Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Àwọn Ọba 21:1-26

21  Ẹni ọdún méjìlá ni Mánásè+ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún márùn-dín-lọ́gọ́ta sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Héfísíbà.  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà,+ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí ti àwọn orílẹ̀-èdè+ tí Jèhófà lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.  Nítorí náà, ó tún àwọn ibi gíga tí Hesekáyà baba rẹ̀ ti pa run kọ́,+ ó sì gbé àwọn pẹpẹ kalẹ̀ fún Báálì, ó sì ṣe òpó ọlọ́wọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí Áhábù+ ọba Ísírẹ́lì ti ṣe; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹrí ba+ fún gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run,+ ó sì ń sìn wọ́n.+  Ó sì mọ àwọn pẹpẹ sí ilé Jèhófà,+ èyí tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ pé: “Inú Jerúsálẹ́mù ni èmi yóò fi orúkọ mi sí.”+  Ó sì ń bá a lọ láti mọ àwọn pẹpẹ fún gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run+ sí àgbàlá méjì nínú ilé Jèhófà.+  Ó sì mú ọmọ ara rẹ̀ la iná kọjá,+ ó sì ń pidán,+ ó sì ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀, ó sì mú kí àwọn abẹ́mìílò+ àti àwọn olùsàsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀+ wà. Ní ìwọ̀n púpọ̀ gan-an ni ó ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, láti mú un bínú.  Síwájú sí i, ó gbé ère gbígbẹ́+ ti òpó ọlọ́wọ̀ tí ó ṣe sínú ilé+ tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ fún Dáfídì àti fún Sólómọ́nì ọmọkùnrin rẹ̀ pé: “Inú ilé yìí àti ní Jerúsálẹ́mù, tí mo ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ni èmi yóò fi orúkọ mi sí fún àkókò tí ó lọ kánrin.+  Èmi kì yóò sì tún mú kí ẹsẹ̀ Ísírẹ́lì rìn gbéregbère kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá wọn,+ kìkì bí wọ́n bá sáà ti kíyè sára láti ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún wọn,+ àní ní ti gbogbo òfin tí ìránṣẹ́ mi Mósè pa láṣẹ fún wọn.”  Wọn kò sì fetí sílẹ̀,+ ṣùgbọ́n Mánásè ń bá a nìṣó ní sísún wọn dẹ́ṣẹ̀ láti ṣe ohun tí ó burú+ ju ti àwọn orílẹ̀-èdè+ tí Jèhófà pa rẹ́ ráúráú kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 10  Jèhófà sì ń báa nìṣó ní sísọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì,+ pé: 11  “Nítorí ìdí náà pé Mánásè+ ọba Júdà ti ṣe àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí+ wọ̀nyí, ó ti ṣe burúkú ju gbogbo èyí tí àwọn Ámórì+ ṣe, àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ rẹ̀ mú Júdà pàápàá ṣẹ̀.+ 12  Ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù wá sórí Jerúsálẹ́mù+ àti Júdà, èyí tí ó jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ nípa rẹ̀, etí rẹ̀ méjèèjì yóò hó yee.+ 13  Dájúdájú, èmi yóò sì na okùn ìdiwọ̀n+ tí a lò fún Samáríà+ sórí Jerúsálẹ́mù àti ohun èlò ìmú-nǹkan-tẹ́jú tí a lò fún ilé Áhábù;+ èmi yóò wulẹ̀ nu+ Jerúsálẹ́mù mọ́ gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹní nu àwokòtò aláìní iga-ìdìmú mọ́, ní nínù ún mọ́ àti ní dídojú rẹ̀ délẹ̀.+ 14  Èmi yóò sì ṣá àṣẹ́kù+ ogún mi+ tì ní ti tòótọ́, èmi yóò sì fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, wọn yóò wulẹ̀ di ohun tí a piyẹ́ àti ìkógun lọ́dọ̀ gbogbo ọ̀tá wọn,+ 15  nítorí ìdí náà pé wọ́n ṣe ohun tí ó burú ní ojú mi, tí wọ́n sì ń bá a lọ láti mú mi bínú láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wọn ti jáde wá láti Íjíbítì títí di òní yìí.’”+ 16  Ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ tí Mánásè ta sílẹ̀+ ní ìwọ̀n púpọ̀ gidigidi tún wà pẹ̀lú, títí ó fi mú kí Jerúsálẹ́mù kún láti ìpẹ̀kun dé ìpẹ̀kun, yàtọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó fi mú kí Júdà ṣẹ̀ nípa ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.+ 17  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Mánásè àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Júdà? 18  Níkẹyìn, Mánásè dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ a sì sin ín sínú ọgbà ilé rẹ̀, sínú ọgbà Úúsà;+ Ámọ́nì ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀. 19  Ẹni ọdún méjìlélógún ni Ámọ́nì+ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún méjì+ sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Méṣúlémétì ọmọbìnrin Hárúsì láti Jótíbà. 20  Ó sì ń bá a lọ láti ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, gan-an gẹ́gẹ́ bí Mánásè baba rẹ̀ ti ṣe.+ 21  Ó sì ń rìn ṣáá nínú gbogbo ọ̀nà tí baba rẹ̀ rìn,+ ó sì ń bá a lọ ní sísin àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ+ tí baba rẹ̀ sìn, ó sì ń tẹrí ba fún wọn. 22  Bí ó ṣe fi Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀ sílẹ̀ nìyẹn,+ kò sì rìn ní ọ̀nà Jèhófà.+ 23  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn ìránṣẹ́ Ámọ́nì di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun sí i, wọ́n sì fi ikú pa ọba+ nínú ilé rẹ̀. 24  Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà ṣá gbogbo àwọn tí ó di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun+ sí Ámọ́nì Ọba balẹ̀. Lẹ́yìn náà, àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà fi Jòsáyà+ ọmọkùnrin rẹ̀ jẹ ọba ní ipò rẹ̀. 25  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Ámọ́nì, ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Júdà? 26  Nítorí náà, wọ́n sin ín sí sàréè rẹ̀ nínú ọgbà Úúsà;+ Jòsáyà+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé