Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Àwọn Ọba 1:1-18

1  Móábù+ sì bẹ̀rẹ̀ sí dìtẹ̀+ sí Ísírẹ́lì lẹ́yìn ikú Áhábù.+  Nígbà náà, Ahasáyà já bọ́+ láti ibi asẹ́ ojú fèrèsé ìyẹ̀wù+ òrùlé rẹ̀ tí ó wà ní Samáríà, ó sì ṣàìsàn. Nítorí náà, ó rán àwọn ońṣẹ́, ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ lọ, kí ẹ wádìí+ lọ́dọ̀ Baali-sébúbù+ ọlọ́run Ékírónì+ bóyá èmi yóò sàn nínú àìsàn+ yìí.”  Ní ti áńgẹ́lì+ Jèhófà, ó bá Èlíjà ará Tíṣíbè+ sọ̀rọ̀ pé: “Dìde, gòkè lọ pàdé àwọn ońṣẹ́ ọba Samáríà, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ṣé nítorí pé kò sí Ọlọ́run+ rárá ní Ísírẹ́lì ni ẹ fi ń lọ wádìí lọ́dọ̀ Baali-sébúbù ọlọ́run Ékírónì?  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ní ti àga ìrọ̀gbọ̀kú náà, orí èyí tí ìwọ wà, ìwọ kì yóò sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí rẹ̀, nítorí ó dájú pé ìwọ yóò kú.”’”+ Pẹ̀lú ìyẹn, Èlíjà lọ.  Nígbà tí àwọn ońṣẹ́ náà padà wá sọ́dọ̀ rẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi padà wá?”  Nítorí náà, wọ́n sọ fún un pé: “Ọkùnrin kan ni ó gòkè wá pàdé wa, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wa pé, ‘Ẹ lọ, ẹ padà sọ́dọ̀ ọba tí ó rán yín, kí ẹ sì sọ fún un pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí,+ ‘Ṣé nítorí pé kò sí Ọlọ́run rárá ní Ísírẹ́lì ni o fi ń ránṣẹ́ lọ wádìí lọ́dọ̀ Baali-sébúbù ọlọ́run Ékírónì? Nítorí náà, ní ti àga ìrọ̀gbọ̀kú náà, orí èyí tí ìwọ wà, ìwọ kì yóò sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí rẹ̀, nítorí ó dájú pé ìwọ yóò kú.’”’”+  Látàrí èyí, ó bá wọn sọ̀rọ̀ pé: “Kí ni ìrísí ọkùnrin náà tí ó gòkè wá pàdé yín, tí ó sì wá sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún yín?”  Nítorí náà, wọ́n sọ fún un pé: “Ọkùnrin kan tí ó ní ẹ̀wù+ tí a fi irun ṣe, tí ó sì fi ìgbànú awọ di abẹ́nú+ rẹ̀ lámùrè ni.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ pé: “Èlíjà ará Tíṣíbè ni.”  Ó sí tẹ̀ síwájú láti rán olórí àádọ́ta pẹ̀lú àádọ́ta rẹ̀+ sí i. Nígbà tí ó gòkè tọ̀ ọ́ lọ, kíyè sí i, ó jókòó sórí òkè ńlá náà. Ó bá a sọ̀rọ̀ wàyí pé: “Ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́,+ ọba fúnra rẹ̀ sọ pé, ‘Sọ̀ kalẹ̀ wá.’” 10  Ṣùgbọ́n Èlíjà dáhùn, ó sì bá olórí àádọ́ta sọ̀rọ̀ pé: “Tóò, bí mo bá jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run, kí iná+ sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kí ó sì jẹ ìwọ àti àádọ́ta rẹ run.” Iná sì ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀ wá, ó sì jẹ òun àti àádọ́ta rẹ̀+ run. 11  Nítorí náà, ó tún rán olórí àádọ́ta mìíràn pẹ̀lú àádọ́ta rẹ̀+ sí i. Ẹ̀wẹ̀, ó dáhùn, ó sì bá a sọ̀rọ̀ pé: “Ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́, èyí ni ohun tí ọba wí, ‘Sọ̀ kalẹ̀ wá kíákíá.’”+ 12  Ṣùgbọ́n Èlíjà dáhùn, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ pé: “Bí mo bá jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́, kí iná sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kí ó sì jẹ ìwọ àti àádọ́ta rẹ run.” Iná Ọlọ́run sì ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀ wá, ó sì jẹ òun àti àádọ́ta rẹ̀ run. 13  Ó sì tún rán olórí àádọ́ta kẹta pẹ̀lú àádọ́ta rẹ̀.+ Ṣùgbọ́n olórí àádọ́ta kẹta gòkè lọ, ó sì wá, ó sì tẹ̀ ba lórí eékún+ rẹ̀ ní iwájú Èlíjà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi taratara bẹ̀bẹ̀+ fún ojú rere rẹ̀, ó sì bá a sọ̀rọ̀ pé: “Ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́, jọ̀wọ́, jẹ́ kí ọkàn+ mi àti ọkàn àádọ́ta ìránṣẹ́ rẹ wọ̀nyí ṣe iyebíye+ ní ojú rẹ. 14  Kíyè sí i, iná sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, ó sì jẹ olórí àádọ́ta méjì ìṣáájú àti àádọ́ta-àádọ́ta wọn run,+ ṣùgbọ́n nísinsìnyí, jẹ́ kí ọkàn mi ṣe iyebíye ní ojú rẹ.” 15  Látàrí ìyẹn, áńgẹ́lì Jèhófà bá Èlíjà sọ̀rọ̀ pé: “Bá a sọ̀ kalẹ̀ lọ. Má fòyà nítorí rẹ̀.”+ Nítorí náà, ó dìde, ó sì bá a sọ̀ kalẹ̀ lọ sọ́dọ̀ ọba. 16  Nígbà náà ni ó bá a sọ̀rọ̀ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Nítorí ìdí náà pé o rán àwọn ońṣẹ́+ lọ wádìí lọ́dọ̀ Baali-sébúbù ọlọ́run Ékírónì,+ ṣé nítorí pé kò sí Ọlọ́run rárá ní Ísírẹ́lì tí a lè wádìí nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni? Nítorí náà, ní ti àga ìrọ̀gbọ̀kú náà, orí èyí tí ìwọ wà, ìwọ kì yóò sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí rẹ̀, nítorí ó dájú pé ìwọ yóò kú.’” 17  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó kú,+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀+ Jèhófà tí Èlíjà ti sọ; Jèhórámù+ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀, ní ọdún kejì Jèhórámù+ ọmọkùnrin Jèhóṣáfátì ọba Júdà, nítorí pé kò ní ọmọkùnrin kankan. 18  Ní ti ìyókù àwọn nǹkan tí Ahasáyà+ ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì?

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé