Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Tímótì 2:1-15

2  Nítorí náà, ọ̀rọ̀ ìyànjú mi ni pé, ṣáájú ohun gbogbo, kí a máa ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, àdúrà,+ ìbẹ̀bẹ̀fúnni, ọrẹ ẹbọ ọpẹ́, nípa gbogbo onírúurú ènìyàn,+  nípa àwọn ọba+ àti gbogbo àwọn tí ó wà ní ipò gíga;+ kí a lè máa bá a lọ ní gbígbé ìgbésí ayé píparọ́rọ́ àti dídákẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ àti ìwà àgbà.+  Èyí dára lọ́pọ̀lọpọ̀, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà+ lójú Olùgbàlà wa, Ọlọ́run,+  ẹni tí ó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn+ là,+ kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye+ nípa òtítọ́.+  Nítorí Ọlọ́run kan+ ni ó wà, àti alárinà kan+ láàárín Ọlọ́run+ àti àwọn ènìyàn,+ ọkùnrin kan, Kristi Jésù,+  ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fúnni ní ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí fún gbogbo ènìyàn+—èyí ni ohun tí a óò jẹ́rìí sí ní àwọn àkókò rẹ̀ gan-an.  Fún ète ẹ̀rí yìí,+ a yàn mí ṣe oníwàásù àti àpọ́sítélì+—èmi ń sọ òtítọ́,+ èmi kò purọ́—olùkọ́ àwọn orílẹ̀-èdè+ nínú ọ̀ràn ìgbàgbọ́+ àti òtítọ́.  Nítorí náà, mo ní ìfẹ́-ọkàn pé ní ibi gbogbo, kí àwọn ọkùnrin máa bá a lọ ní gbígbàdúrà, kí wọ́n máa gbé ọwọ́ ìdúróṣinṣin sókè,+ láìsí ìrunú+ àti ọ̀rọ̀ fífà.+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, mo ní ìfẹ́-ọkàn pé kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà+ àti ìyèkooro èrò inú, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn àrà irun dídì àti wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ àrà olówó ńlá gan-an,+ 10  ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó yẹ àwọn obìnrin tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run,+ èyíinì ni, nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rere.+ 11  Kí obìnrin kẹ́kọ̀ọ́ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú ẹ̀mí ìtẹríba kíkún.+ 12  Èmi kò gba obìnrin láyè láti kọ́ni,+ tàbí láti lo ọlá àṣẹ lórí ọkùnrin,+ bí kò ṣe láti wà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́. 13  Nítorí Ádámù ni a kọ́kọ́ ṣẹ̀dá, lẹ́yìn náà Éfà.+ 14  Bákan náà, a kò tan Ádámù jẹ,+ ṣùgbọ́n obìnrin náà ni a tàn jẹ pátápátá,+ ó sì wá wà nínú ìrélànàkọjá.+ 15  Bí ó ti wu kí ó rí, a ó pa á mọ́ láìséwu nípasẹ̀ ọmọ bíbí,+ bí ó bá ṣe pé wọn ń bá a lọ nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ àti ìsọdimímọ́ pa pọ̀ pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé