Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Àwọn Ọba 9:1-37

9  Èlíṣà wòlíì, ní tirẹ̀, sì pe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ àwọn wòlíì,+ ó sì wá sọ fún un pé: “Di abẹ́nú rẹ lámùrè, kí o sì mú ṣágo+ òróró yìí dání, kí o sì lọ sí Ramoti-gílíádì.+  Nígbà tí o bá ti wọ ibẹ̀, kí o lọ rí Jéhù+ ọmọkùnrin Jèhóṣáfátì ọmọkùnrin Nímúṣì níbẹ̀; kí o sì wọlé, kí o sì mú kí ó dìde kúrò láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀, kí o sì mú un wá sínú ìyẹ̀wù inú pátápátá.+  Kí o sì mú ṣágo òróró náà kí o sì dà á sí i ní orí,+ kí o sì sọ pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Mo fòróró yàn+ ọ́ gẹ́gẹ́ bí ọba+ lórí Ísírẹ́lì.”’ Kí o sì ṣí ilẹ̀kùn, kí o sì sá lọ, kí o má sì dúró.”  Ẹmẹ̀wà náà, ẹmẹ̀wà wòlíì, sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí Ramoti-gílíádì.  Nígbà tí ó wọlé, họ́wù, àwọn olórí ẹgbẹ́ ológun rèé ní ìjókòó. Wàyí o, ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ wà fún ọ,+ balógun.” Látàrí èyí, Jéhù sọ pé: “Fún èwo nínú gbogbo wa?”+ Nígbà náà ni ó sọ pé: “Fún ìwọ, balógun.”  Nítorí náà, ó dìde, ó sì wá sínú ilé; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí da òróró sí i ní orí, ó sì sọ fún un pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Mo fòróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí ọba+ lórí àwọn ènìyàn Jèhófà,+ èyíinì ni, lórí Ísírẹ́lì.  Kí ìwọ sì ṣá ilé olúwa rẹ Áhábù balẹ̀, èmi yóò sì gbẹ̀san+ ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì àti ẹ̀jẹ̀ gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́wọ́ Jésíbẹ́lì.+  Gbogbo ilé Áhábù yóò sì ṣègbé; èmi yóò sì ké ẹnikẹ́ni tí ń tọ̀ sí ara ògiri+ kúrò lọ́dọ̀ Áhábù+ àti ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní olùrànlọ́wọ́ àti aláìníláárí+ ní Ísírẹ́lì.  Èmi yóò ṣe ilé Áhábù bí ilé Jèróbóámù+ ọmọkùnrin Nébátì àti bí ilé Bááṣà+ ọmọkùnrin Áhíjà. 10  Jésíbẹ́lì sì ni àwọn ajá yóò jẹ+ ní abá ilẹ̀ tí ó wà ní Jésíréélì, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò sin ín.’” Látàrí ìyẹn, ó ṣí ilẹ̀kùn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ.+ 11  Ní ti Jéhù, ó jáde tọ àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀ lọ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún un pé: “Ṣé kò sí o?+ Èé ṣe tí ayírí yìí+ fi wọlé tọ̀ ọ́ wá?” Ṣùgbọ́n ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin fúnra yín mọ ọkùnrin náà dáadáa, àti irú ọ̀rọ̀ tí ó máa ń sọ.” 12  Ṣùgbọ́n wọ́n sọ pé: “Èké ni! Jọ̀wọ́, sọ fún wa.” Nígbà náà ni ó sọ pé: “Báyìí-báyìí ni ó sọ fún mi, pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Mo fòróró yàn ọ́ ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì.”’”+ 13  Látàrí èyí, wéréwéré, olúkúlùkù wọn mú ẹ̀wù rẹ̀,+ wọ́n sì fi í sí abẹ́ rẹ̀ lórí àwọn àtẹ̀gùn borokoto, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fun ìwo,+ wọ́n sì sọ pé: “Jéhù ti di ọba!”+ 14  Jéhù+ ọmọkùnrin Jèhóṣáfátì ọmọkùnrin Nímúṣì+ sì bẹ̀rẹ̀ sí di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun+ sí Jèhórámù. Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, Jèhórámù alára ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ ní Ramoti-gílíádì,+ òun pẹ̀lú gbogbo Ísírẹ́lì, nítorí ti Hásáélì+ ọba Síríà. 15  Lẹ́yìn náà, Jèhórámù+ ọba padà láti gba ìmúláradá ní Jésíréélì+ nínú ọgbẹ́ tí àwọn ará Síríà dá sí i lára nígbà tí ó bá Hásáélì ọba Síríà jà.+ Wàyí o, Jéhù sọ pé: “Bí ọkàn yín bá gbà bẹ́ẹ̀,+ ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sá lọ láti inú ìlú ńlá láti lọ ròyìn ní Jésíréélì.” 16  Jéhù sì bẹ̀rẹ̀ sí gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin lọ sí Jésíréélì; nítorí Jèhórámù dùbúlẹ̀ sí ibẹ̀, Ahasáyà+ ọba Júdà pàápàá sì ti sọ̀ kalẹ̀ lọ wo Jèhórámù. 17  Olùṣọ́+ sì dúró sórí ilé gogoro+ tí ó wà ní Jésíréélì,+ ó sì wá rí ìrọ́sókèsódò àgbájọ ènìyàn Jéhù bí ó ṣe ń bọ̀, kíákíá ó sì sọ pé: “Mo ń rí ìrọ́sókèsódò àgbájọ ènìyàn.” Látàrí ìyẹn, Jèhórámù sọ pé: “Mú agẹṣinjagun kan, kí o sì rán an lọ pàdé wọn, kí ó sì sọ pé, ‘Ṣé àlàáfíà ni?’”+ 18  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, olùgun ẹṣin kan sì lọ pàdé rẹ̀, ó sì sọ pé: “Èyí ni ohun tí ọba wí, ‘Ṣé àlàáfíà ni?’” Ṣùgbọ́n Jéhù sọ pé: “Kí ni o ní í fi ‘àlàáfíà’ ṣe?+ Bọ́ sẹ́yìn mi!” Olùṣọ́+ sí tẹ̀ síwájú láti ròyìn, pé: “Ońṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tíì padà.” 19  Nítorí náà, ó rán olùgun ẹṣin kejì jáde lórí ẹṣin, ẹni tí ó jẹ́ pé, nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ wọn, ó tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Èyí ni ohun tí ọba wí, ‘Ṣé àlàáfíà ni?’” Ṣùgbọ́n Jéhù sọ pé: “Kí ni o ní í fi ‘àlàáfíà’ ṣe?+ Bọ́ sẹ́yìn mi!” 20  Olùṣọ́ sì tẹ̀ síwájú láti ròyìn, pé: “Ó dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tíì padà; ìṣọwọ́gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ sì dà bí ìṣọwọ́gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin Jéhù+ ọmọ-ọmọ Nímúṣì,+ nítorí àsápajúdé eré ni ó ń sá.”+ 21  Látàrí ìyẹn, Jèhórámù sọ pé: “Di kẹ̀kẹ́ ẹṣin!”+ Nítorí náà, wọ́n di kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀, Jèhórámù ọba Ísírẹ́lì àti Ahasáyà+ ọba Júdà sì jáde lọ, olúkúlùkù nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun tirẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń jáde lọ pàdé Jéhù, wọ́n wá bá a ní abá ilẹ̀ Nábótì+ ará Jésíréélì. 22  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí Jèhórámù rí Jéhù, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó sọ pé: “Ṣé àlàáfíà ni, Jéhù?” Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Àlàáfíà báwo,+ níwọ̀n ìgbà tí ìwà àgbèrè Jésíbẹ́lì+ ìyá rẹ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àjẹ́ rẹ̀ bá ń bẹ?”+ 23  Lójú-ẹsẹ̀, Jèhórámù yí ọwọ́ rẹ̀ padà, pé kí òun lè sá lọ, ó sì sọ fún Ahasáyà pé: “Àgálámàṣà rèé,+ Ahasáyà!” 24  Jéhù alára sì gbá ọrun+ mú, ó sì tẹ̀ síwájú láti ta Jèhórámù láàárín àwọn apá rẹ̀, tí ọfà náà fi gba ti ọkàn-àyà rẹ̀ jáde, ó sì wó sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀.+ 25  Wàyí o, ó sọ fún Bídíkárì tí í ṣe olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ lójú ogun pé:+ “Gbé e; sọ ọ́ sínú abá pápá Nábótì ará Jésíréélì;+ nítorí, rántí pé: Èmi pẹ̀lú rẹ ń gun ọ̀wọ́ ẹṣin àsomọ́-kẹ̀kẹ́ lẹ́yìn Áhábù baba rẹ̀, Jèhófà fúnra rẹ̀ sì gbé ọ̀rọ̀ ìkéde+ yìí dìde lòdì sí i pé: 26  ‘“Dájúdájú, mo rí ẹ̀jẹ̀+ Nábótì àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ rẹ̀+ lánàá,” ni àsọjáde Jèhófà, “dájúdájú, èmi yóò san án padà+ fún ọ ní abá ilẹ̀ yìí,” ni àsọjáde Jèhófà.’ Ǹjẹ́ nísinsìnyí, gbé e; sọ ọ́ sínú abá ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà.”+ 27  Ahasáyà+ ọba Júdà alára sì rí i, ó sì fẹsẹ̀ fẹ gba ti ọ̀nà ilé ọgbà.+ (Lẹ́yìn náà, Jéhù bẹ̀rẹ̀ sí lépa rẹ̀, ó sì sọ pé: “Àti òun náà! Ẹ ṣá a balẹ̀!” [Nítorí náà, wọ́n ṣá a balẹ̀] bí ó ti wà nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin lójú ọ̀nà àtigòkè lọ sí Gúrì, èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Íbíléámù.+ Ó sì ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀fẹ lọ sí Mẹ́gídò,+ ó sì wá kú sí ibẹ̀.+ 28  Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi kẹ̀kẹ́ ẹṣin gbé e lọ sí Jerúsálẹ́mù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sin ín sí sàréè rẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Ńlá Dáfídì.+ 29  Ọdún kọkànlá Jèhórámù+ ọmọkùnrin Áhábù sì ni Ahasáyà+ di ọba lórí Júdà.) 30  Níkẹyìn, Jéhù dé Jésíréélì,+ Jésíbẹ́lì+ alára sì gbọ́. Ó sì tẹ̀ síwájú láti lé+ tìróò sójú, ó sì ṣe orí rẹ̀ lọ́nà tí ó lẹ́wà,+ ó sì bojú wolẹ̀ láti ojú fèrèsé.+ 31  Jéhù alára sì gba ti ẹnubodè wọlé. Obìnrin náà sì sọ pé: “Nǹkan ha lọ dáadáa fún Símírì+ ẹni tí ó pa olúwa rẹ̀ bí?” 32  Látàrí ìyẹn, ó gbé ojú rẹ̀ sókè wo fèrèsé náà, ó sì sọ pé: “Ta ní wà pẹ̀lú mi? Ta ni?”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ méjì tàbí mẹ́ta láàfin+ bojú wò ó nísàlẹ̀. 33  Nítorí náà, ó sọ pé: “Ẹ ré e bọ́!”+ Nígbà náà ni wọ́n ré e bọ́, lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì fún ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀ sára ògiri àti sára àwọn ẹṣin; òun sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀+ wàyí. 34  Lẹ́yìn ìyẹn, ó wọlé wá, ó jẹ, ó sì mu, ó sì wá sọ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ bójú tó ẹni ègún yìí,+ kí ẹ sì sin ín, nítorí ọmọbìnrin ọba ni.”+ 35  Nígbà tí wọ́n lọ láti sin ín, wọn kò rí kí ohunkóhun ṣẹ́ kù lára rẹ̀ bí kò ṣe agbárí àti ẹsẹ̀ àti àwọn àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀.+ 36  Nígbà tí wọ́n padà tí wọ́n sì sọ fún un, ó tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà ni, tí ó sọ nípasẹ̀+ ìránṣẹ́ rẹ̀ Èlíjà ará Tíṣíbè, pé, ‘Abá ilẹ̀ tí ó wà ní Jésíréélì ni ajá yóò ti jẹ ẹran ara Jésíbẹ́lì.+ 37  Dájúdájú, òkú Jésíbẹ́lì yóò sì di ajílẹ̀+ lórí pápá abá ilẹ̀ tí ó wà ní Jésíréélì, kí wọ́n má bàa sọ pé: “Jésíbẹ́lì nìyí.”’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé