Ọlọ́run, kí ìlérí rẹ fún Dáfídì baba mi já sí aṣeégbíyèlé,+ nítorí ìwọ fúnra rẹ ni ó fi mí jẹ ọba+ lórí àwọn ènìyàn kan tí ó pọ̀ níye bí egunrín ekuru ilẹ̀.+ 10  Wàyí o, fún mi ní ọgbọ́n àti ìmọ̀+ kí n lè máa jáde lọ níwájú àwọn ènìyàn yìí, kí n sì lè máa wọlé,+ nítorí ta ní lè ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ tí ó pọ̀ yìí?”+ 11  Nígbà náà, Ọlọ́run sọ fún Sólómọ́nì pé: “Nítorí ìdí náà pé èyí wà ní góńgó ọkàn-àyà+ rẹ, tí o kò sì béèrè fún ọlà, ọrọ̀ àti ọlá tàbí ọkàn àwọn tí ó kórìíra rẹ, bẹ́ẹ̀ ni o kò tilẹ̀ béèrè fún ọjọ́ púpọ̀,+ ṣùgbọ́n o béèrè fún ọgbọ́n àti ìmọ̀ fún ara rẹ kí o lè máa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn mi tí mo fi ọ́ jẹ ọba+ lé lórí, 12  ọgbọ́n àti ìmọ̀ ni a ó fi fún ọ;+ ọlà àti ọrọ̀ àti ọlá pẹ̀lú ni èmi yóò fi fún ọ, irú èyí tí kò ṣẹlẹ̀ pé ọba kankan tí ó wà ṣáájú rẹ ní,+ àti irú èyí tí ẹnì kankan tí ó wà lẹ́yìn rẹ kì yóò wá ní.”+ 13  Nítorí náà, Sólómọ́nì dé láti ibi gíga tí ó wà ní Gíbéónì,+ láti iwájú àgọ́ ìpàdé,+ sí Jerúsálẹ́mù, ó sì ń bá a lọ láti jọba lé Ísírẹ́lì lórí.+ 14  Sólómọ́nì sì ń kó kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹṣin ogun jọ, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi wá ní egbèje kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹgbẹ̀rún méjìlá ẹṣin ogun,+ ó sì yàn wọ́n sí àwọn ìlú ńlá kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ àti sí tòsí ọba ní Jerúsálẹ́mù. 15  Ọba sì wá ṣe fàdákà àti wúrà tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù bí àwọn òkúta;+ ó sì ṣe igi kédárì bí àwọn igi síkámórè+ tí ó wà ní Ṣẹ́fẹ́là+ ní ti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ. 16  A sì ń kó àwọn ẹṣin ránṣẹ́ sí Sólómọ́nì láti Íjíbítì,+ àwùjọ ẹgbẹ́ àwọn olówò ọba a sì fúnra wọn gba agbo ẹṣin náà ní iye owó kan.+ 17  Wọ́n sì sábà máa ń gbé kẹ̀kẹ́ ẹṣin gòkè wá, wọn a sì fi í ránṣẹ́ láti Íjíbítì fún ẹgbẹ̀ta ẹyọ fàdákà àti ẹṣin kan fún àádọ́jọ; bí ó sì ti rí nìyẹn fún gbogbo ọba àwọn ọmọ Hétì àti àwọn ọba Síríà.+ Ipasẹ̀ wọn ni wọ́n gbà ń ṣe ìfiránṣẹ́ náà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé