Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Àwọn Ọba 18:1-37

18  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọdún kẹta Hóṣéà+ ọmọkùnrin Éláhì ọba Ísírẹ́lì pé Hesekáyà+ ọmọkùnrin Áhásì+ ọba Júdà di ọba.  Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Ábì ọmọbìnrin Sekaráyà.+  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà,+ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ṣe.+  Òun ni ó mú àwọn ibi gíga+ kúrò tí ó sì fọ́ àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀+ sí wẹ́wẹ́ tí ó sì gé òpó ọlọ́wọ̀+ lulẹ̀ tí ó sì fọ́ ejò bàbà+ tí Mósè ṣe+ sí wẹ́wẹ́; nítorí pé títí di ọjọ́ wọnnì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bá a lọ ní rírú èéfín ẹbọ+ sí i, tí wọ́n sì ń pè é ní òrìṣà ejò bàbà.+  Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ó gbẹ́kẹ̀ lé;+ lẹ́yìn rẹ̀, kò tún wá sí ẹnì kankan tí ó dà bí rẹ̀ nínú gbogbo ọba Júdà,+ àní àwọn tí wọ́n wà ṣáájú rẹ̀ pàápàá.+  Ó sì ń bá a nìṣó ní fífà mọ́ Jèhófà.+ Kò yà kúrò nínú títọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ṣùgbọ́n ó ń bá a lọ láti pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè.+  Jèhófà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.+ Níbikíbi tí ó bá jáde lọ, òun a hùwà lọ́nà ìmòyemèrò;+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Ásíríà, kò sì sìn ín.+  Òun ni ó ṣá àwọn Filísínì balẹ̀+ títí lọ dé Gásà+ àti àwọn ìpínlẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú, láti ilé gogoro+ àwọn olùṣọ́ títí lọ dé ìlú ńlá olódi.  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọdún kẹrin Hesekáyà Ọba, èyíinì ni, ọdún keje Hóṣéà+ ọmọkùnrin Éláhì ọba Ísírẹ́lì, pé Ṣálímánésà+ ọba Ásíríà gòkè wá gbéjà ko Samáríà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sàga tì í.+ 10  Wọ́n sì gbà á+ ní òpin ọdún mẹ́ta; ní ọdún kẹfà Hesekáyà, èyíinì ni, ọdún kẹsàn-án Hóṣéà ọba Ísírẹ́lì, a gba Samáríà.+ 11  Lẹ́yìn ìyẹn, ọba Ásíríà+ kó Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn+ ní Ásíríà, ó sì fìdí wọn kalẹ̀ sí Hálà+ àti sí Hábórì+ níbi Odò Gósánì àti sí àwọn ìlú ńlá àwọn ará Mídíà,+ 12  ní tìtorí òtítọ́ náà pé wọn kò fetí sí+ ohùn Jèhófà Ọlọ́run wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ń tẹ májẹ̀mú rẹ̀ lójú ṣáá,+ àní gbogbo èyí tí Mósè+ ìránṣẹ́ Jèhófà pa láṣẹ.+ Wọn kò fetí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò pa á mọ́. 13  Àti ní ọdún kẹrìnlá Hesekáyà Ọba, Senakéríbù+ ọba Ásíríà+ gòkè wá gbéjà ko gbogbo ìlú ńlá olódi Júdà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbà wọ́n. 14  Nítorí náà, Hesekáyà ọba Júdà ránṣẹ́ sí ọba Ásíríà ní Lákíṣì, pé: “Mo ti ṣẹ̀. Yí padà kúrò nínú gbígbéjàkò mí. Ohun yòówù tí o bá gbé kà mí lórí ni èmi yóò rù.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ọba Ásíríà gbé ọ̀ọ́dúnrún tálẹ́ńtì fàdákà+ àti ọgbọ̀n tálẹ́ńtì wúrà lé Hesekáyà ọba Júdà. 15  Nítorí náà, Hesekáyà fi gbogbo fàdákà tí a rí ní ilé Jèhófà+ àti nínú àwọn ìṣúra ilé ọba+ lélẹ̀. 16  Ní ìgbà yẹn ni Hesekáyà gé àwọn ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì Jèhófà+ kúrò àti àwọn òpó ilẹ̀kùn tí Hesekáyà ọba Júdà fi nǹkan bò,+ lẹ́yìn náà, ó fi wọ́n fún ọba Ásíríà.+ 17  Ọba Ásíríà sì tẹ̀ síwájú láti rán Tátánì+ àti Rábúsárísì àti Rábúṣákè+ láti Lákíṣì+ sí Hesekáyà Ọba pẹ̀lú ẹgbẹ́ ológun tí ó bùáyà sí Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n bàa lè gòkè lọ, kí wọ́n sì wá sí Jerúsálẹ́mù. Nítorí náà, wọ́n gòkè lọ, wọ́n sì dé, wọ́n sì dúró jẹ́ẹ́ ní ọ̀nà omi+ ti odò adágún tí ń bẹ ní apá òkè,+ èyí tí ó wà ní òpópó pápá alágbàfọ̀.+ 18  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké sí ọba, ṣùgbọ́n Élíákímù+ ọmọkùnrin Hilikáyà, ẹni tí ń bójú tó agbo ilé, àti Ṣẹ́bínà+ akọ̀wé àti Jóà ọmọkùnrin Ásáfù akọ̀wé ìrántí ni ó jáde tọ̀ wọ́n wá. 19  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Rábúṣákè+ sọ fún wọn pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ sọ fún Hesekáyà pé, ‘Èyí ni ohun tí ọba ńlá,+ ọba Ásíríà wí: “Kí ni ohun ìgbọ́kànlé yìí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀ lé?+ 20  Ìwọ sọ (ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ètè ni) pé, ‘Ìmọ̀ràn+ àti agbára ńlá wà fún ogun.’ Wàyí o, ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀ lé, tí o fi ṣọ̀tẹ̀+ sí mi? 21  Wàyí o, wò ó! ìwọ gbẹ́kẹ̀ lé ìtìlẹ́yìn esùsú fífọ́ yìí,+ Íjíbítì,+ tí ó jẹ́ pé, bí ènìyàn bá fara tì í, ṣe ni yóò wọ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, tí yóò sì gún un. Bí Fáráò+ ọba Íjíbítì ṣe rí nìyẹn sí gbogbo àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé e. 22  Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ẹ sọ fún mi pé, ‘Jèhófà+ Ọlọ́run wa ni ẹni tí àwa gbẹ́kẹ̀ lé,’+ òun ha kọ́ ni ẹni tí Hesekáyà+ ti mú àwọn ibi gíga+ rẹ̀ àti àwọn pẹpẹ rẹ̀ kúrò, nígbà tí ó sọ fún Júdà àti Jerúsálẹ́mù pé, ‘Iwájú pẹpẹ yìí ni kí ẹ ti máa tẹrí ba ní Jerúsálẹ́mù’?”’+ 23  Ǹjẹ́ nísinsìnyí, ẹ jọ̀wọ́, ẹ mú ohun ìdúró+ wá fún olúwa mi ọba Ásíríà, kí ẹ sì jẹ́ kí n fún yín ní ẹgbàá ẹṣin láti rí i bóyá ẹ̀yin, níhà ọ̀dọ̀ yín, lè fi olùgun ẹṣin sórí wọn.+ 24  Báwo wá ni ẹ ṣe lè yí ojú gómìnà kan padà lára èyí tí ó kéré jù lọ nínú àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi,+ nígbà tí ẹ̀yin, ní tiyín, gbẹ́kẹ̀ yín lé Íjíbítì fún àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ àti àwọn ẹlẹ́ṣin?+ 25  Wàyí o, ó ha jẹ́ láìgba ọlá àṣẹ lọ́wọ́ Jèhófà ni mo gòkè wá gbéjà ko ibí yìí láti run ún? Jèhófà tìkára rẹ̀ wí fún mi pé,+ ‘Gòkè lọ gbéjà ko ilẹ̀ yìí, kí o sì run ún.’” 26  Látàrí èyí, Élíákímù+ ọmọkùnrin Hilikáyà àti Ṣẹ́bínà+ àti Jóà+ sọ fún Rábúṣákè pé:+ “Jọ̀wọ́, bá àwa ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Síríà,+ nítorí àwa gbọ́; má sì bá wa sọ̀rọ̀ ní èdè àwọn Júù+ ní etí àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ògiri.” 27  Ṣùgbọ́n Rábúṣákè sọ fún wọn pé: “Ṣé olúwa yín àti ẹ̀yin ni olúwa mi rán mi sí láti bá sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni? Kì í ha ṣe sí àwọn ọkùnrin tí ó jókòó sórí ògiri, pé kí wọ́n lè jẹ ìgbọ̀nsẹ̀ ara wọn+ kí wọ́n sì mu ìtọ̀ ara wọn pẹ̀lú yín?”+ 28  Rábúṣákè sì ń bá a lọ ní dídúró, ó sì fi ohùn rara ké jáde ní èdè àwọn Júù;+ ó sì ń bá a lọ láti sọ̀rọ̀, ó sì sọ pé: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba ńlá,+ ọba Ásíríà. 29  Èyí ni ohun tí ọba wí, ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekáyà tàn yín jẹ, nítorí kò lè dá yín nídè kúrò lọ́wọ́ mi.+ 30  Ẹ má sì jẹ́ kí Hesekáyà mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà,+ wí pé: “Láìkùnà, Jèhófà yóò dá wa nídè,+ a kì yóò sì fi ìlú ńlá yìí lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.”+ 31  Ẹ má fetí sí Hesekáyà; nítorí èyí ni ohun tí ọba Ásíríà wí: “Ẹ túúbá fún mi, kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá, kí olúkúlùkù sì máa jẹ láti inú àjàrà tirẹ̀ àti olúkúlùkù láti inú igi ọ̀pọ̀tọ́ tirẹ̀,+ kí olúkúlùkù sì máa mu omi inú ìkùdu tirẹ̀,+ 32  títí èmi yóò fi wá, tí èmi yóò sì kó yín lọ ní ti tòótọ́ sí ilẹ̀ tí ó dà bí ilẹ̀ tiyín,+ ilẹ̀ ọkà àti ti wáìnì tuntun, ilẹ̀ oúnjẹ+ àti ti àwọn ọgbà àjàrà,+ ilẹ̀ àwọn igi ólífì àti ti oyin;+ kí ẹ sì máa wà láàyè nìṣó, kí ẹ má bàa kú. Ẹ má sì fetí sí Hesekáyà, nítorí ó ń dẹ yín lọ, wí pé, ‘Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò dá wa nídè.’+ 33  Olúkúlùkù ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè ha ti dá ilẹ̀ tirẹ̀ nídè+ rárá kúrò lọ́wọ́ ọba Ásíríà bí?+ 34  Àwọn ọlọ́run Hámátì+ àti Áápádì dà?+ Àwọn ọlọ́run Séfáfáímù,+ Hénà+ àti Ífáhì dà?+ Wọ́n ha ti dá Samáríà nídè kúrò lọ́wọ́ mi?+ 35  Èwo nínú gbogbo ọlọ́run àwọn ilẹ̀ wọnnì tí ó tíì dá ilẹ̀ wọn nídè kúrò lọ́wọ́ mi,+ tí Jèhófà yóò fi dá Jerúsálẹ́mù nídè kúrò lọ́wọ́ mi?”’”+ 36  Àwọn ènìyàn náà sì dákẹ́,+ wọn kò sì dá a+ lóhùn ọ̀rọ̀ kan, nítorí àṣẹ ọba ni, pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ dá a lóhùn.”+ 37  Ṣùgbọ́n Élíákímù+ ọmọkùnrin Hilikáyà, ẹni tí ń bójú tó agbo ilé, àti Ṣẹ́bínà+ akọ̀wé àti Jóà+ ọmọkùnrin Ásáfù akọ̀wé ìrántí tọ Hesekáyà wá ti àwọn ti ẹ̀wù gbígbọ̀nya,+ wọ́n sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ Rábúṣákè fún un.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé