Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Àwọn Ọba 20:1-21

20  Ní ọjọ́ wọnnì, Hesekáyà ṣàìsàn dé ojú ikú.+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Aísáyà+ ọmọkùnrin Émọ́sì, tí í ṣe wòlíì, wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Pa àṣẹ fún agbo ilé rẹ,+ nítorí pé ìwọ fúnra rẹ yóò kú ní tòótọ́, ìwọ kì yóò sì yè.’”+  Látàrí ìyẹn, ó yí ojú sí ògiri,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Jèhófà,+ pé:  “Mo fi taratara bẹ̀ ọ́, Jèhófà, jọ̀wọ́, rántí+ bí mo ṣe rìn+ níwájú rẹ nínú òtítọ́+ àti pẹ̀lú ọkàn-àyà pípé pérépéré,+ ohun tí ó dára ní ojú rẹ sì ni mo ṣe.”+ Hesekáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, Aísáyà alára kò tíì jáde lọ sí ìgà àárín nígbà tí ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ̀ ọ́ wá,+ pé:  “Padà lọ, kí o sì sọ fún Hesekáyà aṣáájú+ àwọn ènìyàn mi pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run+ Dáfídì baba ńlá rẹ wí: “Mo ti gbọ́+ àdúrà rẹ.+ Mo ti rí omijé rẹ.+ Kíyè sí i, èmi yóò mú ọ lára dá.+ Ní ọjọ́ kẹta, ìwọ yóò gòkè lọ sí ilé Jèhófà.+  Dájúdájú, èmi yóò sì fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ rẹ, èmi yóò sì dá ìwọ àti ìlú ńlá yìí nídè kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ ọba Ásíríà, èmi yóò sì gbèjà+ ìlú ńlá yìí dájúdájú, nítorí tèmi àti nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi.”’”+  Aísáyà sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Ẹ mú ìṣù+ èso ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ.” Nítorí náà, wọ́n mú un, wọ́n sì fi í sórí oówo náà,+ lẹ́yìn èyí tí ó sàn ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀.+  Láàárín àkókò náà, Hesekáyà sọ fún Aísáyà pé: “Kí ni àmì+ pé Jèhófà yóò mú mi lára dá àti pé èmi yóò gòkè lọ sí ilé Jèhófà ní ọjọ́ kẹta?”  Aísáyà fèsì pé: “Èyí ni àmì+ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà pé Jèhófà yóò mú ọ̀rọ̀ tí ó sọ ṣẹ: Ṣé kí òjìji lọ síwájú ní ìdásẹ̀lé mẹ́wàá lára àtẹ̀gùn tàbí kí ó padà ní ìdásẹ̀lé mẹ́wàá?” 10  Nígbà náà ni Hesekáyà sọ pé: “Ohun tí ó rọrùn ni fún òjìji láti fa ara rẹ̀ gùn síwájú ní ìdásẹ̀lé mẹ́wàá,+ ṣùgbọ́n kì í ṣe pé kí òjìji padà sẹ́yìn ní ìdásẹ̀lé mẹ́wàá.” 11  Látàrí ìyẹn, Aísáyà wòlíì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Jèhófà; ó sì mú kí òjìji tí ó ti sọ̀ kalẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ padà wá sórí àwọn ìdásẹ̀lé náà, èyíinì ni, sára àwọn ìdásẹ̀lé ara àtẹ̀gùn Áhásì, ní ìdásẹ̀lé mẹ́wàá padà sẹ́yìn.+ 12  Ní àkókò yẹn, Berodaki-báládánì+ ọmọkùnrin Báládánì ọba Bábílónì+ fi àwọn lẹ́tà+ àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Hesekáyà; nítorí ó gbọ́ pé Hesekáyà ṣàìsàn. 13  Hesekáyà sì tẹ̀ síwájú láti fetí sí wọn, ó sì fi gbogbo ilé ìṣúra rẹ̀ hàn wọ́n,+ fàdákà àti wúrà+ àti òróró básámù+ àti òróró dáradára àti ilé ìhámọ́ra rẹ̀ àti gbogbo ohun tí a rí nínú àwọn ìṣúra rẹ̀. Kò sí nǹkan kan tí Hesekáyà kò fi hàn wọ́n nínú ilé tirẹ̀ àti nínú gbogbo àgbègbè ìṣàkóso rẹ̀.+ 14  Lẹ́yìn ìyẹn, Aísáyà wòlíì wọlé tọ Hesekáyà Ọba wá, ó sì sọ fún un pé:+ “Kí ni àwọn ọkùnrin wọ̀nyí wí, ibo sì ni wọ́n ti wá sọ́dọ̀ rẹ?”+ Nítorí náà, Hesekáyà wí pé: “Láti ilẹ̀ jíjìnnà ni wọ́n ti wá, láti Bábílónì.” 15  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Kí ni wọ́n rí nínú ilé rẹ?” Hesekáyà fèsì pé: “Ohun gbogbo tí ó wà nínú ilé mi ni wọ́n rí. Kò sí nǹkan kan tí èmi kò fi hàn wọ́n nínú àwọn ìṣúra mi.”+ 16  Aísáyà wá sọ fún Hesekáyà pé: “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà,+ 17  ‘“Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀, gbogbo ohun tí ó sì wà nínú ilé tìrẹ+ àti èyí tí àwọn baba ńlá rẹ ti tò jọ pa mọ́ títí di òní yìí ni a óò kó lọ sí Bábílónì ní ti tòótọ́.+ Kì yóò ṣẹ́ kù nǹkan kan,”+ ni Jèhófà wí. 18  “Àwọn kan lára àwọn ọmọ tìrẹ tí yóò ti inú rẹ jáde wá, àwọn tí ìwọ yóò bí, àwọn pàápàá ni a óò kó,+ ní ti tòótọ́ wọn yóò di òṣìṣẹ́ ààfin+ ní ààfin ọba Bábílónì.”’”+ 19  Látàrí ìyẹn, Hesekáyà wí fún Aísáyà pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ìwọ sọ dára.”+ Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí àlàáfíà àti òtítọ́+ yóò bá máa bá a lọ ní àwọn ọjọ́ mi?”+ 20  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Hesekáyà àti gbogbo agbára ńlá rẹ̀ àti bí ó ti ṣe odò adágún+ àti ọ̀nà omi+ tí ó sì wá fa omi náà wá sínú ìlú ńlá náà, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Júdà? 21  Níkẹyìn, Hesekáyà dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀;+ Mánásè+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé