Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Tímótì 4:1-16

4  Bí ó ti wù kí ó rí, àsọjáde onímìísí sọ ní pàtó pé ní ìkẹyìn àwọn sáà àkókò,+ àwọn kan yóò yẹsẹ̀+ kúrò nínú ìgbàgbọ́, ní fífi àfiyèsí sí àwọn àsọjáde onímìísí tí ń ṣini lọ́nà+ àti àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù,+  nípasẹ̀ àgàbàgebè àwọn ènìyàn tí ń purọ́,+ àwọn tí a ti sàmì sí inú ẹ̀rí-ọkàn+ wọn gẹ́gẹ́ bí pé pẹ̀lú irin ìsàmì;  wọ́n ń ka gbígbéyàwó léèwọ̀,+ wọ́n ń pàṣẹ pé kí a ta kété sí àwọn oúnjẹ+ tí Ọlọ́run dá+ pé kí àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́,+ tí wọ́n sì mọ òtítọ́ lọ́nà pípéye lè máa jẹ nínú wọn pẹ̀lú ìdúpẹ́.  Ìdí fún èyí ni pé gbogbo ìṣẹ̀dá Ọlọ́run ni ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀,+ kò sì sí nǹkan kan tí ó yẹ kí a kọ̀+ bí a bá fi ìdúpẹ́ gbà á,+  nítorí tí a sọ ọ́ di mímọ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà lórí rẹ̀.  Nípa fífún àwọn ará ní ìmọ̀ràn wọ̀nyí, ìwọ yóò jẹ́ òjíṣẹ́ àtàtà ti Kristi Jésù, ọ̀kan tí a fi àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ bọ́ àti ti ẹ̀kọ́ àtàtà+ tí ìwọ ti tẹ̀ lé pẹ́kípẹ́kí.+  Ṣùgbọ́n kọ̀ láti gba àwọn ìtàn èké+ tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́, èyí tí àwọn arúgbó obìnrin máa ń sọ. Ní òdì-kejì ẹ̀wẹ̀, máa kọ́ ara rẹ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìfojúsùn rẹ.+  Nítorí ara títọ́ ṣàǹfààní fún ohun díẹ̀; ṣùgbọ́n fífọkànsin Ọlọ́run+ ṣàǹfààní fún ohun gbogbo,+ bí ó ti ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ̀.+  Gbólóhùn náà+ ṣeé gbíyè lé, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà kíkún. 10  Nítorí fún ète yìí ni àwa ń ṣiṣẹ́ kára, tí a sì ń tiraka,+ nítorí tí a ti gbé ìrètí+ wa lé Ọlọ́run alààyè, ẹni tí ó jẹ́ Olùgbàlà+ gbogbo onírúurú ènìyàn,+ ní pàtàkì ti àwọn olùṣòtítọ́.+ 11  Máa bá a nìṣó ní pípa àṣẹ+ wọ̀nyí àti fífi wọ́n kọ́ni.+ 12  Má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kankan fojú tẹ́ńbẹ́lú èwe rẹ láé.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, di àpẹẹrẹ+ fún àwọn olùṣòtítọ́+ nínú ọ̀rọ̀ sísọ, nínú ìwà, nínú ìfẹ́, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́.+ 13  Láàárín àkókò tí mo ń bọ̀wá, máa bá a lọ ní fífi ara rẹ fún ìwé kíkà+ ní gbangba,+ fún ìgbani-níyànjú, fún kíkọ́ni. 14  Má ṣe máa ṣàìnáání ẹ̀bùn+ tí ń bẹ nínú rẹ, èyí tí a fi fún ọ nípasẹ̀ ìsọtẹ́lẹ̀+ àti nígbà tí ẹgbẹ́ àwọn àgbà ọkùnrin gbé ọwọ́+ lé ọ. 15  Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí;+ fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú+ rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn. 16  Máa fiyè sí ara rẹ+ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ.+ Dúró nínú nǹkan wọ̀nyí, nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé