Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Àwọn Ọba 17:1-41

17  Ní ọdún kejìlá Áhásì ọba Júdà, Hóṣéà+ ọmọkùnrin Éláhì di ọba ní Samáríà+ lórí Ísírẹ́lì fún ọdún mẹ́sàn-án.  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, kìkì pé kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba Ísírẹ́lì tí wọ́n wà ṣáájú rẹ̀.+  Òun ni Ṣálímánésà+ ọba Ásíríà+ gòkè wá gbéjà kò, Hóṣéà sì wá di ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí san owó òde+ fún un.  Bí ó ti wù kí ó rí, ọba Ásíríà wá rí tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun+ nínú ọ̀ràn Hóṣéà, ní ti pé ó rán àwọn ońṣẹ́ sí Sóò ọba Íjíbítì,+ kò sì mú owó òde wá fún ọba Ásíríà bí ti àwọn ọdún àtẹ̀yìnwá. Nítorí náà, ọba Ásíríà sé e mọ́, ó sì mú kí ó wà ní dídè nínú àtìmọ́lé.+  Ọba Ásíríà sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè wá láti gbéjà ko gbogbo ilẹ̀ náà, ó sì gòkè wá sí Samáríà, ó sì sàga tì+ í fún ọdún mẹ́ta.  Ní ọdún kẹsàn-án Hóṣéà, ọba Ásíríà gba Samáríà,+ nígbà náà ni ó kó Ísírẹ́lì ní ìgbèkùn+ lọ sí Ásíríà, ó sì mú kí wọ́n máa gbé ní Hálà+ àti ní Hábórì níbi Odò Gósánì+ àti ní àwọn ìlú ńlá àwọn ará Mídíà.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ nítorí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ̀+ sí Jèhófà Ọlọ́run wọn, tí ó mú wọn gòkè wá láti ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò lábẹ́ ọwọ́ Fáráò ọba Íjíbítì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù àwọn ọlọ́run mìíràn;+  wọ́n sì ń bá a nìṣó ní rírìn nínú àwọn ìlànà àgbékalẹ̀+ ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àti nínú àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ àwọn ọba Ísírẹ́lì, èyí tí wọ́n ṣe;  àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí wá inú àwọn nǹkan tí kò tọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wọn,+ wọ́n sì ń bá a nìṣó ní kíkọ́ àwọn ibi gíga+ fún ara wọn nínú gbogbo ìlú ńlá wọn, láti ilé gogoro+ àwọn olùṣọ́ títí lọ dé ìlú ńlá olódi; 10  wọ́n sì ń bá a nìṣó ní gbígbé àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀+ àti àwọn òpó ọlọ́wọ̀+ nà ró fún ara wọn lórí gbogbo òkè kéékèèké tí ó ga+ àti lábẹ́ gbogbo igi tí ó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀;+ 11  àti níbẹ̀, lórí gbogbo ibi gíga, wọ́n ń bá a lọ ní rírú èéfín ẹbọ gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè+ tí Jèhófà ti kó lọ sí ìgbèkùn nítorí tiwọn, wọ́n sì ń ṣe ohun búburú ṣáá láti mú Jèhófà bínú;+ 12  Wọ́n sì ń bá a lọ ní sísin àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ,+ nípa èyí tí Jèhófà ti sọ fún wọn pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe nǹkan yìí”;+ 13  Jèhófà sì ń kìlọ̀+ fún Ísírẹ́lì+ àti Júdà+ ṣáá nípasẹ̀ gbogbo wòlíì rẹ̀+ àti nípasẹ̀ gbogbo olùríran,+ pé: “Ẹ yí padà kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú+ yín, kí ẹ sì pa àwọn àṣẹ mi mọ́,+ àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi,+ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin+ tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín,+ àti èyí tí mo fi ránṣẹ́ sí yín nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì”;+ 14  wọn kò sì fetí sílẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n ń bá a nìṣó ní mímú ọrùn+ wọn le gẹ́gẹ́ bí ọrùn àwọn baba ńlá wọn tí kò lo ìgbàgbọ́+ nínú Jèhófà Ọlọ́run wọn; 15  wọ́n sì ń bá a lọ láti kọ àwọn ìlànà rẹ̀ sílẹ̀ àti májẹ̀mú rẹ̀+ tí ó bá àwọn baba ńlá wọn dá àti àwọn ìránnilétí rẹ̀,+ èyí tí ó fi kìlọ̀ fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ àwọn òrìṣà asán+ lẹ́yìn, àwọn fúnra wọn sì di asán,+ àní ní àfarawé àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà yí wọn ká, nípa àwọn tí Jèhófà ti pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe bí tiwọn;+ 16  Wọ́n sì ń fi gbogbo àṣẹ+ Jèhófà Ọlọ́run wọn sílẹ̀ ṣáá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ère dídà+ fún ara wọn, ọmọ màlúù méjì,+ wọ́n sì ṣe òpó ọlọ́wọ̀,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹrí ba fún gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run,+ wọ́n sì ń sin Báálì;+ 17  wọ́n sì ń bá a lọ ní mímú àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn la iná+ kọjá, wọ́n sì ń woṣẹ́,+ wọ́n sì ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀,+ wọ́n sì ń bá a nìṣó ní títa+ ara wọn fún ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, láti mú un bínú;+ 18  Nítorí náà, ìbínú Jèhófà ru+ gidigidi sí Ísírẹ́lì, tí ó fi mú wọn kúrò níwájú rẹ̀.+ Kò jẹ́ kí ó ṣẹ́ ku èyíkéyìí bí kò ṣe ẹ̀yà Júdà nìkan ṣoṣo.+ 19  Júdà pàápàá kò pa àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run wọn mọ́,+ ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rìn nínú àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ ti Ísírẹ́lì,+ èyí tí wọ́n ṣe. 20  Nítorí náà, Jèhófà kọ gbogbo irú-ọmọ+ Ísírẹ́lì, ó sì ń ṣẹ́ wọn níṣẹ̀ẹ́ ṣáá, ó sì ń fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn akóni-ní-ìkógun, títí ó fi ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀.+ 21  Nítorí tí ó fa Ísírẹ́lì ya kúrò nínú ilé Dáfídì, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti fi Jèróbóámù ọmọkùnrin Nébátì jẹ ọba; Jèróbóámù+ sì bẹ̀rẹ̀ sí ya Ísírẹ́lì kúrò nínú títọ Jèhófà lẹ́yìn, ó sì mú kí wọ́n ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ ńláǹlà.+ 22  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù, èyí tí ó ṣẹ̀.+ Wọn kò yà kúrò nínú wọn, 23  títí Jèhófà fi mú Ísírẹ́lì kúrò níwájú rẹ̀,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípasẹ̀ gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì.+ Bí Ísírẹ́lì ṣe lọ kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀ sí ìgbèkùn ní Ásíríà títí di òní yìí+ nìyẹn. 24  Lẹ́yìn náà, ọba Ásíríà kó àwọn ènìyàn wá láti Bábílónì+ àti Kútà àti Áfà+ àti Hámátì+ àti Séfáfáímù,+ ó sì mú kí wọ́n máa gbé inú àwọn ìlú ńlá Samáríà+ dípò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gba Samáríà, wọ́n sì ń gbé inú àwọn ìlú ńlá rẹ̀. 25  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ gbígbé wọn níbẹ̀ pé wọn kò bẹ̀rù+ Jèhófà. Nítorí náà, Jèhófà rán àwọn kìnnìún+ sáàárín wọn, wọ́n sì wá di panipani láàárín wọn. 26  Nítorí náà, wọ́n fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ọba Ásíríà, pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ kó lọ sí ìgbèkùn, tí o sì wá mú kí wọ́n tẹ̀ dó sínú àwọn ìlú ńlá Samáríà, kò tíì mọ ẹ̀sìn Ọlọ́run ilẹ̀ náà, tí ó fi ń rán àwọn kìnnìún sáàárín wọn ṣáá;+ sì wò ó! wọ́n ń fi ikú pa wọ́n, níwọ̀n ìgbà tí kò ti sí ẹni tí ó mọ ẹ̀sìn Ọlọ́run ilẹ̀ náà.” 27  Látàrí ìyẹn, ọba Ásíríà pàṣẹ, pé: “Jẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn àlùfáà+ tí ẹ kó lọ sí ìgbèkùn láti ibẹ̀ kí ó lọ síbẹ̀, kí ó lè lọ máa gbé níbẹ̀, kí ó sì kọ́ wọn ní ẹ̀sìn Ọlọ́run ilẹ̀ náà.” 28  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ọ̀kan nínú àwọn àlùfáà tí wọ́n kó lọ sí ìgbèkùn láti Samáríà wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní Bẹ́tẹ́lì,+ ó sì wá di olùkọ́ wọn, ní ti bí ó ṣe yẹ kí wọ́n máa bẹ̀rù Jèhófà.+ 29  Bí ó ti wù kí ó rí, olúkúlùkù orílẹ̀-èdè wá di olùṣe ọlọ́run tirẹ̀,+ èyí tí wọ́n wá kó sínú ilé àwọn ibi gíga tí àwọn ará Samáríà ṣe, olúkúlùkù orílẹ̀-èdè, ní àwọn ìlú ńlá wọn níbi tí wọ́n ń gbé. 30  Àwọn ènìyàn Bábílónì, ní tiwọn, ṣe Sukotu-bénótì, àwọn ènìyàn Kútì,+ ní tiwọn, ṣe Nẹ́gálì, àwọn ènìyàn Hámátì, ní tiwọn, ṣe Áṣímà. 31  Ní ti àwọn ará Áfà,+ wọ́n ṣe Níbúhásì àti Tátákì; àwọn ará Séfáfáímù+ sì ń sun àwọn ọmọ wọn nínú iná+ sí Adiramélékì àti Anamélékì, àwọn ọlọ́run Séfáfáímù. 32  Wọ́n sì wá di olùbẹ̀rù Jèhófà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí mú lára àwọn ènìyàn ní gbogbo gbòò ṣe àlùfáà+ àwọn ibi gíga fún ara wọn, wọ́n sì wá di olùṣiṣẹ́ fún wọn nínú ilé àwọn ibi gíga. 33  Wọ́n sì di olùbẹ̀rù+ Jèhófà, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́run tiwọn ni wọ́n ń jọ́sìn,+ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn àwọn orílẹ̀-èdè láti inú èyí tí wọ́n ti kó wọn lọ sí ìgbèkùn.+ 34  Títí di òní yìí, wọ́n ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn wọn àtijọ́.+ Kò sí ẹnì kankan nínú wọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà,+ kò sì sí ẹnì kankan nínú wọn tí ń ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́+ rẹ̀ àti òfin+ àti àṣẹ+ tí Jèhófà pa fún àwọn ọmọ Jékọ́bù,+ orúkọ ẹni tí ó sọ di Ísírẹ́lì;+ 35  nígbà tí Jèhófà bá wọn dá májẹ̀mú,+ tí ó sì pàṣẹ fún wọn, pé: “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù àwọn ọlọ́run mìíràn,+ ẹ kò sì gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún wọn tàbí kí ẹ sìn wọ́n tàbí kí ẹ rúbọ sí wọn.+ 36  Ṣùgbọ́n Jèhófà, ẹni tí ó mú yín gòkè wá láti ilẹ̀ Íjíbítì pẹ̀lú agbára ńlá àti apá nínà jáde,+ ni Ẹni tí ẹ ó bẹ̀rù,+ òun sì ni kí ẹ máa tẹrí ba fún,+ òun sì ni kí ẹ máa rúbọ sí.+ 37  Àwọn ìlànà+ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́+ àti òfin àti àṣẹ tí ó kọ fún yín,+ ni kí ẹ kíyè sára láti máa pa mọ́ nígbà gbogbo;+ ẹ kò sì gbọ́dọ̀ bẹ̀rù àwọn ọlọ́run mìíràn. 38  Májẹ̀mú tí mo sì bá yín dá, ẹ kò gbọ́dọ̀ gbàgbé;+ ẹ kò sì gbọ́dọ̀ bẹ̀rù àwọn ọlọ́run mìíràn.+ 39  Ṣùgbọ́n Jèhófà+ Ọlọ́run yín ni kí ẹ bẹ̀rù, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé òun ni ẹni tí yóò dá yín nídè kúrò lọ́wọ́ gbogbo ọ̀tá yín.”+ 40  Wọn kò sì ṣègbọràn, ṣùgbọ́n ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀sìn wọn àtẹ̀yìnwá ni wọ́n ń ṣe.+ 41  Àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí sì wá di olùbẹ̀rù Jèhófà,+ ṣùgbọ́n àwọn ère fífín tiwọn ni wọ́n ń sìn. Ní ti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ọmọ-ọmọ wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá wọn ti ṣe ni àwọn fúnra wọn ń ṣe títí di òní yìí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé