Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Tẹsalóníkà 4:1-18

4  Lákòótán, ẹ̀yin ará, a ń béèrè lọ́wọ́ yín, a sì ń gbà yín níyànjú nípasẹ̀ Jésù Olúwa, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gba ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ wa lórí bí ó ṣe yẹ kí ẹ máa rìn,+ kí ẹ sì máa wu Ọlọ́run, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń rìn ní ti tòótọ́, pé kí ẹ tẹra mọ́ títúbọ̀ ṣe é lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́.+  Nítorí ẹ mọ àwọn àṣẹ ìtọ́ni+ tí a fún yín nípasẹ̀ Jésù Olúwa.  Nítorí èyí ni ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, sísọ yín di mímọ́,+ pé kí ẹ ta kété sí àgbèrè;+  pé kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun èlò+ tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́+ àti ọlá,  kì í ṣe nínú ìdálọ́rùn olójúkòkòrò fún ìbálòpọ̀ takọtabo+ irúfẹ́ èyí tí àwọn orílẹ̀-èdè+ wọnnì pẹ̀lú tí kò mọ Ọlọ́run+ ní;  pé kí ẹnì kankan má ṣe lọ títí dé àyè ṣíṣe ìpalára fún àti rírakakalé àwọn ẹ̀tọ́ arákùnrin rẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí,+ nítorí Jèhófà ni ẹni tí ń fi ìyà jẹni ní dandan fún gbogbo nǹkan wọ̀nyí,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti sọ fún yín ṣáájú, tí a sì tún jẹ́rìí kúnnákúnná fún yín.+  Nítorí Ọlọ́run kò pè wá pẹ̀lú ìyọ̀ǹda fún ìwà àìmọ́, bí kò ṣe ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìsọdimímọ́.+  Nítorí bẹ́ẹ̀, ènìyàn tí ó bá fi ìwà àìkanisí hàn,+ kì í ṣe ènìyàn ni ó ń ṣàìkàsí, bí kò ṣe Ọlọ́run,+ ẹni tí ó fí ẹ̀mí mímọ́+ rẹ̀ sínú yín.  Bí ó ti wù kí ó rí, ní ti ìfẹ́ ará,+ ẹ kò nílò kí a máa kọ̀wé sí yín, nítorí Ọlọ́run ti kọ́ ẹ̀yin fúnra yín+ láti nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì;+ 10  ní ti tòótọ́, ẹ sì ń ṣe é sí gbogbo àwọn ará ní gbogbo Makedóníà. Ṣùgbọ́n a gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, láti máa bá a lọ ní ṣíṣe é ní ìwọ̀n kíkúnrẹ́rẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ, 11  kí ẹ sì fi í ṣe ìfojúsùn yín láti máa gbé ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́,+ kí ẹ má sì máa yọjú sí ọ̀ràn ọlọ́ràn,+ kí ẹ sì máa fi ọwọ́ yín ṣiṣẹ́,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti pa àṣẹ ìtọ́ni fún yín; 12  kí ẹ lè máa rìn lọ́nà bíbójúmu+ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń bẹ lóde,+ kí ẹ má sì ṣe aláìní ohunkóhun.+ 13  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin ará, a kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀ nípa àwọn tí ń sùn+ nínú ikú; kí ẹ má bàa kárí sọ gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù tí kò ní ìrètí ti ń ṣe pẹ̀lú.+ 14  Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ìgbàgbọ́ wa ni pé Jésù kú, ó sì tún dìde,+ bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú, àwọn tí ó ti sùn nínú ikú nípasẹ̀ Jésù ni Ọlọ́run yóò mú wá pẹ̀lú rẹ̀.+ 15  Nítorí èyí ni ohun tí a sọ fún yín nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Jèhófà,+ pé àwa alààyè tí a kù nílẹ̀ di ìgbà wíwàníhìn-ín Olúwa+ kì yóò ṣáájú àwọn tí ó ti sùn nínú ikú lọ́nàkọnà; 16  nítorí Olúwa fúnra rẹ̀ yóò sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run+ wá pẹ̀lú ìpè àṣẹ, pẹ̀lú ohùn olú-áńgẹ́lì+ àti pẹ̀lú kàkàkí+ Ọlọ́run, àwọn tí ó kú ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi ni yóò sì kọ́kọ́ dìde.+ 17  Lẹ́yìn náà, àwa alààyè tí a kù nílẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú wọn,+ ni a ó gbà lọ+ dájúdájú nínú àwọsánmà+ láti pàdé+ Olúwa nínú afẹ́fẹ́; a ó sì tipa báyìí máa wà pẹ̀lú Olúwa nígbà gbogbo.+ 18  Nítorí náà, ẹ máa fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tu ara yín nínú lẹ́nì kìíní-kejì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé