Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Àwọn Ọba 12:1-21

12  Ní ọdún keje Jéhù,+ Jèhóáṣì+ di ọba, ogójì ọdún sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Sibáyà láti Bíá-ṣébà.  Jèhóáṣì sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ tirẹ̀ tí Jèhóádà àlùfáà fi fún un ní ìtọ́ni.+  Kìkì àwọn ibi gíga ni kò dàwátì.+ Àwọn ènìyàn ṣì ń rúbọ, wọ́n sì ń rú èéfín ẹbọ lórí àwọn ibi gíga.  Jèhóáṣì sì tẹ̀ síwájú láti sọ fún àwọn àlùfáà pé:+ “Gbogbo owó àwọn ọrẹ ẹbọ mímọ́+ tí a bá mú wá sí ilé Jèhófà,+ owó tí a bá dá lé olúkúlùkù,+ owó àwọn ọkàn gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé+ ti olúkúlùkù, gbogbo owó tí ó bá wá sí ọkàn-àyà olúkúlùkù láti mú wá sí ilé Jèhófà,+  kí àwọn àlùfáà gbà á fún ara wọn, olúkúlùkù lọ́wọ́ ojúlùmọ̀ rẹ̀;+ kí àwọn, ní tiwọn, sì tún àwọn ibi tí ó sán lára ilé náà ṣe, ibikíbi tí a bá ti rí ibi sísán èyíkéyìí.”+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ó máa fi di ọdún kẹtàlélógún Jèhóáṣì Ọba, àwọn àlùfáà kò tíì tún àwọn ibi tí ó sán lára ilé náà ṣe síbẹ̀.+  Nítorí náà, Jèhóáṣì Ọba pe Jèhóádà+ àlùfáà àti àwọn àlùfáà, ó sì wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ kò fi tún àwọn ibi tí ó sán lára ilé náà ṣe? Ǹjẹ́ nísinsìnyí, ẹ má gba owó kankan mọ́ lọ́wọ́ àwọn ojúlùmọ̀ yín, ṣùgbọ́n àwọn ibi tí ó sán lára ilé náà ni kí ẹ fi í lélẹ̀ fún.”+  Látàrí ìyẹn, àwọn àlùfáà gbà láti má gba owó lọ́wọ́ àwọn ènìyàn mọ́ àti láti má ṣe tún àwọn ibi tí ó sán lára ilé náà ṣe.  Jèhóádà àlùfáà gbé àpótí+ kan wàyí, ó sì dá ihò lu sí ọmọrí rẹ̀, ó sì gbé e sẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ, ní ìhà ọ̀tún bí ènìyàn bá ń wọ inú ilé Jèhófà bọ̀, ibẹ̀ sì ni àwọn àlùfáà, àwọn olùṣọ́nà,+ ń kó gbogbo owó+ tí a mú wá sí ilé Jèhófà sí. 10  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí wọ́n bá ti rí i pé owó púpọ̀ ń bẹ nínú àpótí náà, akọ̀wé+ ọba àti àlùfáà àgbà a gòkè wá, wọn a sì dì í, wọn a sì ka owó náà tí a rí ní ilé Jèhófà.+ 11  Wọ́n sì kó owó tí a ti kà sọ́tọ̀ náà lé ọwọ́ àwọn olùṣe iṣẹ́ tí a yàn sí ilé Jèhófà. Àwọn, ẹ̀wẹ̀, san án fún àwọn oníṣẹ́ igi+ àti fún àwọn akọ́lé tí ń ṣiṣẹ́ ní ilé Jèhófà, 12  àti fún àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn agbẹ́kùúta+ àti láti fi ra ẹ̀là gẹdú àti òkúta gbígbẹ́ láti fi tún àwọn ibi tí ó sán lára ilé Jèhófà ṣe àti fún gbogbo ohun tí a lò sí ara ilé náà láti fi tún un ṣe. 13  Kìkì pé ní ti ilé Jèhófà, a kò ṣe àwọn bàsíà fàdákà, àwọn àlùmọ́gàjí fìtílà,+ àwọn àwokòtò,+ àwọn kàkàkí,+ irú ohun èlò wúrà èyíkéyìí àti ohun èlò fàdákà láti inú owó tí a mú wá sí ilé Jèhófà;+ 14  nítorí pé àwọn olùṣe iṣẹ́ náà ni wọ́n ń kó o fún, èyí sì ni wọ́n fi ń tún ilé Jèhófà ṣe.+ 15  Wọn kì í sì í béèrè fún ìṣirò+ lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin tí wọ́n ń kó owó náà lé lọ́wọ́ láti kó o fún àwọn olùṣe iṣẹ́ náà,+ nítorí pé ìṣòtítọ́+ ni wọ́n fi ń ṣiṣẹ́. 16  Ní ti owó àwọn ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi+ àti owó àwọn ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, a kì í mú un wá sí ilé Jèhófà. Nítorí náà, ó wá jẹ́ ti àwọn àlùfáà.+ 17  Ìgbà náà ni Hásáélì+ ọba Síríà bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ láti bá Gátì+ jà àti láti gbà á, lẹ́yìn èyí tí Hásáélì gbé ojú+ lé àtigòkè lọ láti gbéjà ko Jerúsálẹ́mù.+ 18  Látàrí ìyẹn, Jèhóáṣì ọba Júdà kó gbogbo ọrẹ ẹbọ mímọ́+ tí Jèhóṣáfátì àti Jèhórámù àti Ahasáyà àwọn baba ńlá rẹ̀, àwọn ọba Júdà, ti sọ di mímọ́ àti àwọn ọrẹ ẹbọ mímọ́ tirẹ̀ àti gbogbo wúrà tí a rí nínú àwọn ìṣúra ilé Jèhófà àti ilé ọba, ó sì kó wọn ránṣẹ́+ sí Hásáélì ọba Síríà. Nítorí náà, ó fà sẹ́yìn kúrò nínú gbígbéjàko Jerúsálẹ́mù. 19  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Jèhóáṣì àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Júdà? 20  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀+ dìde, wọ́n sì mulẹ̀ nínú tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun,+ wọ́n sì ṣá Jèhóáṣì balẹ̀ ní ilé+ Òkìtì,+ ní ọ̀nà tí ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Síílà. 21  Jósákárì ọmọkùnrin Ṣíméátì àti Jèhósábádì+ ọmọkùnrin Ṣómérì, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ni àwọn tí ó ṣá a balẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Ńlá Dáfídì; Amasááyà+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé