Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Àwọn Ọba 24:1-20

24  Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀ ni Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì gòkè wá, bí Jèhóákímù sì ṣe di ìránṣẹ́ rẹ̀+ fún ọdún mẹ́ta nìyẹn. Bí ó ti wù kí ó rí, ó yí padà, ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí i.  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí rán àwọn ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí tí í ṣe ará Kálídíà+ sí i àti àwọn ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí tí í ṣe ará Síríà àti àwọn ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí àwọn ọmọ Móábù+ àti àwọn ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí àwọn ọmọ Ámónì, ó sì ń rán wọn sí Júdà ṣáá láti pa á run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà+ tí ó sọ nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, wòlíì.  Kìkì pé nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà ni ó fi ṣẹlẹ̀ sí Júdà, láti mú un kúrò+ níwájú rẹ̀ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Mánásè,+ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó ṣe;  àti nítorí ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀+ tí ó ta sílẹ̀ pẹ̀lú, tí ó fi jẹ́ pé ó fi ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ kún Jerúsálẹ́mù, Jèhófà kò sì gbà láti dárí jì.+  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Jèhóákímù+ àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Júdà?  Níkẹyìn, Jèhóákímù dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ Jèhóákínì ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.  Ọba Íjíbítì kò sì tún jẹ́+ jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀+ mọ́, nítorí pé ọba Bábílónì ti gba gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti ọba Íjíbítì,+ láti àfonífojì olójú ọ̀gbàrá+ ti Íjíbítì títí dé Odò Yúfírétì.+  Ẹni ọdún méjìdínlógún ni Jèhóákínì+ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, oṣù mẹ́ta sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Néhúṣítà ọmọbìnrin Élínátánì ti Jerúsálẹ́mù.  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí baba rẹ̀ ṣe.+ 10  Ní àkókò yẹn ni àwọn ìránṣẹ́ Nebukadinésárì ọba Bábílónì gòkè wá sí Jerúsálẹ́mù, tí ìlú ńlá náà fi wá sábẹ̀ ìsàgatì.+ 11  Nebukadinésárì ọba Bábílónì sì bẹ̀rẹ̀ sí gbéjà ko ìlú ńlá náà, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ti sàga tì í.+ 12  Nígbà tí ó ṣe, Jèhóákínì ọba Júdà jáde tọ ọba Bábílónì+ lọ, ti òun ti ìyá rẹ̀+ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ọmọ aládé rẹ̀ àti àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ láàfin; ọba Bábílónì sì mú un ní ọdún kẹjọ+ tí ó jẹ ọba. 13  Nígbà náà ni ó kó gbogbo ìṣúra ilé Jèhófà àti ìṣúra ilé ọba+ jáde kúrò níbẹ̀, ó sì tẹ̀ síwájú láti ké gbogbo nǹkan èlò wúrà+ tí Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì ṣe sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà sí wẹ́wẹ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe sọ. 14  Ó sì kó gbogbo Jerúsálẹ́mù àti gbogbo ọmọ aládé+ àti gbogbo akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin+ lọ sí ìgbèkùn+—ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni ó kó lọ sí ìgbèkùn—àti gbogbo oníṣẹ́ ọnà+ àti àwọn tí ń kọ́ àwọn odi ààbò pẹ̀lú. Kò fi ẹnikẹ́ni sílẹ̀ sẹ́yìn bí kò ṣe ìsọ̀rí àwọn ẹni rírẹlẹ̀+ lára àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. 15  Bí ó ṣe mú Jèhóákínì+ lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì nìyẹn;+ ìyá ọba+ àti àwọn aya ọba àti àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ láàfin+ àti àwọn tí ó wà ní ipò iwájú ní ilẹ̀ náà ni ó sì kó lọ gẹ́gẹ́ bí àwọn ìgbèkùn láti Jerúsálẹ́mù sí Bábílónì. 16  Ní ti gbogbo àwọn akíkanjú, ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin, àti àwọn oníṣẹ́ ọnà àti àwọn tí ń kọ́ àwọn odi ààbò, ẹgbẹ̀rún kan, gbogbo àwọn alágbára ńlá tí ń ja ogun, ọba Bábílónì bẹ̀rẹ̀ sí kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí Bábílónì.+ 17  Síwájú sí i, ọba Bábílónì+ fi Matanáyà arákùnrin òbí rẹ̀+ jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó yí orúkọ rẹ̀ padà sí Sedekáyà.+ 18  Ẹni ọdún mọ́kànlélógún ni Sedekáyà+ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mọ́kànlá sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Hámútálì+ ọmọbìnrin Jeremáyà láti Líbínà. 19  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Jèhóákímù ti ṣe.+ 20  Nítorí pé, ní tìtorí ìbínú+ Jèhófà ni ó fi ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù àti ní Júdà, títí ó fi gbá wọn dànù kúrò níwájú rẹ̀.+ Sedekáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Bábílónì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé