Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Tímótì 5:1-25

5  Má ṣe fi àṣìṣe àgbà ọkùnrin hàn lọ́nà mímúná janjan.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, pàrọwà fún un gẹ́gẹ́ bí baba, àwọn ọ̀dọ́kùnrin gẹ́gẹ́ bí arákùnrin,  àwọn àgbà obìnrin+ gẹ́gẹ́ bí ìyá, àwọn ọ̀dọ́bìnrin gẹ́gẹ́ bí arábìnrin+ pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.  Bọlá fún àwọn opó tí wọ́n jẹ́ opó ní ti gidi.+  Ṣùgbọ́n bí opó èyíkéyìí bá ní àwọn ọmọ tàbí àwọn ọmọ-ọmọ, kí àwọn wọ̀nyí kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ láti máa fi ìfọkànsin Ọlọ́run ṣe ìwà hù nínú agbo ilé+ tiwọn, kí wọ́n sì máa san àsanfidípò yíyẹ fún àwọn òbí+ wọn àti àwọn òbí wọn àgbà, nítorí tí èyí ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run.+  Wàyí o, obìnrin tí ó jẹ́ opó ní ti gidi, tí a sì fi sílẹ̀ ní aláìní,+ ti fi ìrètí rẹ̀ sínú Ọlọ́run,+ ó sì tẹpẹlẹ mọ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àti àdúrà lóru àti lọ́sàn-án.+  Ṣùgbọ́n èyí tí ó kó wọnú títẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara lọ́rùn+ ti kú+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì wà láàyè.  Nítorí náà, máa bá a nìṣó ní pípa àṣẹ wọ̀nyí,+ kí wọ́n lè jẹ́ aláìlẹ́gàn.+  Dájúdájú, bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀,+ àti ní pàtàkì fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀,+ ó ti sẹ́+ ìgbàgbọ́,+ ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.  Kí a fi orúkọ opó kan sínú ìwé àkọsílẹ̀, ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò dín ní ọgọ́ta ọdún, tí ó jẹ́ aya ọkọ kan,+ 10  tí ó ní ẹ̀rí tí a jẹ́ sí i fún àwọn iṣẹ́ àtàtà,+ bí ó bá tọ́ àwọn ọmọ,+ bí ó bá ṣe àwọn àjèjì lálejò,+ bí ó bá wẹ ẹsẹ̀ àwọn ẹni mímọ́,+ bí ó bá mú ìtura bá àwọn tí ó wà nínú ìpọ́njú,+ bí ó bá fi taápọn-taápọn tẹ̀ lé gbogbo iṣẹ́ rere.+ 11  Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kọ̀ láti gba àwọn opó tí wọ́n kéré ní ọjọ́ orí, nítorí nígbà tí òòfà-ọkàn wọn fún ìbálòpọ̀ takọtabo bá ti wá sí àárín àwọn àti Kristi,+ wọn a fẹ́ láti ṣe ìgbéyàwó, 12  ní gbígba ìdájọ́ nítorí tí wọ́n ti ṣàìka gbólóhùn ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ wọn àkọ́kọ́ sí.+ 13  Ní àkókò kan náà, wọ́n tún kọ́ láti jẹ́ olóòrayè, wọ́n ń rin ìrìn ìranù kiri lọ sí àwọn ilé; bẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe aláìníṣẹ́ nìkan, ṣùgbọ́n olófòófó pẹ̀lú àti alátojúbọ àlámọ̀rí àwọn ẹlòmíràn,+ wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí kò yẹ kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. 14  Nítorí náà, mo fẹ́ kí àwọn opó tí ó kéré ní ọjọ́ orí ṣe ìgbéyàwó,+ kí wọ́n bímọ,+ kí wọ́n mójú tó agbo ilé kan, kí wọ́n má ṣe fún alátakò ní ìsúnniṣe kankan láti kẹ́gàn.+ 15  Nísinsìnyí gan-an, ní tòótọ́, àwọn kan ni a ti yí sápá kan láti tẹ̀ lé Sátánì. 16  Bí obìnrin èyíkéyìí tí ó gbà gbọ́ bá ní àwọn opó, kí ó mú ìtura bá wọn,+ kí ìjọ má sì wà lábẹ́ ẹrù ìnira náà. Nígbà náà, ìjọ yóò lè mú ìtura bá àwọn tí ó jẹ́ opó ní ti gidi.+ 17  Kí a ka àwọn àgbà ọkùnrin tí ń ṣe àbójútó+ lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ yẹ fún ọlá ìlọ́po méjì,+ ní pàtàkì, àwọn tí ń ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni.+ 18  Nítorí tí ìwé mímọ́ wí pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ dí akọ màlúù lẹ́nu nígbà tí ó bá ń pa ọkà”;+ bákan náà: “Aṣiṣẹ́ yẹ fún owó ọ̀yà rẹ̀.”+ 19  Má ṣe gba ẹ̀sùn lòdì sí àgbà ọkùnrin, àyàfi kìkì lórí ẹ̀rí ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta.+ 20  Àwọn tí ń sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá+ dàṣà ni kí o fi ìbáwí tọ́ sọ́nà+ níwájú gbogbo òǹwòran, kí àwọn yòókù pẹ̀lú lè bẹ̀rù.+ 21  Mo pàṣẹ fún ọ lọ́nà tí ó wúwo rinlẹ̀ níwájú Ọlọ́run àti Kristi Jésù+ àti àwọn áńgẹ́lì àyànfẹ́ láti pa nǹkan wọ̀nyí mọ́ láìsí ìdájọ́ kò-dúró-gbẹ́jọ́, láìṣe ohunkóhun ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí ìgbèsápákan.+ 22  Má ṣe fi ìkánjú gbé ọwọ́+ lé ọkùnrin èyíkéyìí+ láé; bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe jẹ́ alájọpín nínú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn;+ pa ara rẹ mọ́ ní oníwàmímọ́.+ 23  Má mu omi mọ́, ṣùgbọ́n máa lo wáìnì+ díẹ̀ nítorí àpòlúkù rẹ àti ọ̀ràn àìsàn rẹ tí ó ṣe lemọ́lemọ́. 24  Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn kan a máa fara hàn gbangba,+ ní ṣíṣamọ̀nà sí ìdájọ́ ní tààràtà, ṣùgbọ́n ní ti àwọn ẹlòmíràn, ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú a máa fara hàn kedere lẹ́yìn-ọ̀-rẹ̀yìn.+ 25  Lọ́nà kan náà pẹ̀lú, àwọn iṣẹ́ àtàtà a máa fara hàn gbangba,+ àwọn tí kò sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a kò lè fi pa mọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé