Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Tẹsalóníkà 2:1-20

2  Láìsí àní-àní, ẹ̀yin fúnra yín mọ̀, ẹ̀yin ará, bí ìbẹ̀wò+ wa sọ́dọ̀ yín kò ti jẹ́ aláìní àwọn ìyọrísí,+  ṣùgbọ́n bí àwa, lẹ́yìn tí a ti kọ́kọ́ jìyà,+ tí a sì hùwà sí wa lọ́nà àfojúdi+ (gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀) ní ìlú Fílípì,+ ti máyàle nípasẹ̀ Ọlọ́run wa láti sọ+ ìhìn rere Ọlọ́run fún yín pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìjàkadì.  Nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú tí a ń fi fúnni kò wá láti inú ìṣìnà tàbí láti inú ìwà àìmọ́+ tàbí pẹ̀lú ẹ̀tàn,  ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti fi wá hàn ní ẹni tí ó yẹ kí a fi ìhìn rere sí ní ìkáwọ́,+ bẹ́ẹ̀ ni a ń sọ̀rọ̀, kì í ṣe bí ẹni tí ń wu+ ènìyàn, bí kò ṣe Ọlọ́run, ẹni tí ń mú kí a fi ohun tí ọkàn-àyà wa jẹ́ hàn.+  Ní ti tòótọ́, kò sí ìgbà kankan rí tí a fara hàn yálà nínú ọ̀rọ̀ ìpọ́nni,+ (gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀) tàbí nínú ìrísí ẹ̀tàn+ fún ojúkòkòrò,+ Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí!  Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé a ti ń wá ògo láti ọ̀dọ̀ ènìyàn,+ ó tì o, ì báà ṣe láti ọ̀dọ̀ yín tàbí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè jẹ́ ẹrù ìnira+ tí ń wọni lọ́rùn gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Kristi.  Kàkà bẹ́ẹ̀, àwa di ẹni pẹ̀lẹ́ láàárín yín, bí ìgbà tí abiyamọ ń ṣìkẹ́+ àwọn ọmọ tirẹ̀.  Nítorí náà, ní níní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún yín,+ ó dùn mọ́ wa nínú jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ọkàn àwa fúnra wa pẹ̀lú,+ nítorí ẹ di olùfẹ́ ọ̀wọ́n+ fún wa.  Ẹ̀yin ará, ó dájú pé ẹ fi òpò àti làálàá wa sọ́kàn. Pẹ̀lú ṣíṣiṣẹ́+ ní òru àti ọ̀sán ni a fi wàásù ìhìn rere Ọlọ́run fún yín, kí a má bàa gbé ẹrù ìnira tí ń wọni lọ́rùn lé ẹnikẹ́ni nínú yín lórí.+ 10  Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí, Ọlọ́run jẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, bí a ti jẹ́ adúróṣinṣin àti olódodo àti aláìṣeé-dálẹ́bi+ sí ẹ̀yin onígbàgbọ́. 11  Ní ìbámu pẹ̀lú èyíinì, ẹ mọ̀ dáadáa bí a tí ń bá a nìṣó ní gbígba ẹnì kọ̀ọ̀kan yín níyànjú,+ àti ní títù yín nínú àti ní jíjẹ́rìí yín, bí baba+ ti ń ṣe sí àwọn ọmọ rẹ̀, 12  fún ète pé kí ẹ lè máa bá a lọ ní rírìn+ lọ́nà tí ó yẹ Ọlọ́run, ẹni tí ń pè+ yín sí ìjọba+ àti ògo rẹ̀. 13  Ní tòótọ́, ìdí nìyẹn tí àwa pẹ̀lú fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run láìdabọ̀,+ nítorí nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,+ èyí tí ẹ gbọ́ láti ọ̀dọ̀ wa, ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn,+ ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ pẹ̀lú nínú ẹ̀yin onígbàgbọ́.+ 14  Nítorí, ẹ̀yin ará, ẹ di aláfarawé àwọn ìjọ Ọlọ́run tí ń bẹ ní Jùdíà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù, nítorí ẹ̀yin pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí jìyà lọ́wọ́ àwọn ará ilẹ̀ ìbílẹ̀ tiyín àwọn ohun kan náà gẹ́gẹ́ bí àwọn pẹ̀lú ti ń jìyà+ lọ́wọ́ àwọn Júù, 15  àwọn tí wọ́n pa Jésù Olúwa+ pàápàá àti àwọn wòlíì,+ tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí wa.+ Síwájú sí i, wọn kò wu Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n lòdì sí ire gbogbo ènìyàn, 16  bí wọ́n ti ń gbìyànjú láti dí wa lọ́wọ́+ bíbá àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè sọ̀rọ̀ kí a lè gba àwọn wọ̀nyí là,+ pẹ̀lú ìyọrísí náà pé wọ́n ń kún òṣùwọ̀n+ ẹ̀ṣẹ̀ wọn dókè nígbà gbogbo. Ṣùgbọ́n ìrunú rẹ̀ ti dé sórí wọn+ níkẹyìn. 17  Ní ti àwa fúnra wa, ẹ̀yin ará, nígbà tí a gbà yín kúrò lọ́wọ́ wa fún kìkì àkókò kúkúrú, nínú ara, kì í ṣe nínú ọkàn-àyà, a sakun púpọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá láti rí ojú yín pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ńláǹlà.+ 18  Fún ìdí yìí, a fẹ́ wá sọ́dọ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni, èmi Pọ́ọ̀lù, lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n Sátánì dábùú ọ̀nà wa. 19  Nítorí kí ni ìrètí tàbí ìdùnnú tàbí adé+ ayọ̀ ńláǹlà wa—họ́wù, ní ti tòótọ́, kì í ha ṣe ẹ̀yin ni bí?—níwájú Jésù Olúwa wa nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀?+ 20  Dájúdájú, ẹ̀yin ni ògo àti ìdùnnú wa.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé