Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Tẹsalóníkà 5:1-28

5  Wàyí o, ní ti àwọn ìgbà àti àwọn àsìkò,+ ẹ̀yin ará, ẹ kò nílò kí a kọ̀wé nǹkan kan sí yín.  Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ dáadáa pé ọjọ́ Jèhófà+ ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí olè ní òru.+  Ìgbà yòówù tí ó jẹ́ tí wọ́n+ bá ń sọ pé: “Àlàáfíà+ àti ààbò!” nígbà náà ni ìparun+ òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìroragógó wàhálà lórí obìnrin tí ó lóyún;+ wọn kì yóò sì yè bọ́ lọ́nàkọnà.+  Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, ará, ẹ kò sí nínú òkùnkùn,+ tí ọjọ́ yẹn yóò fi dé bá yín lójijì gẹ́gẹ́ bí yóò ti dé bá àwọn olè,+  nítorí gbogbo yín jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀+ àti ọmọ ọ̀sán.+ Àwa kì í ṣe ti òru tàbí ti òkùnkùn.+  Nítorí bẹ́ẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sùn+ gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù ti ń ṣe,+ ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a wà lójúfò,+ kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́.+  Nítorí ó ti jẹ́ àṣà àwọn tí ń sùn+ láti máa sùn ní òru,+ àwọn tí wọ́n sì ń mu àmupara sábà máa ń mu àmupara ní òru.  Ṣùgbọ́n ní ti àwa tí a jẹ́ ti ọ̀sán, ẹ jẹ́ kí a pa agbára ìmòye wa mọ́, kí a sì gbé àwo ìgbàyà+ ìgbàgbọ́+ àti ìfẹ́ wọ̀ àti ìrètí ìgbàlà+ gẹ́gẹ́ bí àṣíborí;+  nítorí Ọlọ́run kò yàn wá fún ìrunú,+ bí kò ṣe fún rírí ìgbàlà+ nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa.+ 10  Ó kú fún wa,+ pé, yálà a wà lójúfò tàbí a sùn, kí a lè wà láàyè pa pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.+ 11  Nítorí náà, ẹ máa tu ara yín nínú lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa gbé ara yin ró lẹ́nì kìíní-kejì,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe ní tòótọ́.+ 12  Wàyí o, àwa béèrè lọ́wọ́ yín, ẹ̀yin ará, pé kí ẹ ní ẹ̀mí ìkanisí fún àwọn tí ń ṣiṣẹ́ kára láàárín yín, tí wọ́n ń ṣe àbójútó+ yín nínú Olúwa, tí wọ́n sì ń ṣí yín létí; 13  kí ẹ sì máa fún wọn ní ìkàsí tí ó ju àrà ọ̀tọ̀ lọ nínú ìfẹ́ nítorí iṣẹ́ wọn.+ Ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.+ 14  Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, a ń gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, kí ẹ máa fún àwọn tí ń ṣe ségesège+ ní ìṣílétí, ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́,+ ẹ máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera, ẹ máa ní ìpamọ́ra+ fún gbogbo ènìyàn. 15  Ẹ rí i pé ẹnì kankan kò fi ìṣeniléṣe san ìṣeniléṣe fún ẹnikẹ́ni mìíràn,+ ṣùgbọ́n nígbà gbogbo ẹ máa lépa ohun rere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì àti sí gbogbo àwọn ẹlòmíràn.+ 16  Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo.+ 17  Ẹ máa gbàdúrà láìdabọ̀.+ 18  Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohun gbogbo, ẹ máa dúpẹ́.+ Nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù nípa yín. 19  Ẹ má ṣe pa iná ẹ̀mí.+ 20  Ẹ má ṣe fojú tín-ín-rín àwọn ìsọtẹ́lẹ̀.+ 21  Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú;+ ẹ di ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ mú ṣinṣin.+ 22  Ẹ ta kété sí gbogbo oríṣi ìwà burúkú.+ 23  Kí Ọlọ́run àlàáfíà+ fúnra rẹ̀ sọ yín di mímọ́ pátápátá.+ Àti ní yíyèkooro lọ́nà gbogbo, kí a pa ẹ̀mí àti ọkàn àti ara ẹ̀yin ará mọ́ lọ́nà tí ó jẹ́ aláìlẹ́bi nígbà wíwàníhìn-ín Olúwa wa Jésù Kristi.+ 24  Ẹni tí ń pè yín jẹ́ olùṣòtítọ́, yóò sì ṣe é pẹ̀lú. 25  Ẹ̀yin ará, ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà fún wa.+ 26  Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí gbogbo àwọn ará.+ 27  Mo ń fi yín sábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe wíwúwo nípasẹ̀ Olúwa pé kí ẹ ka lẹ́tà yìí fún gbogbo àwọn ará.+ 28  Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ Olúwa wa Jésù Kristi wà pẹ̀lú yín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé