Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Àwọn Ọba 15:1-38

15  Ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Jèróbóámù ọba Ísírẹ́lì, Asaráyà+ ọmọkùnrin Amasááyà+ ọba Júdà di ọba.  Ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún ni nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún méjì-lé-láàádọ́ta sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jekoláyà ti Jerúsálẹ́mù.  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó dúró ṣánṣán ní ojú Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Amasááyà baba rẹ̀ ṣe.+  Kìkì pé àwọn ibi gíga kò dàwátì.+ Àwọn ènìyàn ṣì ń rúbọ, wọ́n sì ń rú èéfín ẹbọ lórí àwọn ibi gíga.+  Níkẹyìn, Jèhófà fi àrùn kọlu ọba,+ ó sì ń bá a lọ ní jíjẹ́ adẹ́tẹ̀+ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, ó sì ń gbé ní ilé rẹ̀ ní ẹni tí a yọ kúrò lẹ́nu iṣẹ́,+ nígbà tí Jótámù+ ọmọkùnrin ọba ń bójú tó ilé, tí ó ń ṣe ìdájọ́+ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Asaráyà àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Júdà?  Nígbà tí ó ṣe, Asaráyà dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Ńlá Dáfídì; Jótámù ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.+  Ní ọdún kejìdínlógójì Asaráyà+ ọba Júdà, Sekaráyà+ ọmọkùnrin Jèróbóámù di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà fún oṣù mẹ́fà.  Ó sì ń ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+ Kò yà kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù+ ọmọkùnrin Nébátì, èyí tí ó fi mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.+ 10  Nígbà náà ni Ṣálúmù ọmọkùnrin Jábẹ́ṣì di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun+ sí i, ó sì ṣá a balẹ̀+ ní Íbíléámù,+ ó sì fi ikú pa á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀. 11  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Sekaráyà, ibẹ̀ ni a kọ wọ́n sí, nínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì. 12  Ìyẹn ni ọ̀rọ̀ Jèhófà+ tí ó sọ fún Jéhù, pé:+ “Dé ìran kẹrin ni àwọn ọmọ+ yóò máa jókòó fún ọ lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.” Bí ó sì ṣe ṣẹlẹ̀ níyẹn.+ 13  Ní ti Ṣálúmù ọmọkùnrin Jábẹ́ṣì, ó di ọba ní ọdún kọkàndínlógójì Ùsáyà+ ọba Júdà, ó sì ń bá a lọ láti jọba fún oṣù òṣùpá kan gbáko ní Samáríà.+ 14  Nígbà náà ni Ménáhémù+ ọmọkùnrin Gádì gòkè wá láti Tírísà,+ ó sì wá sí Samáríà, ó sì ṣá Ṣálúmù+ ọmọkùnrin Jábẹ́ṣì balẹ̀ ní Samáríà, ó sì fi ikú pa á; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀. 15  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Ṣálúmù àti tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun rẹ̀+ èyí tí ó dì, ibẹ̀ ni a kọ wọ́n sí nínú ìwé àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì. 16  Ìgbà náà ni Ménáhémù ṣá Tífísà balẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀ àti ìpínlẹ̀ rẹ̀ láti Tírísà lọ, nítorí pé kò ṣí sílẹ̀, ó sì ṣá a balẹ̀. Gbogbo aboyún rẹ̀ ni ó là ní inú.+ 17  Ní ọdún kọkàndínlógójì+ Asaráyà ọba Júdà, Ménáhémù ọmọkùnrin Gádì di ọba lórí Ísírẹ́lì fún ọdún mẹ́wàá ní Samáríà. 18  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.+ Kò yà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù+ ọmọkùnrin Nébátì, èyí tí ó fi mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀,+ ní gbogbo ọjọ́ rẹ̀. 19  Púlì+ ọba Ásíríà+ wá sí ilẹ̀ náà. Nítorí náà, Ménáhémù fún+ Púlì ní ẹgbẹ̀rún tálẹ́ńtì fàdákà,+ kí ọwọ́ rẹ̀ lè wà pẹ̀lú rẹ̀ láti fún ìjọba náà lókun ní ọwọ́ tirẹ̀.+ 20  Nítorí náà, Ménáhémù kó fàdákà náà jáde wá, sí àdánù Ísírẹ́lì àti sí àdánù gbogbo akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin,+ láti kó àádọ́ta ṣékélì fàdákà lórí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan fún ọba Ásíríà. Látàrí ìyẹn, ọba Ásíríà yí padà, kò sí dúró níbẹ̀ ní ilẹ̀ náà. 21  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Ménáhémù+ àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì? 22  Níkẹyìn, Ménáhémù dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, Pekaháyà+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀. 23  Ní ọdún àádọ́ta Asaráyà ọba Júdà, Pekaháyà ọmọkùnrin Ménáhémù di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà fún ọdún méjì.+ 24  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.+ Kò yà kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù+ ọmọkùnrin Nébátì, èyí tí ó fi mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.+ 25  Nígbà náà ni Pékà+ ọmọkùnrin Remaláyà, olùrànlọ́wọ́ òun ọ̀gágun,+ di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun+ sí i, ó sì ṣá a balẹ̀ ní Samáríà nínú ilé gogoro ibùgbé tí ó wà ní ilé ọba,+ pẹ̀lú Ágóbù àti Áríè, àádọ́ta ọkùnrin láti inú àwọn ọmọ Gílíádì sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Bí ó ṣe fi ikú pa á nìyẹn tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀. 26  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Pekaháyà àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ibẹ̀ ni a kọ wọ́n sí nínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì. 27  Ní ọdún kejì-lé-láàádọ́ta Asaráyà ọba Júdà, Pékà+ ọmọkùnrin Remaláyà+ di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà fún ogún ọdún. 28  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.+ Kò yà kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù+ ọmọkùnrin Nébátì, èyí tí ó fi mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.+ 29  Ní àwọn ọjọ́ Pékà ọba Ísírẹ́lì, Tigilati-pílésà+ ọba Ásíríà+ wọlé wá, ó sì tẹ̀ síwájú láti gba Íjónì+ àti Ebẹli-bẹti-máákà+ àti Jánóà àti Kédéṣì+ àti Hásórì+ àti Gílíádì+ àti Gálílì,+ gbogbo ilẹ̀ Náfútálì,+ ó sì kó wọn lọ sí ìgbèkùn ní Ásíríà.+ 30  Níkẹyìn, Hóṣéà+ ọmọkùnrin Éláhì di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun+ sí Pékà ọmọkùnrin Remaláyà, ó sì kọlù ú,+ ó sì fi ikú pa á; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀ ní ọdún ogún Jótámù+ ọmọkùnrin Ùsáyà. 31  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Pékà àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ibẹ̀ ni a kọ wọ́n sí nínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì. 32  Ní ọdún kejì Pékà ọmọkùnrin Remaláyà ọba Ísírẹ́lì, Jótámù+ ọmọkùnrin Ùsáyà+ ọba Júdà di ọba. 33  Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jẹ́rúṣà ọmọbìnrin Sádókù.+ 34  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà.+ Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Ùsáyà baba rẹ̀ ṣe, ni ó ṣe.+ 35  Kìkì pé àwọn ibi gíga kò dàwátì. Àwọn ènìyàn ṣì ń rúbọ, wọ́n sì ń rú èéfín ẹbọ ní àwọn ibi gíga.+ Òun ni ó kọ́ ẹnubodè apá òkè ti ilé Jèhófà.+ 36  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Jótámù, ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Júdà?+ 37  Ní ọjọ́ wọnnì, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí rán+ Résínì+ ọba Síríà àti Pékà+ ọmọkùnrin Remaláyà láti dojú ìjà kọ Júdà. 38  Níkẹyìn, Jótámù dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Ńlá Dáfídì baba ńlá rẹ̀;+ Áhásì+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé