Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Àwọn Ọba 13:1-25

13  Ní ọdún kẹtàlélógún Jèhóáṣì+ ọmọkùnrin Ahasáyà+ ọba Júdà, Jèhóáhásì+ ọmọkùnrin Jéhù+ di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà fún ọdún mẹ́tàdínlógún.  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà,+ ó sì ń tọpasẹ̀ Jèróbóámù+ ọmọkùnrin Nébátì, èyí tí ó fi mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.+ Kò yà kúrò nínú rẹ̀.  Ìbínú Jèhófà+ sì wá gbóná sí Ísírẹ́lì, tí ó fi fi wọ́n lé Hásáélì+ ọba Síríà lọ́wọ́ àti lé Bẹni-hádádì+ ọmọkùnrin Hásáélì lọ́wọ́ ní gbogbo ọjọ́ wọn.  Nígbà tí ó ṣe, Jèhóáhásì tu Jèhófà lójú,+ tí Jèhófà fi fetí sí i;+ nítorí tí ó ti rí ìnilára tí ó dé bá Ísírẹ́lì,+ nítorí pé ọba Síríà ni wọ́n lára.+  Nítorí náà, Jèhófà fún Ísírẹ́lì ní olùgbàlà kan,+ tí wọ́n fi kúrò lábẹ́ ọwọ́ Síríà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ ní gbígbé ní ilé wọn bí ti tẹ́lẹ̀ rí.+  (Kìkì pé wọn kò yà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jèróbóámù, èyí tí ó fi mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.+ Inú rẹ̀ ni ó ti rìn;+ àní òpó ọlọ́wọ̀+ pàápàá wà ní ìdúró ní Samáríà.)  Nítorí pé kò ṣẹ́ àwọn ènìyàn kankan kù fún Jèhóáhásì bí kò ṣe àádọ́ta ẹlẹ́ṣin àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin mẹ́wàá àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ènìyàn tí ń fẹsẹ̀ rìn,+ nítorí tí ọba Síríà ti pa wọ́n run,+ kí ó lè ṣe wọ́n bí ekuru ibi ìpakà.+  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Jèhóáhásì àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti agbára ńlá rẹ̀, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì?  Níkẹyìn, Jèhóáhásì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Samáríà;+ Jèhóáṣì+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀. 10  Ní ọdún kẹtàdínlógójì Jèhóáṣì ọba Júdà, Jèhóáṣì+ ọmọkùnrin Jèhóáhásì di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà fún ọdún mẹ́rìndínlógún. 11  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.+ Kò yà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù ọmọkùnrin Nébátì, èyí tí ó fi mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.+ Inú wọn ni ó ti rìn. 12  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Jèhóáṣì àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti agbára ńlá rẹ̀ àti bí ó ṣe bá Amasááyà ọba Júdà jà,+ a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì? 13  Níkẹyìn, Jèhóáṣì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, Jèróbóámù+ alára sì jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀. Ẹ̀wẹ̀, a sin Jèhóáṣì sí Samáríà pẹ̀lú àwọn ọba Ísírẹ́lì.+ 14  Ní ti Èlíṣà,+ ó ń ṣàìsàn èyí tí yóò fi kú.+ Nítorí náà, Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì sọ̀ kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún sí i lójú, ó sì wí pé: “Baba mi,+ baba mi, kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun Ísírẹ́lì àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀!”+ 15  Èlíṣà sì sọ fún un pé: “Mú ọrun àti àwọn ọfà.” Nítorí náà, ó mú ọrun àti àwọn ọfà sọ́dọ̀ ara rẹ̀. 16  Ó sì ń bá a lọ láti sọ fún ọba Ísírẹ́lì pé: “Gbé ọwọ́ rẹ lé ọrun.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e, lẹ́yìn èyí tí Èlíṣà gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ọwọ́ ọba.+ 17  Nígbà náà ni ó sọ pé: “Ṣí fèrèsé tí ó wà ní ìlà-oòrùn.” Nítorí náà, ó ṣí i. Níkẹyìn, Èlíṣà sọ pé: “Ta á!” Nítorí náà, ó ta á. Wàyí o, ó wí pé: “Ọfà ìgbàlà Jèhófà, àní ọfà ìgbàlà+ ní ìdojú-ìjà-kọ Síríà! Dájúdájú, ìwọ yóò ṣá Síríà balẹ̀ ní Áfékì+ títí yóò fi pa rẹ́.” 18  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Kó àwọn ọfà náà.” Látàrí ìyẹn, ó kó wọn. Nígbà náà ni ó sọ fún ọba Ísírẹ́lì pé: “Ta wọ́n sí ilẹ̀.” Nítorí náà, ó ta ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta, ó sì dáwọ́ dúró.+ 19  Ìkannú ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́+ sì ru sí i; nítorí náà, ó wí pé: “Ẹ̀ẹ̀márùn-ún tàbí mẹ́fà ni ìwọ ì bá ta á! Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, dájúdájú, ìwọ ì bá máa ṣá Síríà balẹ̀ títí yóò fi pa rẹ́, ṣùgbọ́n, nísinsìnyí, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ni ìwọ yóò ṣá Síríà balẹ̀.”+ 20  Lẹ́yìn ìyẹn, Èlíṣà kú, wọ́n sì sin ín.+ Àwọn ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí+ tí wọ́n jẹ́ ọmọ Móábù+ sì ń bẹ tí ń wá déédéé sí ilẹ̀ náà nígbà ìwọlédé ọdún. 21  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí wọ́n ti ń sìnkú ọkùnrin kan, họ́wù, kíyè sí i, wọ́n rí ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí. Kíákíá, wọ́n sọ ọkùnrin náà sínú ibi ìsìnkú Èlíṣà, wọ́n sì lọ. Nígbà tí ọkùnrin náà fara kan egungun Èlíṣà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó wá sí ìyè,+ ó sì díde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀.+ 22  Ní ti Hásáélì+ ọba Síríà, ó ń ni Ísírẹ́lì lára+ ní gbogbo ọjọ́ Jèhóáhásì. 23  Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhófà fi ojú rere hàn+ sí wọn, ó sì ṣàánú+ wọn, ó sì yíjú sí wọn nítorí májẹ̀mú+ rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù,+ Ísákì+ àti Jékọ́bù;+ kò sì fẹ́ run wọ́n,+ kò sì ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀ títí di ìsinsìnyí. 24  Níkẹyìn, Hásáélì ọba Síríà kú, Bẹni-hádádì ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀. 25  Jèhóáṣì ọmọkùnrin Jèhóáhásì sì tún gba àwọn ìlú ńlá tí Bẹni-hádádì ọmọkùnrin Hásáélì fi ogun gbà ní ọwọ́ Jèhóáhásì baba rẹ̀ padà lọ́wọ́ rẹ̀. Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ni Jèhóáṣì ṣá a balẹ̀, ó sì gba àwọn ìlú ńlá Ísírẹ́lì padà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé