Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Àwọn Ọba 22:1-20

22  Ẹni ọdún mẹ́jọ ni Jòsáyà+ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jédídà ọmọbìnrin Ádáyà láti Bósíkátì.+  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà,+ ó sì ń rìn ní gbogbo ọ̀nà Dáfídì baba ńlá rẹ̀,+ kò sì yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọdún kejìdínlógún Jòsáyà Ọba pé ọba rán Ṣáfánì+ ọmọkùnrin Asaláyà ọmọkùnrin Méṣúlámù akọ̀wé sí ilé Jèhófà, pé:  “Gòkè tọ Hilikáyà+ àlùfáà àgbà+ lọ, kí ó sì kó owó tí a mú wá sí ilé Jèhófà+ jọ,+ èyí tí àwọn olùṣọ́nà+ ti kó jọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn náà;  kí wọ́n sì fi í lé ọwọ́ àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ náà,+ àwọn tí a yàn sípò, nínú ilé Jèhófà, kí wọ́n lè fi í fún àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ náà, àwọn tí wọ́n wà nínú ilé Jèhófà láti tún àwọn ibi tí ó sán lára ilé náà ṣe,+  fún àwọn oníṣẹ́ ọnà àti àwọn akọ́lé àti àwọn ọ̀mọ̀lé, àti láti ra àwọn ẹ̀là gẹdú àti àwọn òkúta gbígbẹ́ láti tún ilé náà ṣe.+  Kìkì pé kí a má ṣe ṣírò owó tí ó wà lọ́dọ̀ wọn sí ọwọ́ ẹni tí a ń fi í sí,+ nítorí pé ìṣòtítọ́+ ni wọ́n fi ń ṣiṣẹ́.”  Lẹ́yìn náà, Hilikáyà+ àlùfáà àgbà wí fún Ṣáfánì+ akọ̀wé pé:+ “Ìwé òfin+ gan-an ni mo ti rí ní ilé Jèhófà.” Nítorí náà, Hilikáyà fi ìwé náà fún Ṣáfánì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kà á.  Nígbà náà ni Ṣáfánì akọ̀wé wọlé wá sọ́dọ̀ ọba, ó sì fún ọba lésì, ó sì sọ pé: “Àwọn ìránṣẹ́ rẹ ti da owó tí a rí nínú ilé náà, wọ́n sì ń bá a nìṣó láti fi í lé ọwọ́ àwọn olùṣe iṣẹ́ náà, àwọn tí a yàn sípò, nínú ilé Jèhófà.”+ 10  Ṣáfánì akọ̀wé sì ń bá a lọ láti sọ fún ọba, pé: “Ìwé+ kan wà tí Hilikáyà àlùfáà fi fún mi.” Ṣáfánì sì bẹ̀rẹ̀ sí kà á níwájú ọba. 11  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ọba gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìwé òfin náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya.+ 12  Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Hilikáyà àlùfáà àti Áhíkámù+ ọmọkùnrin Ṣáfánì àti Ákíbórì ọmọkùnrin Mikáyà àti Ṣáfánì akọ̀wé àti Ásáyà+ ìránṣẹ́ ọba, pé: 13  “Ẹ lọ, ẹ wádìí+ lọ́dọ̀ Jèhófà, nítorí tèmi àti nítorí ti àwọn ènìyàn àti nítorí ti gbogbo Júdà, nípa àwọn ọ̀rọ̀ ìwé yìí tí a rí; nítorí títobí ni ìhónú Jèhófà+ tí a mú gbaná jẹ sí wa nítorí òtítọ́ náà pé àwọn baba ńlá+ wa kò fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ ìwé yìí nípa ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí a kọ nípa wa.”+ 14  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Hilikáyà àlùfáà àti Áhíkámù àti Ákíbórì àti Ṣáfánì àti Ásáyà lọ sọ́dọ̀ Húlídà wòlíì obìnrin,+ aya Ṣálúmù ọmọkùnrin Tíkífà ọmọkùnrin Háhásì, olùbójútó àwọn ẹ̀wù,+ bí ó ti ń gbé ní Jerúsálẹ́mù ní ìhà kejì; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a sọ̀rọ̀.+ 15  Ẹ̀wẹ̀, ó wí fún wọn pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí,+ ‘Ẹ wí fún ọkùnrin tí ó rán yín wá sọ́dọ̀ mi pé: 16  “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù+ wá sórí ibí yìí àti sórí àwọn olùgbé rẹ̀,+ àní gbogbo ọ̀rọ̀+ ìwé tí ọba Júdà kà;+ 17  nítorí òtítọ́ náà pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀, tí wọ́n sì lọ ń rú èéfín ẹbọ sí àwọn ọlọ́run mìíràn,+ kí wọ́n lè fi gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn+ mú mi bínú, ìhónú mi sì ni a ti mú gbaná jẹ sí ibí yìí, a kì yóò sì fẹ́ ẹ pa.’”’+ 18  Àti ní ti ọba Júdà tí ó rán yín láti wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, èyí ni ohun tí ẹ óò wí fún un, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Ní ti àwọn ọ̀rọ̀ tí o ti gbọ́,+ 19  nítorí ìdí náà pé ọkàn-àyà rẹ+ rọ̀ tí ó fi jẹ́ pé o rẹ ara rẹ sílẹ̀+ nítorí Jèhófà bí o ṣe gbọ́ ohun tí mo sọ lòdì sí ibí yìí àti àwọn olùgbé rẹ̀, pé kí ó di ohun ìyàlẹ́nu àti ìfiré,+ tí o sì wá gbọn ẹ̀wù rẹ ya,+ tí o sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún níwájú mi, èmi, àní èmi, ti gbọ́,” ni àsọjáde Jèhófà.+ 20  “Kíyè sí i, ìdí nìyẹn tí èmi yóò fi kó ọ jọ+ sọ́dọ̀ àwọn baba ńlá rẹ, a ó sì kó ọ jọ dájúdájú sínú itẹ́ tìrẹ ní àlàáfíà,+ ojú rẹ kì yóò sì rí gbogbo ìyọnu àjálù tí èmi yóò mú wá sórí ibí yìí.”’” Wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti mú èsì náà wá fún ọba.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé