Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Àwọn Ọba 2:1-25

2  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí Jèhófà fẹ́ fi ìjì ẹlẹ́fùúùfù gbé Èlíjà+ gòkè re ọ̀run,+ Èlíjà àti Èlíṣà+ bẹ̀rẹ̀ sí lọ láti Gílígálì.+  Èlíjà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Èlíṣà pé: “Jọ̀wọ́, jókòó síhìn-ín, nítorí pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ti rán mi lọ tààrà sí Bẹ́tẹ́lì.” Ṣùgbọ́n Èlíṣà sọ pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ,+ àti bí ọkàn rẹ ti ń bẹ,+ èmi kí yóò fi ọ́ sílẹ̀.”+ Nítorí náà, wọ́n sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Bẹ́tẹ́lì.+  Nígbà náà ni àwọn ọmọ àwọn wòlíì+ tí wọ́n wà ní Bẹ́tẹ́lì jáde tọ Èlíṣà wá, wọ́n sì sọ fún un pé: “O ha mọ̀ ní tòótọ́ pé, lónìí, Jèhófà yóò mú ọ̀gá rẹ kúrò ní ṣíṣe olórí rẹ?”+ Látàrí èyí, ó wí pé: “Èmi pẹ̀lú mọ̀ dáadáa.+ Ẹ dákẹ́.”  Wàyí o, Èlíjà sọ fún un pé: “Èlíṣà, jọ̀wọ́, jókòó síhìn-ín, nítorí pé, Jèhófà fúnra rẹ̀ rán mi lọ sí Jẹ́ríkò.”+ Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ, àti bí ọkàn rẹ ti ń bẹ, ó dájú pé èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà, wọ́n wá sí Jẹ́ríkò.  Nígbà náà ni àwọn ọmọ àwọn wòlíì tí wọ́n wà ní Jẹ́ríkò tọ Èlíṣà wá, wọ́n sì sọ fún un pé: “O ha mọ̀ ní tòótọ́ pé, lónìí, Jèhófà yóò mú ọ̀gá rẹ kúrò ní ṣíṣe olórí rẹ?” Látàrí èyí, ó wí pé: “Èmi pẹ̀lú mọ̀ dáadáa. Ẹ dákẹ́.”+  Wàyí o, Èlíjà sọ fún un pé: “Jọ̀wọ́, jókòó síhìn-ín, nítorí pé Jèhófà fúnra rẹ̀ rán mi lọ sí Jọ́dánì.”+ Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ, àti bí ọkàn rẹ ti ń bẹ, ó dájú pé èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀.”+ Nítorí náà, àwọn méjèèjì jọ ń lọ.  Àádọ́ta ọkùnrin lára àwọn ọmọ àwọn wòlíì sì ń bẹ tí ó lọ dúró ní ọ̀kánkán lókèèrè;+ ṣùgbọ́n, ní ti àwọn méjèèjì, wọ́n dúró lẹ́bàá Jọ́dánì.  Nígbà náà ni Èlíjà mú ẹ̀wù oyè+ rẹ̀, ó sì ká a, ó sì lu omi náà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó pín síhìn-ín àti sọ́hùn-ún, tí àwọn méjèèjì fi sọdá lórí ilẹ̀ gbígbẹ.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí wọ́n ti sọdá, Èlíjà fúnra rẹ̀ sọ fún Èlíṣà pé: “Béèrè ohun tí èmi yóò ṣe fún ọ kí a tó mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ.”+ Èlíṣà fèsì pé: “Jọ̀wọ́, kí ipa méjì+ nínú ẹ̀mí+ rẹ lè bà lé mi.”+ 10  Látàrí ìyẹn, ó sọ pé: “Ìwọ béèrè+ ohun kan tí ó ṣòro. Bí o bá rí mi nígbà tí a bá mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ, yóò ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ fún ọ; ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rí mi, kì yóò ṣẹlẹ̀.” 11  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí wọ́n ti ń rìn lọ, tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ bí wọ́n ti ń rìn, họ́wù, wò ó! kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun oníná+ kan àti àwọn ẹṣin oníná, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti pààlà sáàárín àwọn méjèèjì; Èlíjà sì gòkè re ọ̀run+ nínú ìjì ẹlẹ́fùúùfù. 12  Ní gbogbo àkókò náà, Èlíṣà rí i, ó sì ń ké jáde pé: “Baba mi, baba mi,+ kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun Ísírẹ́lì àti àwọn ẹlẹ́ṣin+ rẹ̀!” Òun kò sì rí i mọ́. Nítorí náà, ó di ẹ̀wù ara rẹ̀ mú, ó sì fà á ya sí méjì.+ 13  Lẹ́yìn ìyẹn, ó mú ẹ̀wù oyè+ Èlíjà tí ó já bọ́ lára rẹ̀, ó sì padà, ó sì dúró lẹ́bàá èbúté Jọ́dánì. 14  Nígbà náà ni ó mú ẹ̀wù oyè Èlíjà tí ó já bọ́ lára rẹ̀, ó sì lu omi+ náà, ó sì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Èlíjà dà, àní Òun?”+ Nígbà tí ó lu omi náà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n pín síhìn-ín àti sọ́hùn-ún, tí Èlíṣà fi sọdá. 15  Nígbà tí àwọn ọmọ àwọn wòlíì tí wọ́n wà ní Jẹ́ríkò rí i lókèèrè, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Ẹ̀mí+ Èlíjà ti sọ̀ kalẹ̀ sórí Èlíṣà.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n wá pàdé rẹ̀, wọ́n sì tẹrí ba mọ́lẹ̀+ fún un. 16  Wọ́n sì ń bá a lọ láti sọ fún un pé: “Kíyè sí i, nísinsìnyí, àádọ́ta ọkùnrin, akíkanjú ènìyàn, ń bẹ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ. Jọ̀wọ́, jẹ́ kí wọ́n lọ wá ọ̀gá rẹ. Ó lè jẹ́ pé ẹ̀mí+ Jèhófà gbé e, tí ó sì wá sọ ọ́ sí orí ọ̀kan nínú àwọn òkè ńlá tàbí sínú ọ̀kan nínú àwọn àfonífojì.” Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ rán wọn.” 17  Wọ́n sì ń rọ̀ ọ́ ṣáá, títí ara fi tì í, tí ó fi sọ pé: “Ẹ ránṣẹ́.” Wọ́n wá rán àádọ́ta ọkùnrin; wọ́n sì ń wá a fún ọjọ́ mẹ́ta, ṣùgbọ́n wọn kò rí i. 18  Nígbà tí wọ́n padà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó ń gbé ní Jẹ́ríkò.+ Nígbà náà ni ó sọ fún wọn pé: “Èmi kò ha sọ fún yín pé, ‘Ẹ má lọ’?” 19  Nígbà tí ó ṣe, àwọn ọkùnrin ìlú ńlá náà sọ fún Èlíṣà pé: “Kíyè sí i, nísinsìnyí, ipò tí ìlú ńlá yìí wà dára,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá mi ṣe rí i; ṣùgbọ́n omi+ rẹ̀ burú, ilẹ̀ yìí sì ń fa ìṣẹ́nú.”+ 20  Látàrí ìyẹn, ó sọ pé: “Ẹ wá àwokòtò kékeré tuntun kan wá, kí ẹ sì fi iyọ̀ sínú rẹ̀.” Nítorí náà, wọ́n wá a wá fún un. 21  Nígbà náà ni ó jáde lọ sí orísun omi náà, ó sì da iyọ̀ sínú rẹ̀,+ ó sì sọ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Mo sọ omi yìí di afúnni-nílera.+ Ikú tàbí ohun tí ń fa ìṣẹ́nú kì yóò ti inú rẹ̀ wá mọ́.’” 22  A sì ṣe àwòtán omi náà títí di òní yìí,+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Èlíṣà tí ó sọ. 23  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè láti ibẹ̀ lọ sí Bẹ́tẹ́lì.+ Bí ó ṣe ń gòkè lọ lójú ọ̀nà, àwọn ọmọdékùnrin kéékèèké+ kan wà tí ó jáde wá láti inú ìlú ńlá náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi í ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n ń wí fún un ṣáá pé: “Gòkè lọ, apárí!+ Gòkè lọ, apárí!” 24  Níkẹyìn, ó bojú wo ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì rí wọn, ó sì pe ibi+ wá sórí wọn ní orúkọ Jèhófà. Nígbà náà ni abo béárì+ méjì jáde wá láti inú ẹgàn, wọ́n sì fa méjì-lé-lógójì ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ lára àwọn ọmọ náà.+ 25  Ó ń bá a nìṣó ní lílọ láti ibẹ̀ sí Òkè Ńlá Kámẹ́lì,+ láti ibẹ̀, ó padà sí Samáríà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé