Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Àwọn Ọba 19:1-37

19  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Hesekáyà Ọba+ gbọ́, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya,+ ó sì fi aṣọ àpò ìdọ̀họ bora,+ ó sì wá sínú ilé Jèhófà.+  Síwájú sí i, ó rán Élíákímù,+ ẹni tí ń bójú tó agbo ilé, àti Ṣẹ́bínà+ akọ̀wé àti àwọn àgbà ọkùnrin nínú àwọn àlùfáà tí wọ́n fi aṣọ àpò ìdọ̀họ bora sí Aísáyà+ wòlíì, ọmọkùnrin Émọ́sì.+  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún un pé: “Èyí ni ohun tí Hesekáyà wí, ‘Ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ wàhálà+ àti ti ìbáwí mímúná+ àti ti àfojúdi tí ó kún fún ìpẹ̀gàn;+ nítorí pé àwọn ọmọ ń bọ̀ títí wọ́n fi dé ẹnu ilé ọlẹ̀,+ kò sì sí agbára láti bímọ.+  Bóyá Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò gbọ́+ gbogbo ọ̀rọ̀ Rábúṣákè, ẹni tí olúwa rẹ̀ ọba Ásíríà rán láti ṣáátá+ Ọlọ́run alààyè, òun yóò sì pè é wá jíhìn ní ti tòótọ́, fún àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti gbọ́.+ Kí o sì gbé àdúrà+ sókè nítorí ti àṣẹ́kù+ tí a lè rí.’”  Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ Hesekáyà Ọba wọlé tọ Aísáyà wá.+  Nígbà náà ni Aísáyà sọ fún wọn pé: “Èyí ni kí ẹ sọ fún olúwa yín, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí:+ “Má fòyà+ nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí o gbọ́, èyí tí àwọn ẹmẹ̀wà ọba Ásíríà sọ sí mi tèébútèébú.+  Kíyè sí i, èmi yóò fi ẹ̀mí+ kan sínú rẹ̀, òun yóò sì gbọ́ ìròyìn kan,+ yóò sì padà sí ilẹ̀ tirẹ̀; dájúdájú, èmi yóò mú kí ó tipa idà ṣubú ní ilẹ̀ tirẹ̀.”’”+  Lẹ́yìn ìyẹn, Rábúṣákè+ padà, ó sì rí i tí ọba Ásíríà ń bá Líbínà+ jà; nítorí ó gbọ́ pé ó ti ṣí kúrò ní Lákíṣì.+  Ó gbọ́ tí a sọ nípa Tíhákà ọba Etiópíà pé: “Kíyè sí i, ó ti jáde wá láti bá ọ jà.” Nítorí náà, ó tún rán àwọn ońṣẹ́+ sí Hesekáyà, pé: 10  “Èyí ni kí ẹ sọ fún Hesekáyà ọba Júdà, ‘Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run rẹ tí o gbẹ́kẹ̀ lé tàn ọ́ jẹ,+ wí pé: “A kì yóò fi Jerúsálẹ́mù+ lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.”+ 11  Wò ó! Ìwọ alára ti gbọ́ ohun tí àwọn ọba Ásíríà ṣe sí gbogbo ilẹ̀ nípa yíyà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun;+ a ó ha sì dá ìwọ alára nídè bí?+ 12  Àwọn ọlọ́run+ àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi run ha ti dá wọn nídè bí, àní Gósánì+ àti Háránì+ àti Réséfù àti àwọn ọmọ Édẹ́nì+ tí ó wà ní Tẹli-ásárì?+ 13  Òun dà—ọba Hámátì+ àti ọba Áápádì+ àti ọba àwọn ìlú ńlá Séfáfáímù, Hénà àti Ífáhì?’”+ 14  Nígbà náà ni Hesekáyà gba àwọn lẹ́tà náà lọ́wọ́ àwọn ońṣẹ́ náà, ó sì kà wọ́n,+ lẹ́yìn èyí tí Hesekáyà gòkè lọ sí ilé Jèhófà, ó sì tẹ́ ẹ síwájú Jèhófà.+ 15  Hesekáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà+ níwájú Jèhófà, ó sì wí pé: “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ ẹni tí ń jókòó sórí àwọn kérúbù,+ ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run tòótọ́ ti gbogbo ìjọba+ ilẹ̀ ayé.+ Ìwọ tìkára rẹ ni ó ṣe ọ̀run+ àti ilẹ̀ ayé.+ 16  Dẹ etí sílẹ̀, Jèhófà, kí o sì gbọ́.+ La ojú rẹ,+ Jèhófà, kí o sì wò, kí o sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Senakéríbù tí ó fi ránṣẹ́ láti ṣáátá+ Ọlọ́run alààyè. 17  Òtítọ́ ni, Jèhófà, àwọn ọba Ásíríà ti pa àwọn orílẹ̀-èdè àti ilẹ̀ wọn run di ahoro.+ 18  Wọ́n sì ti gbé àwọn ọlọ́run wọn lé iná lọ́wọ́, nítorí pé wọn kì í ṣe ọlọ́run,+ bí kò ṣe iṣẹ́ ọnà ọwọ́ ènìyàn,+ igi àti òkúta; tí ó fi jẹ́ pé wọ́n pa wọ́n run. 19  Wàyí o, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa,+ jọ̀wọ́, gbà wá là+ lọ́wọ́ rẹ̀, kí gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé lè mọ̀ pé ìwọ, Jèhófà, nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run.”+ 20  Aísáyà ọmọkùnrin Émọ́sì sì tẹ̀ síwájú láti ránṣẹ́ sí Hesekáyà, pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí,+ ‘Àdúrà+ tí ìwọ gbà sí mi nípa Senakéríbù ọba Ásíríà ni èmi ti gbọ́.+ 21  Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà ti sọ lòdì sí i: “Wúńdíá ọmọbìnrin Síónì ti tẹ́ńbẹ́lú rẹ,+ ó ti fi ọ́ ṣẹ̀sín.+ Ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù+ ti mi orí rẹ̀+ lẹ́yìn rẹ. 22  Ta ni ìwọ ṣáátá,+ tí o sì sọ̀rọ̀ sí tèébútèébú?+ Ta sì ni ìwọ gbé ohùn rẹ sókè lòdì sí,+ Tí ìwọ sì gbé ojú rẹ ga sókè sí?+ Sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì mà ni!+ 23  Ìwọ tipasẹ̀ àwọn ońṣẹ́ rẹ+ ṣáátá Jèhófà, ìwọ sì wí pé,+ ‘Ògìdìgbó kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun mi ni èmi fúnra mi+ Ni èmi yóò fi gun ibi gíga àwọn ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá dájúdájú,+ Àwọn apá ibi jíjìnnàréré jù lọ ní Lẹ́bánónì;+ Èmi yóò sì gé àwọn kédárì rẹ̀ gíga fíofío lulẹ̀,+ àwọn ààyò igi júnípà rẹ̀.+ Ṣe ni èmi yóò sì wọ ìpẹ̀kun ibùwọ̀ rẹ̀, igbó ọgbà igi eléso rẹ̀.+ 24  Dájúdájú, èmi fúnra mi yóò walẹ̀, èmi yóò sì mu àjèjì omi, Èmi yóò sì fi àtẹ́lẹsẹ̀ mi mú gbogbo ipa odò Náílì ti Íjíbítì gbẹ táútáú.’+ 25  Ṣé ìwọ kò tíì gbọ́ ni?+ Láti àwọn àkókò jíjìnnà, èyí ni èmi yóò ṣe dájúdájú.+ Láti àwọn ọjọ́ tí ó ti kọjá lọ ni mo tilẹ̀ ti ṣẹ̀dá rẹ̀.+ Wàyí o, èmi yóò mú un wá dájúdájú.+ Ìwọ yóò sì wà fún mímú kí àwọn ìlú ńlá olódi di ahoro gẹ́gẹ́ bí ìtòjọpelemọ àwókù.+ 26  Àwọn olùgbé inú wọn yóò sì jẹ́ ọlọ́wọ́ ahẹrẹpẹ;+ Ṣe ni àyà wọn yóò wulẹ̀ máa já, tí ojú yóò sì tì wọ́n.+ Wọn yóò dà bí ewéko pápá àti bí ọ̀jẹ̀lẹ́ koríko,+ Koríko orí òrùlé,+ nígbà tí ìjógbẹ bá wáyé níwájú ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn.+ 27  Jíjókòó jẹ́ẹ́ rẹ àti jíjáde rẹ+ àti wíwọlé rẹ sì ni mo mọ̀ dáadáa,+ Àti ríru tí o ń ru ara rẹ sókè sí mi,+ 28  Nítorí pé, ríru tí o ń ru ara rẹ sókè sí mi+ àti kíké tí o ń ké ramúramù ti dé etí mi.+ Dájúdájú, èmi yóò sì fi ìwọ̀ mi sí imú rẹ àti ìjánu mi sáàárín ètè rẹ,+ Ní tòótọ́, èmi yóò sì mú ọ padà lọ ní ojú ọ̀nà tí o gbà wá.”+ 29  “‘Èyí ni yóò sì jẹ́ àmì fún ọ:+ Ní ọdún yìí, jíjẹ láti inú èéhù àwọn kóró dídàálẹ̀ yóò wáyé,+ àti ní ọdún kejì, ọkà tí ó lalẹ̀ hù; ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ fún irúgbìn,+ kí ẹ sì kárúgbìn, kí ẹ gbin ọgbà àjàrà, kí ẹ sì jẹ èso rẹ̀.+ 30  Àwọn tí ó sì sá àsálà lára ilé Júdà, àwọn tí ó ṣẹ́ kù,+ yóò sì ta gbòǹgbò lọ sísàlẹ̀ dájúdájú, wọn yóò sì so èso sókè.+ 31  Nítorí pé àṣẹ́kù yóò jáde lọ láti Jerúsálẹ́mù,+ àwọn tí ó sì sá àsálà yóò jáde lọ láti Òkè Ńlá Síónì.+ Ìtara+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni yóò ṣe èyí. 32  “‘Ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé èyí ni ohun tí Jèhófà wí nípa ọba Ásíríà:+ “Kì yóò wá sínú ìlú ńlá yìí,+ bẹ́ẹ̀ ni kí yóò ta ọfà+ kan sí ibẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí yóò fi apata kò ó lójú, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò mọ ohun àfiṣe-odi ìsàgatì+ nà ró tì í. 33  Ọ̀nà tí ó gbà wá, ni yóò gbà padà, kì yóò sì wá sínú ìlú ńlá yìí, ni àsọjáde Jèhófà.+ 34  Dájúdájú, èmi yóò gbèjà+ ìlú ńlá yìí láti gbà á là nítorí tèmi+ àti nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi.”’”+ 35  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní òru yẹn pé áńgẹ́lì Jèhófà tẹ̀ síwájú láti jáde lọ, ó sì ṣá ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n balẹ̀ nínú ibùdó+ àwọn ará Ásíríà.+ Nígbà tí àwọn ènìyàn dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, họ́wù, òkú ni gbogbo wọn jẹ́ níbẹ̀.+ 36  Nítorí náà, Senakéríbù+ ọba Ásíríà ṣí kúrò, ó sì padà lọ,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé Nínéfè.+ 37  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí ó ti ń tẹrí ba ní ilé Nísírọ́kì+ ọlọ́run rẹ̀,+ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, Adiramélékì àti Ṣárésà fúnra wọn fi idà ṣá a balẹ̀,+ wọn sì sá lọ sí ilẹ̀ Árárátì.+ Esari-hádónì+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé