Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Tímótì 6:1-21

6  Kí gbogbo àwọn tí ó jẹ́ ẹrú lábẹ́ àjàgà máa bá a lọ ní kíka olúwa wọn yẹ sí ọlá kíkún,+ kí orúkọ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ náà má bàa di èyí tí a sọ̀rọ̀ sí lọ́nà ìbàjẹ́ láé.+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, kí àwọn tí ó ní àwọn olúwa+ tí ó gbà gbọ́ má ṣe fojú tẹ́ńbẹ́lú wọn,+ nítorí pé wọ́n jẹ́ ará.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, kí wọ́n túbọ̀ múra tán láti jẹ́ ẹrú, nítorí àwọn tí ń jàǹfààní iṣẹ́ ìsìn rere wọn jẹ́ onígbàgbọ́ àti olùfẹ́ ọ̀wọ́n. Máa bá a nìṣó ní kíkọ́ni ní nǹkan wọ̀nyí+ àti fífúnni ní ọ̀rọ̀ ìyànjú wọ̀nyí.  Bí ọkùnrin èyíkéyìí bá ń fi ẹ̀kọ́ mìíràn kọ́ni,+ tí kò sì fara mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera,+ tí ó jẹ́ ti Olúwa wa Jésù Kristi, tàbí ẹ̀kọ́ tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run,+  ó ń wú fùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga,+ láìlóye ohunkóhun,+ ṣùgbọ́n ó jẹ́ olókùnrùn ní èrò orí+ lórí bíbéèrè ìbéèrè àti fífa ọ̀rọ̀.+ Láti inú nǹkan wọ̀nyí ni ìlara+ ti ń jáde wá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, ọ̀rọ̀ èébú,+ ìfura burúkú,  awuyewuye lílenípá lórí àwọn ohun tí kò tó nǹkan níhà ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí a ti sọ èrò inú wọn di ìbàjẹ́,+ tí a sì ti fi òtítọ́ wọn ṣe ìjẹ,+ wọ́n ń ronú pé fífọkànsin Ọlọ́run jẹ́ ọ̀nà èrè.+  Láìsí àní-àní, ó jẹ́ ọ̀nà èrè ńlá,+ àní fífọkànsin Ọlọ́run+ pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi.+  Nítorí a kò mú nǹkan kan wá sínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mú ohunkóhun jáde.+  Nítorí náà, bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.+  Àmọ́ ṣá o, àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò+ àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn+ tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.+ 10  Nítorí ìfẹ́+ owó ni gbòǹgbò+ onírúurú ohun aṣeniléṣe+ gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora+ gún ara wọn káàkiri. 11  Àmọ́ ṣá o, ìwọ, ènìyàn Ọlọ́run, sá fún nǹkan wọ̀nyí.+ Ṣùgbọ́n máa lépa òdodo, fífọkànsin Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ìfaradà, inú tútù.+ 12  Ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́,+ di ìyè àìnípẹ̀kun mú gírígírí èyí tí a torí rẹ̀ pè ọ́, tí ìwọ sì ṣe ìpolongo+ àtàtà ní gbangba níwájú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹlẹ́rìí. 13  Níwájú Ọlọ́run, ẹni tí ó pa ohun gbogbo mọ́ láàyè, àti ti Kristi Jésù, ẹni tí ó ṣe ìpolongo+ àtàtà ní gbangba gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí+ níwájú Pọ́ńtíù Pílátù,+ mo fún ọ ní àwọn àṣẹ ìtọ́ni+ 14  pé kí o pa àṣẹ náà mọ́ lọ́nà àìléèérí àti àìlẹ́gàn títí di ìgbà ìfarahàn+ Olúwa wa Jésù Kristi. 15  Ìfarahàn yìí ni aláyọ̀ àti Ọba Alágbára Gíga+ kan ṣoṣo náà yóò fi hàn ní àwọn àkókò rẹ̀ tí a yàn kalẹ̀,+ òun Ọba+ àwọn tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti Olúwa+ àwọn tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí olúwa, 16  ẹnì kan ṣoṣo tí ó ní àìkú,+ ẹni tí ń gbé nínú ìmọ́lẹ̀ tí kò ṣeé sún mọ́,+ ẹni tí kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tí ó ti rí i tàbí lè rí i.+ Òun ni kí ọlá+ àti agbára ńlá àìnípẹ̀kun jẹ́ tirẹ̀. Àmín. 17  Fún àwọn ọlọ́rọ̀+ nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ní àṣẹ ìtọ́ni láti má ṣe jẹ́ ọlọ́kàn-gíga,+ kí wọ́n má ṣe gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú,+ bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa;+ 18  láti máa ṣe rere,+ láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà,+ láti jẹ́ aláìṣahun, kí wọ́n múra tán láti ṣe àjọpín,+ 19  kí wọ́n máa fi àìséwu to ìṣúra+ ìpìlẹ̀+ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wọn de ẹ̀yìn ọ̀la, kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́+ mú gírígírí. 20  Ìwọ Tímótì, máa ṣọ́ ohun tí a tò jọ ní ìtọ́júpamọ́ sọ́dọ̀ rẹ,+ yẹra fún àwọn òfìfo ọ̀rọ̀ tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́ àti fún àwọn ìtakora ohun tí a fi èké pè ní “ìmọ̀.”+ 21  Nítorí ní ṣíṣe àṣehàn irúfẹ́ ìmọ̀ bẹ́ẹ̀, àwọn kan ti yapa kúrò nínú ìgbàgbọ́.+ Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí wà pẹ̀lú yín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé