Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Tímótì 3:1-16

3  Gbólóhùn náà ṣeé gbíyè lé.+ Bí ọkùnrin èyíkéyìí bá ń nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó,+ iṣẹ́ àtàtà ni ó ń fẹ́.  Nítorí náà, alábòójútó ní láti jẹ́ aláìlẹ́gàn,+ ọkọ aya kan, oníwọ̀ntúnwọ̀nsì+ nínú ìwà, ẹni tí ó yè kooro ní èrò inú,+ tí ó wà létòletò,+ tí ó ní ẹ̀mí aájò àlejò,+ ẹni tí ó tóótun láti kọ́ni,+  kì í ṣe aláriwo ọ̀mùtípara,+ kì í ṣe aluni,+ bí kò ṣe afòyebánilò,+ kì í ṣe aríjàgbá,+ kì í ṣe olùfẹ́ owó,+  ọkùnrin kan tí ń ṣe àbójútó agbo ilé tirẹ̀ lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀,+ tí ó ní àwọn ọmọ tí wọ́n ní ìtẹríba pẹ̀lú gbogbo ìwà àgbà;+  (ní tòótọ́, bí ọkùnrin èyíkéyìí kò bá mọ agbo ilé ara rẹ̀ bójú tó, báwo ni yóò ṣe bójú tó ìjọ Ọlọ́run?)  kì í ṣe ọkùnrin tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yí lọ́kàn padà,+ fún ìbẹ̀rù pé ó lè wú fùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga,+ kí ó sì ṣubú sínú ìdájọ́ tí a ṣe fún Èṣù.+  Ní àfikún, ó tún ní láti ní gbólóhùn ẹ̀rí tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn lóde,+ kí ó má bàa ṣubú sínú ẹ̀gàn àti ìdẹkùn+ Èṣù.  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́+ ní láti ní ìwà àgbà, kì í ṣe ẹlẹ́nu méjì, kí wọ́n má ṣe fi ara wọn fún ọ̀pọ̀ wáìnì, kí wọ́n má ṣe jẹ́ oníwọra fún èrè àbòsí,+  kí wọ́n máa di àṣírí ọlọ́wọ̀+ ti ìgbàgbọ́ mú pẹ̀lú ẹ̀rí-ọkàn tí ó mọ́.+ 10  Pẹ̀lúpẹ̀lù, kí a kọ́kọ́ dán àwọn wọ̀nyí wò+ ní ti bí wọn ti yẹ sí, lẹ́yìn náà kí wọ́n sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́, bí wọn kò ti ní ẹ̀sùn lọ́rùn.+ 11  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn obìnrin ní láti jẹ́ oníwà àgbà, kì í ṣe afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́,+ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì+ nínú ìwà, olùṣòtítọ́ nínú ohun gbogbo.+ 12  Kí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ jẹ́ ọkọ aya kan,+ tí ń ṣe àbójútó àwọn ọmọ àti agbo ilé tiwọn lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.+ 13  Nítorí àwọn ọkùnrin tí ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ ń jèrè ìdúró tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀+ fún ara wọn àti òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ńláǹlà+ nínú ìgbàgbọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù. 14  Èmi ń kọ nǹkan wọ̀nyí sí ọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ní ìrètí láti wá sọ́dọ̀ rẹ láìpẹ́,+ 15  ṣùgbọ́n bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé n kò tètè dé, kí ìwọ lè mọ̀ bí ó ti yẹ kí o máa hùwà nínú agbo ilé Ọlọ́run,+ èyí tí í ṣe ìjọ Ọlọ́run alààyè, ọwọ̀n àti ìtìlẹyìn+ òtítọ́. 16  Ní ti tòótọ́, àṣírí ọlọ́wọ̀+ yìí ti fífọkànsin Ọlọ́run ni a gbà pé ó ga lọ́lá: ‘A fi í hàn kedere ní ẹran ara,+ a polongo rẹ̀ ní olódodo nínú ẹ̀mí,+ ó fara han àwọn áńgẹ́lì,+ a wàásù nípa rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ a gbà á gbọ́ nínú ayé,+ a gbà á sókè nínú ògo.’+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé