Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Àwọn Ọba 11:1-21

11  Wàyí o, ní ti Ataláyà+ ìyá Ahasáyà,+ ó rí i pé ọmọkùnrin òun ti kú. Nítorí náà, ó dìde, ó sì pa gbogbo ọmọ ìjọba run.+  Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhóṣébà+ ọmọbìnrin Jèhórámù Ọba, arábìnrin Ahasáyà, gbé Jèhóáṣì+ ọmọkùnrin Ahasáyà, ó sì jí i gbé kúrò láàárín àwọn ọmọkùnrin ọba tí a fẹ́ fi ikú pa, àní òun àti obìnrin olùṣètọ́jú rẹ̀, wá sínú yàrá inú lọ́hùn-ún níbi tí a ń kó àwọn àga ìrọ̀gbọ̀kú sí, wọ́n sì gbé e pa mọ́+ kúrò ní ojú Ataláyà, a kò sì fi ikú pa á.  Ó sì ń bá a lọ ní wíwà pẹ̀lú rẹ̀ ní ilé Jèhófà ní ìpamọ́ fún ọdún mẹ́fà, nígbà tí Ataláyà ń jọba lórí ilẹ̀ náà.+  Ní ọdún keje, Jèhóádà+ sì ránṣẹ́, ó sì wá mú àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún lára ẹ̀ṣọ́ Káríà+ àti lára àwọn sárésáré,+ ó sì mú wọn wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní ilé Jèhófà, ó sì bá wọn dá májẹ̀mú,+ ó sì mú kí wọ́n búra+ ní ilé Jèhófà, lẹ́yìn èyí tí ó fi ọmọkùnrin ọba hàn wọ́n.  Ó sì tẹ̀ síwájú láti pàṣẹ fún wọn, pé: “Èyí ni ohun tí ẹ ó ṣe: Ìdá mẹ́ta lára yín yóò wọlé wá ní sábáàtì, ẹ ó sì máa ṣọ́ ilé ọba+ lójú méjèèjì;  ìdá mẹ́ta yóò sì wà ní Ẹnubodè Ìpìlẹ̀,+ ìdá mẹ́ta yóò sì wà ní ẹnubodè tí ó wà lẹ́yìn àwọn sárésáré; kí ẹ sì máa ṣọ́ ilé náà lójú méjèèjì+ ní ìpín kan tẹ̀ lé òmíràn.  Ìpín méjì ni ó sì ń bẹ lára yín tí gbogbo wọn ń jáde lọ ní sábáàtì, kí wọ́n sì máa ṣọ́ ilé Jèhófà lójú méjèèjì nítorí ọba.  Kí ẹ sì pagbo yí ọba ká ní ìhà gbogbo, olúkúlùkù tòun ti àwọn ohun ìjà tirẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wọlé wá sáàárín àwọn ìlà ni a ó fi ikú pa. Kí ẹ sì máa wà pẹ̀lú ọba nígbà tí ó bá ń jáde àti nígbà tí ó bá ń wọlé.”  Àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Jèhóádà àlùfáà pa láṣẹ. Nítorí náà, olúkúlùkù mú àwọn ọkùnrin tirẹ̀ tí ń wọlé wá ní sábáàtì,+ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ń jáde lọ ní sábáàtì, nígbà náà ni wọ́n sì wọlé tọ Jèhóádà àlùfáà wá. 10  Àlùfáà wá fún àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ní àwọn ọ̀kọ̀ àti apata bìrìkìtì tí ó jẹ́ ti Dáfídì Ọba, èyí tí ó wà nínú ilé Jèhófà.+ 11  Àwọn sárésáré+ sì wà ní ìdúró, olúkúlùkù ti òun ti ohun ìjà tirẹ̀ ní ọwọ́, láti ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ilé náà títí lọ dé ẹ̀gbẹ́ òsì ilé náà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ+ àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé náà, ní gbogbo àyíká nítòsí ọba. 12  Nígbà náà ni ó mú ọmọkùnrin+ ọba jáde, ó sì fi adé dáyádémà+ àti Gbólóhùn Ẹ̀rí+ sí i lórí; nítorí náà, wọ́n sì fi í jẹ ọba,+ wọ́n sì fòróró yàn án.+ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pàtẹ́wọ́,+ wọ́n sì sọ pé: “Kí ọba kí ó pẹ́!”+ 13  Nígbà tí Ataláyà gbọ́ ìró àwọn ènìyàn tí ń sáré, ní kíá ó wá bá àwọn ènìyàn náà ní ilé Jèhófà.+ 14  Nígbà náà ni ó rí i, ọba rèé tí ó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọwọ̀n+ gẹ́gẹ́ bí àṣà, tí àwọn olórí àti àwọn kàkàkí+ sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọba, tí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì ń yọ̀,+ tí wọ́n sì ń fun kàkàkí. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Ataláyà+ gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pé: “Tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun! Tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun!”+ 15  Ṣùgbọ́n Jèhóádà àlùfáà pàṣẹ fún àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, àwọn tí a yàn sípò nínú ẹgbẹ́ ológun,+ ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ mú un jáde kúrò nínú àwọn ìlà, ní ti ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, kí fífi idà ṣekú pa á kí ó wáyé!”+ Nítorí àlùfáà ti sọ pé: “Ẹ má ṣe fi ikú pa á ní ilé Jèhófà.” 16  Nítorí náà, wọ́n gbé ọwọ́ wọn lé e, ó sì gba ti ọ̀nà ibi àbáwọlé ẹṣin+ ní ilé ọba wá,+ wọ́n sì fi ikú pa á níbẹ̀.+ 17  Nígbà náà ni Jèhóádà dá májẹ̀mú+ láàárín Jèhófà+ àti ọba+ àti àwọn ènìyàn náà, pé kí wọ́n fi ara wọn hàn ní ènìyàn Jèhófà; àti láàárín ọba àti àwọn ènìyàn náà pẹ̀lú.+ 18  Lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà wá sí ilé Báálì, wọ́n sì bi àwọn pẹpẹ rẹ̀ wó;+ àwọn ère rẹ̀ ni wọ́n sì fọ́ túútúú,+ Mátánì+ àlùfáà Báálì ni wọ́n sì pa níwájú àwọn pẹpẹ náà.+ Àlùfáà sì tẹ̀ síwájú láti fi alábòójútó sórí ilé Jèhófà.+ 19  Síwájú sí i, ó kó àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àti ẹ̀ṣọ́ Káríà+ àti àwọn sárésáré+ àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, pé kí wọ́n lè mú ọba sọ̀ kalẹ̀ wá láti ilé Jèhófà; ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n sì gba ti ọ̀nà ẹnubodè+ sárésáré wá sí ilé ọba; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jókòó sórí ìtẹ́+ àwọn ọba. 20  Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì ń bá a lọ ní yíyọ̀;+ ìlú ńlá náà, ní tirẹ̀, kò sì ní ìyọlẹ́nu, Ataláyà alára ni wọ́n sì ti fi idà pa ní ilé ọba.+ 21  Ẹni ọdún méje ni Jèhóáṣì+ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé