Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Tẹsalóníkà 3:1-13

3  Nítorí bẹ́ẹ̀, nígbà tí a kò lè mú un mọ́ra mọ́, a rí i pé ó dára kí a fi àwa nìkan sílẹ̀ ní Áténì;+  a sì rán Tímótì,+ arákùnrin wa àti òjíṣẹ́ Ọlọ́run nínú ìhìn rere+ nípa Kristi, láti fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in àti láti tù yín nínú nítorí ìgbàgbọ́ yín,  kí ìpọ́njú+ wọ̀nyí má bàa mú ẹnì kankan yẹsẹ̀. Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé a yàn wá sípò fún nǹkan yìí gan-an.+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ní ti tòótọ́, nígbà tí a wà pẹ̀lú yín, a ti máa ń sọ fún yín tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀+ pé a ti yàn wá tẹ́lẹ̀ láti ní ìpọ́njú,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú àti gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀.+  Ìdí nìyẹn, ní tòótọ́, nígbà tí èmi kò lè mú un mọ́ra mọ́, tí mo fi ránṣẹ́ láti mọ̀ nípa ìṣòtítọ́ yín,+ pé bóyá lọ́nà kan ṣáá Adẹniwò+ lè ti dẹ yín wò, òpò wa sì ti lè já sí asán.+  Ṣùgbọ́n Tímótì ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ọ̀dọ̀ wa nísinsìnyí láti ọ̀dọ̀ yín,+ ó sì fún wa ní ìhìn rere nípa ìṣòtítọ́ àti ìfẹ́ yín,+ àti pé ẹ ń bá a lọ ní rírántí wa sí dáadáa nígbà gbogbo, tí ẹ ń fẹ́ gidigidi láti rí wa lọ́nà kan náà, ní tòótọ́, bí àwa pẹ̀lú ti ṣe sí yín.+  Ìdí nìyẹn, ẹ̀yin ará, tí a fi tù wá nínú+ nítorí yín nínú gbogbo àìní àti ìpọ́njú wa nípasẹ̀ ìṣòtítọ́ tí ẹ ń fi hàn,+  nítorí nísinsìnyí, a wà láàyè bí ẹ bá dúró gbọn-in gbọn-in nínú Olúwa.+  Nítorí ìdúpẹ́ wo ni a lè ṣe fún Ọlọ́run nítorí yín ní ìdápadà fún gbogbo ìdùnnú tí a fi ń yọ̀+ nítorí yín níwájú Ọlọ́run wa, 10  nígbà tí ó jẹ́ pé lóru àti lọ́sàn-án ni a ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀+ tí ó ju àrà ọ̀tọ̀ lọ láti rí ojú yín àti láti dí àwọn ohun tí ìgbàgbọ́ yín ṣaláìní?+ 11  Wàyí o, kí Ọlọ́run àti Baba wa fúnra rẹ̀ àti Jésù Olúwa+ wa fi àṣeyọrí sí rere darí ọ̀nà wa sọ́dọ̀ yín. 12  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí Olúwa mú kí ẹ pọ̀ sí i,+ bẹ́ẹ̀ ni, kí ó mú kí ẹ pọ̀ gidigidi, nínú ìfẹ́+ sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì àti sí gbogbo ènìyàn, àní gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti ṣe sí yín; 13  fún ète pé kí ó lè fìdí ọkàn-àyà yín múlẹ̀ gbọn-in, láìṣeé dá lẹ́bi+ nínú ìjẹ́mímọ́ níwájú Ọlọ́run àti Baba wa nígbà wíwàníhìn-ín+ Jésù Olúwa wa pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé