Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Àwọn Ọba 6:1-33

6  Àwọn ọmọ àwọn wòlíì+ sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Èlíṣà pé: “Wò ó ná! Ibi+ tí àwa ń gbé níwájú rẹ ti há+ jù fún wa.  Jọ̀wọ́, jẹ́ kí a lọ títí dé Jọ́dánì, kí olúkúlùkù wa sì gbé ìtì igi kọ̀ọ̀kan láti ibẹ̀, kí a sì ṣe ibì kan fún ara wa+ níbẹ̀ láti máa gbé.” Nítorí náà, ó sọ pé: “Ẹ lọ.”  Ọ̀kan báyìí sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Dákun, jọ̀wọ́, bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ lọ.” Látàrí ìyẹn, ó sọ pé: “Èmi alára yóò lọ.”  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó bá wọn lọ, níkẹyìn wọ́n dé Jọ́dánì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gé àwọn igi lulẹ̀.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé ọ̀kan báyìí ń gé ìtì igi tirẹ̀, irin àáké+ sì bọ́ sínú omi. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde, ó sì sọ pé: “Págà, ọ̀gá+ mi, ṣe ni a yá+ a!”  Nígbà náà ni ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ sọ pé: “Ibo ni ó bọ́ sí?” Nítorí náà, ó fi ibẹ̀ hàn án. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó gé igi kan, ó sì sọ ọ́ sí ibẹ̀, ó sì mú kí irin àáké náà léfòó.+  Ó wá sọ pé: “Fúnra rẹ mú un sókè.” Kíákíá, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mú un.  Ọba Síríà,+ ní tirẹ̀, ń bá Ísírẹ́lì jagun. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó fọ̀ràn lọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,+ ó wí pé: “Ibi báyìí-báyìí ni ẹ óò dó sí pẹ̀lú mi.”+  Nígbà náà ni ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́+ ránṣẹ́ sí ọba Ísírẹ́lì, pé: “Ṣọ́ ara rẹ ní ti gbígba ibí kọjá,+ nítorí pé ibẹ̀ ni àwọn ará Síríà ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ wá sí.”+ 10  Nítorí náà, ọba Ísírẹ́lì ránṣẹ́ sí ibi tí ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ wí fún un.+ Ó sì kìlọ̀ fún un,+ ó sì yẹra fún ibẹ̀, kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì. 11  Nítorí náà, ọkàn-àyà ọba Síríà kún fún ìhónú lórí ọ̀ràn+ yìí, tí ó fi pe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, tí ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin kì yóò ha sọ ẹni tí í ṣe ti ọba Ísírẹ́lì+ lára àwọn tí ó jẹ́ tiwa fún mi?” 12  Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ pé: “Kò sí ẹnì kankan, olúwa mi ọba, ṣùgbọ́n Èlíṣà+ wòlíì tí ó wà ní Ísírẹ́lì ni ó ń sọ+ àwọn ohun tí o bá sọ nínú yàrá ibùsùn+ rẹ inú lọ́hùn-ún fún ọba Ísírẹ́lì.” 13  Nítorí náà, ó sọ pé: “Ẹ lọ wo ibi tí ó wà, kí n lè ránṣẹ́ láti mú un.”+ Lẹ́yìn náà, a ròyìn fún un, pé: “Òun rèé ní Dótánì.”+ 14  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó rán àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun àti ẹgbẹ́ ológun+ tí ó bùáyà sí ibẹ̀; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dé ní òru, wọ́n sì ká ìlú ńlá náà mọ́. 15  Nígbà tí òjíṣẹ́+ ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ gbéra ní kùtùkùtù láti dìde, tí ó sì jáde, họ́wù, ẹgbẹ́ ológun rèé tí ó fi àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun yí ìlú ńlá náà ká. Lójú ẹsẹ̀, ẹmẹ̀wà rẹ̀ sọ fún un pé: “Págà, ọ̀gá+ mi! Kí ni àwa yóò ṣe?” 16  Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Má fòyà,+ nítorí àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn+ lọ.” 17  Èlíṣà sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà,+ ó sì wí pé: “Jèhófà, jọ̀wọ́, là á ní ojú,+ kí ó lè ríran.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà la ojú ẹmẹ̀wà náà, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ríran; sì wò ó! ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá náà kún fún àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun+ oníná yí Èlíṣà+ ká. 18  Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, Èlíṣà bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, bu ìfọ́jú lu orílẹ̀-èdè yìí.” Nítorí náà, ó bu ìfọ́jú+ lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Èlíṣà. 19  Wàyí o, Èlíṣà sọ fún wọn pé: “Èyí kọ́ ni ọ̀nà, èyí sì kọ́ ni ìlú ńlá náà. Ẹ tẹ̀ lé mi, kí ẹ sì jẹ́ kí n mú yín lọ sọ́dọ̀ ọkùnrin tí ẹ̀yin ń wá.” Bí ó ti wù kí ó rí, ó mú wọ́n lọ sí Samáríà.+ 20  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí wọ́n dé Samáríà, Èlíṣà wá sọ pé: “Jèhófà, la ojú àwọn wọ̀nyí kí wọ́n lè ríran.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà là wọ́n lójú, wọ́n sì ríran; sì kíyè sí i, wọ́n wà ní àárín Samáríà. 21  Wàyí o, ọba Ísírẹ́lì sọ fún Èlíṣà, ní gbàrà tí ó rí wọn, pé: “Ṣé kí n ṣá wọn balẹ̀, ṣé kí n ṣá wọn balẹ̀,+ baba mi?”+ 22  Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣá wọn balẹ̀. Ṣé àwọn tí o ti fi idà rẹ àti ọrun rẹ mú ní òǹdè ni àwọn tí o fẹ́ ṣá balẹ̀?+ Gbé oúnjẹ àti omi kalẹ̀ níwájú wọn, kí wọ́n lè jẹ, kí wọ́n sì mu,+ kí wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ olúwa wọn.” 23  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó se àsè ńláǹlà fún wọn; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ, wọ́n sì mu, lẹ́yìn èyí tí ó rán wọn lọ, wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ olúwa wọn. Àwọn ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí+ ará Síríà kò sì tún jẹ́ wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì mọ́. 24  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà pé Bẹni-hádádì ọba Síríà bẹ̀rẹ̀ sí kó gbogbo ibùdó rẹ̀ jọpọ̀, ó sì gòkè lọ, ó sì sàga+ ti Samáríà. 25  Nígbà tí ó ṣe, ìyàn ńláǹlà mú ní Samáríà,+ sì wò ó! wọ́n sàga tì í títí orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ kan fi wá di ọgọ́rin ẹyọ fàdákà, ìlàrin òṣùwọ̀n káàbù imí+ àdàbà sì di ẹyọ fàdákà márùn-ún. 26  Ó sì ṣẹlẹ̀ bí ọba Ísírẹ́lì ti ń kọjá lọ lórí ògiri pé obìnrin kan ké jáde sí i, pé: “Gbà mí là, olúwa mi ọba!”+ 27  Ó fèsì pé: “Bí Jèhófà kò bá gbà ọ́ là, láti orísun wo ni èmi yóò ti gbà ọ́+ là? ṣé láti ilẹ̀ ìpakà tàbí láti ibi ìfúntí wáìnì tàbí ti òróró?” 28  Ọba sì ń bá a lọ láti sọ fún un pé: “Kí ní ṣe ọ́?” Nítorí náà, ó sọ pé: “Obìnrin yìí ni ó wí fún mi pé, ‘Fi ọmọ rẹ lélẹ̀, kí a lè jẹ ẹ́ lónìí, ọmọ tèmi ni a ó sì jẹ lọ́la.’+ 29  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, a se+ ọmọ mi, a sì jẹ ẹ́.+ Lẹ́yìn náà, mo sọ fún un ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e pé, ‘Fi ọmọ rẹ lélẹ̀, kí a lè jẹ ẹ́.’ Ṣùgbọ́n ó fi ọmọ rẹ̀ pa mọ́.” 30  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ọba gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ obìnrin náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya;+ bí ó sì ti ń kọjá lọ lórí ògiri, àwọn ènìyàn wá rí i, sì wò ó! aṣọ àpò ìdọ̀họ wà nísàlẹ̀, lára rẹ̀. 31  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ṣe sí mi, bẹ́ẹ̀ sì ni kí ó fi kún un, bí orí Èlíṣà ọmọkùnrin Ṣáfátì bá ń bá a lọ ní dídúró lọ́rùn rẹ̀ lónìí!”+ 32  Èlíṣà sì jókòó ní ilé tirẹ̀, àwọn àgbà ọkùnrin sì jókòó pẹ̀lú rẹ̀,+ nígbà tí ó rán ọkùnrin kan láti iwájú rẹ̀. Kí ońṣẹ́ náà tó wọlé wá sọ́dọ̀ rẹ̀, òun alára sọ fún àwọn àgbà ọkùnrin náà pé: “Ǹjẹ́ ẹ rí bí ọmọ òṣìkàpànìyàn+ yìí ṣe ránṣẹ́ láti wá gé orí mi kúrò? Ẹ rí sí i pé: gbàrà tí ońṣẹ́ náà bá dé, ẹ ti ilẹ̀kùn, kí ẹ sì fi ilẹ̀kùn tì í padà sẹ́yìn. Ìró+ ẹsẹ̀ olúwa rẹ̀ kò ha wà lẹ́yìn rẹ̀ bí?” 33  Bí ó ṣì ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ońṣẹ́ náà rèé tí ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ọba sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Kíyè sí i, èyí jẹ́ ìyọnu àjálù láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.+ Èé ṣe tí èmi yóò fi tún máa dúró de Jèhófà?”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé