Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Tẹsalóníkà 1:1-10

1  Pọ́ọ̀lù àti Sílífánù+ àti Tímótì+ sí ìjọ àwọn ará Tẹsalóníkà ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú Ọlọ́run Baba àti Jésù Kristi Olúwa: Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà.+  Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa gbogbo yín nínú àwọn àdúrà wa,+  nítorí láìdabọ̀ ni a ń fi iṣẹ́ ìṣòtítọ́+ yín sọ́kàn àti òpò onífẹ̀ẹ́ yín àti ìfaradà yín nítorí ìrètí+ yín nínú Olúwa wa Jésù Kristi níwájú Ọlọ́run àti Baba wa.  Nítorí a mọ̀, ẹ̀yin ará tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́, yíyàn tí òun yàn yín,+  nítorí ìhìn rere tí a ń wàásù kò fara hàn láàárín yín nínú ọ̀rọ̀ nìkan ṣùgbọ́n nínú agbára+ pẹ̀lú àti nínú ẹ̀mí mímọ́ àti ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó lágbára,+ gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ irú ènìyàn tí a wá jẹ́ sí yín nítorí yín;+  ẹ sì di aláfarawé+ wa àti ti Olúwa,+ níwọ̀n bí ẹ ti tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ náà lábẹ́ ìpọ́njú+ púpọ̀ pẹ̀lú ìdùnnú ẹ̀mí mímọ́,+  tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ wá di àpẹẹrẹ fún gbogbo onígbàgbọ́ ní Makedóníà àti ní Ákáyà.  Òtítọ́ náà ni pé, kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ Jèhófà+ ti dún jáde láti ọ̀dọ̀ yín ní Makedóníà àti Ákáyà nìkan ni, ṣùgbọ́n ní ibi gbogbo, ìgbàgbọ́+ yín sí Ọlọ́run ti tàn káàkiri,+ tó bẹ́ẹ̀ tí a kò nílò láti máa sọ ohunkóhun.  Nítorí àwọn fúnra wọn ń ròyìn ṣáá nípa bí a ti kọ́kọ́ wọlé sí àárín yín àti bí ẹ ṣe yí padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run kúrò nínú òrìṣà+ yín láti sìnrú fún Ọlọ́run tòótọ́+ àti alààyè,+ 10  àti láti dúró+ de Ọmọ rẹ̀ láti ọ̀run,+ ẹni tí òun gbé dìde kúrò nínú òkú,+ èyíinì ni, Jésù, ẹni tí ó dá wa nídè kúrò nínú ìrunú tí ń bọ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé