Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Àwọn Ọba 23:1-37

23  Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́, wọ́n sì kó gbogbo àwọn àgbà ọkùnrin Júdà àti Jerúsálẹ́mù jọ+ sọ́dọ̀ rẹ̀.  Lẹ́yìn ìyẹn, ọba gòkè lọ sí ilé Jèhófà, àti gbogbo ènìyàn Júdà àti gbogbo àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú rẹ̀, àti àwọn àlùfáà+ àti àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn ènìyàn náà pẹ̀lú, láti ẹni kékeré dé ẹni ńlá;+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ka+ gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé+ májẹ̀mú+ náà tí a rí ní ilé Jèhófà+ sí etí wọn.  Ọba sì wà ní ìdúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọwọ̀n,+ ó sì dá májẹ̀mú+ wàyí níwájú Jèhófà, láti tọ Jèhófà lẹ́yìn,+ àti láti fi gbogbo ọkàn-àyà+ àti gbogbo ọkàn+ pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́+ àti àwọn gbólóhùn ẹ̀rí rẹ̀+ àti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀,+ nípa mímú ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí tí a kọ sínú ìwé+ yìí ṣe. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, gbogbo àwọn ènìyàn náà mú ìdúró wọn nínú májẹ̀mú náà.+  Ọba sì tẹ̀ síwájú láti pàṣẹ fún Hilikáyà+ àlùfáà àgbà àti àwọn àlùfáà tí ó wà ní ipò kejì àti àwọn olùṣọ́nà+ pé kí wọ́n kó gbogbo nǹkan èlò tí a ṣe fún Báálì+ àti fún òpó ọlọ́wọ̀+ àti fún gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run+ jáde kúrò nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà. Lẹ́yìn náà, ó fi iná sun wọ́n ní òde Jerúsálẹ́mù lórí ilẹ̀ onípele títẹ́jú tí ó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Kídírónì,+ ó sì kó ekuru wọn wá sí Bẹ́tẹ́lì.+  Ó sì mú àwọn àlùfáà ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè kúrò lẹ́nu iṣẹ́ àmójútó, àwọn ẹni tí ọba Júdà fi síbẹ̀ láti máa rú èéfín ẹbọ lórí àwọn ibi gíga nínú àwọn ìlú ńlá Júdà àti ní àwọn àyíká Jerúsálẹ́mù, àti àwọn tí ń rú èéfín ẹbọ sí Báálì,+ sí oòrùn àti sí òṣùpá àti sí àwọn àgbájọ ìràwọ̀ sódíákì àti sí gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run pẹ̀lú.+  Síwájú sí i, ó gbé òpó ọlọ́wọ̀+ jáde kúrò ní ilé Jèhófà sí ẹ̀yìn odi Jerúsálẹ́mù, sí àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kídírónì, ó sì fi iná sun ún+ ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kídírónì, ó sì lọ̀ ọ́ di ekuru, ó sì da ekuru rẹ̀ sórí ibi ìsìnkú+ àwọn ọmọ àwọn ènìyàn náà.  Síwájú sí i, ó bi àwọn ilé kárùwà ọkùnrin inú tẹnpili+ tí ó wà nínú ilé Jèhófà wó, níbi tí àwọn obìnrin ti ń hun àgọ́ ojúbọ fún òpó ọlọ́wọ̀.  Nígbà náà ni ó kó gbogbo àwọn àlùfáà wá láti àwọn ìlú ńlá Júdà, kí ó bàa lè sọ àwọn ibi gíga tí àwọn àlùfáà ti rú èéfín ẹbọ, láti Gébà+ títí dé Bíá-ṣébà,+ di aláìyẹ fún ìjọsìn; ó sì bi àwọn ibi gíga ẹnubodè tí ó wà ní ibi àtiwọ ẹnubodè Jóṣúà, olórí ìlú ńlá náà wó, èyí tí ó wà ní apá òsì bí ènìyàn bá ti ń wọ ẹnubodè ìlú ńlá náà.  Kìkì pé àwọn àlùfáà+ ibi gíga kì yóò gòkè wá síbi pẹpẹ Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù, ṣùgbọ́n wọ́n ń jẹ àkàrà aláìwú+ láàárín àwọn arákùnrin wọn. 10  Ó sì sọ Tófétì+ tí ó wà ní àfonífojì àwọn ọmọ Hínómù+ di aláìyẹ fún ìjọsìn, kí ẹnikẹ́ni má bàa mú ọmọkùnrin rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ la iná+ kọjá sí Mólékì.+ 11  Síwájú sí i, ó mú kí àwọn ẹṣin tí àwọn ọba Júdà fi fún oòrùn ṣíwọ́ gbígba ti yàrá ìjẹun+ Natani-mélékì òṣìṣẹ́ láàfin, èyí tí ó wà ní àwọn ìloro olórùlé, wọnú ilé Jèhófà; àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin oòrùn+ ni ó sì fi iná sun. 12  Àwọn pẹpẹ tí ó sì wà lórí òrùlé ti ìyẹ̀wù òrùlé+ Áhásì tí àwọn ọba Júdà mọ, àti àwọn pẹpẹ+ tí Mánásè mọ sínú àgbàlá méjì ní ilé Jèhófà ni ọba bì wó, lẹ́yìn èyí tí ó fọ́ wọn túútúú níbẹ̀, ó sì da ekuru wọn sí àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kídírónì. 13  Àwọn ibi gíga tí ó sì wà ní iwájú+ Jerúsálẹ́mù, èyí tí ó wà ní apá ọ̀tún Òkè Ńlá Ìparun, tí Sólómọ́nì+ ọba Ísírẹ́lì mọ fún Áṣítórétì+ ohun ìríra àwọn ọmọ Sídónì àti fún Kémóṣì+ ohun ìríra Móábù àti fún Mílíkómù+ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí ti àwọn ọmọ Ámónì ni ọba sọ di aláìyẹ fún ìjọsìn. 14  Ó sì fọ́+ àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ sí wẹ́wẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gé àwọn òpó ọlọ́wọ̀ lulẹ̀, ó sì fi àwọn egungun ẹ̀dá ènìyàn kún ipò wọn. 15  Pẹ̀lúpẹ̀lù, pẹpẹ tí ó wà ní Bẹ́tẹ́lì,+ ibi gíga tí Jèróbóámù+ ọmọkùnrin Nébátì ṣe, ẹni tí ó mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀,+ àní pẹpẹ yẹn àti ibi gíga náà ni ó bì wó. Nígbà náà ni ó fi iná sun ibi gíga náà; ó lọ̀ ọ́ di ekuru, ó sì fi iná sun òpó ọlọ́wọ̀ náà. 16  Nígbà tí Jòsáyà yí padà, ó wá rí àwọn ibi ìsìnkú tí ó wà nínú òkè ńlá níbẹ̀. Nítorí náà, ó ránṣẹ́, ó sì kó egungun láti inú àwọn ibi ìsìnkú náà, ó sì sun+ wọ́n lórí pẹpẹ náà, kí ó lè sọ ọ́ di aláìyẹ fún ìjọsìn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà+ tí ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ ti pòkìkí rẹ̀,+ ẹni tí ó pòkìkí nǹkan wọ̀nyí. 17  Lẹ́yìn náà ni ó wí pé: “Èwo ni òkúta sàréè tí mo ń wò níbẹ̀ yẹn?” Látàrí èyí, àwọn ènìyàn ìlú ńlá náà sọ fún un pé: “Ibi ìsìnkú+ ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ ni, ẹni tí ó wá láti Júdà+ tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pòkìkí nǹkan wọ̀nyí tí o ṣe sí pẹpẹ tí ó wà ní Bẹ́tẹ́lì.”+ 18  Nítorí náà, ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ó sinmi.+ Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni yọ egungun rẹ̀ lẹ́nu.” Nítorí náà, wọ́n jọ̀wọ́ egungun rẹ̀ jẹ́ẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú egungun wòlíì+ tí ó wá láti Samáríà. 19  Pẹ̀lúpẹ̀lù, gbogbo ilé+ àwọn ibi gíga tí ó wà ní àwọn ìlú ńlá+ Samáríà, èyí tí àwọn ọba+ Ísírẹ́lì kọ́ láti ṣokùnfà ìmúnibínú+ ni Jòsáyà mú kúrò, ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí gbogbo iṣẹ́ tí ó ṣe ní Bẹ́tẹ́lì.+ 20  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó fi gbogbo àlùfáà+ àwọn ibi gíga tí ó wà níbẹ̀ rúbọ lórí àwọn pẹpẹ náà, ó sì sun àwọn egungun ẹ̀dá ènìyàn lórí wọn.+ Lẹ́yìn ìyẹn, ó padà sí Jerúsálẹ́mù. 21  Wàyí o, ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, pé: “Ẹ ṣe ìrékọjá+ sí Jèhófà Ọlọ́run yín gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé májẹ̀mú yìí.”+ 22  Nítorí pé a kò tíì ṣe ìrékọjá kankan bí irú èyí láti ọjọ́ àwọn onídàájọ́ tí ó ti ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì,+ tàbí ní gbogbo ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì àti àwọn ọba Júdà.+ 23  Ṣùgbọ́n ní ọdún kejìdínlógún Jòsáyà Ọba, a ṣe ìrékọjá yìí fún Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù.+ 24  Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn abẹ́mìílò+ àti àwọn olùsàsọtẹ́lẹ̀+ ìṣẹ̀lẹ̀ àti ère tẹ́ráfímù+ àti àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ+ àti gbogbo ohun ìríra+ tí ó fara hàn ní ilẹ̀ Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù ni Jòsáyà kó kúrò, kí ó lè mú àwọn ọ̀rọ̀ òfin+ tí a kọ sínú ìwé+ tí Hilikáyà àlùfáà rí ní ilé Jèhófà+ ṣẹ. 25  Ṣáájú rẹ̀, kò sí ọba kankan bí tirẹ̀, tí ó fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀ àti gbogbo ọkàn rẹ̀+ àti gbogbo okunra rẹ̀ padà+ sọ́dọ̀ Jèhófà, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin Mósè; bẹ́ẹ̀ ni kò tíì sí ìkankan tí ó dìde bí tirẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀. 26  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jèhófà kò yí padà kúrò nínú jíjófòfò ìbínú rẹ̀, èyí tí ìbínú rẹ̀ fi jó lòdì sí Júdà+ nítorí gbogbo ohun amúnibínú, èyí tí Mánásè mú kí wọ́n fi mú un bínú.+ 27  Ṣùgbọ́n Jèhófà wí pé: “Júdà,+ pẹ̀lú, ni èmi yóò mú kúrò níwájú mi,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ṣe mú Ísírẹ́lì kúrò;+ dájúdájú, èmi yóò sì kọ ìlú ńlá yìí tí mo yàn, àní Jerúsálẹ́mù, àti ilé tí mo sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Orúkọ mi yóò máa wà níbẹ̀.’”+ 28  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Jòsáyà àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Júdà? 29  Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀ ni Fáráò Nẹ́kò+ ọba Íjíbítì gòkè wá bá ọba Ásíríà lẹ́bàá Odò Yúfírétì,+ Jòsáyà Ọba sì tẹ̀ síwájú láti lọ pàdé rẹ̀;+ ṣùgbọ́n ó fi ikú pa á+ ní Mẹ́gídò+ ní gbàrà tí ó rí i. 30  Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbé e ní òkú sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin láti Mẹ́gídò, wọ́n sì gbé e wá sí Jerúsálẹ́mù,+ wọ́n sì sin ín sí sàréè rẹ̀. Nígbà náà ni àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú Jèhóáhásì+ ọmọkùnrin Jòsáyà, wọ́n sì fòróró yàn án, wọ́n sì fi í jẹ ọba ní ipò baba rẹ̀. 31  Ẹni ọdún mẹ́tàlélógún ni Jèhóáhásì+ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, oṣù mẹ́ta sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Hámútálì+ ọmọbìnrin Jeremáyà láti Líbínà. 32  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá rẹ̀ ṣe.+ 33  Fáráò Nẹ́kò+ sì fi í sí inú àwọn ìdè+ ní Ríbúlà+ ní ilẹ̀ Hámátì, láti má ṣe jẹ́ kí ó jọba ní Jerúsálẹ́mù, ó sì wá bu owó ìtanràn+ lé ilẹ̀ náà, ọgọ́rùn-ún tálẹ́ńtì fàdákà+ àti tálẹ́ńtì wúrà kan.+ 34  Síwájú sí i, Fáráò Nẹ́kò fi Élíákímù+ ọmọkùnrin Jòsáyà jẹ ọba ní ipò Jòsáyà baba rẹ̀, ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Jèhóákímù; Jèhóáhásì ni ó sì mú, ó sì mú un wá sí Íjíbítì, níbi tí ó kú sí ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.+ 35  Fàdákà+ àti wúrà náà ni Jèhóákímù sì fi fún Fáráò. Kìkì pé ó bu owó orí lé+ ilẹ̀ náà, láti lè mú fàdákà náà wá nípa àṣẹ ìtọ́ni Fáráò. Gẹ́gẹ́ bí iye owó orí olúkúlùkù+ ni ó ṣe fi tipátipá gba fàdákà àti wúrà náà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, láti fi í fún Fáráò Nẹ́kò. 36  Ẹni ọdun mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni Jèhóákímù+ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mọ́kànlá sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Sébídà ọmọbìnrin Pedáyà láti Rúmà. 37  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú+ ní ojú Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá rẹ̀ ṣe.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé