Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Sámúẹ́lì 9:1-27

9  Wàyí o, ọkùnrin kan báyìí wà, ará Bẹ́ńjámínì, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Kíṣì,+ ọmọkùnrin Ábíélì, ọmọkùnrin Sérórì, ọmọkùnrin Békórátì, ọmọkùnrin Áfíà, ọmọ Bẹ́ńjámínì,+ tí ọlà rẹ̀ yamùrá.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé ó ní ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù,+ ó jẹ́ ọ̀dọ́, ó sì rẹwà, kò sì sí ọkùnrin kankan nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó rẹwà jù ú; láti èjì ká rẹ̀ sókè, ó ga ju gbogbo àwọn ènìyàn náà.+  Àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ tí ó jẹ́ ti Kíṣì baba Sọ́ọ̀lù sì sọnù. Nítorí náà, Kíṣì sọ fún Sọ́ọ̀lù ọmọkùnrin rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, mú ọ̀kan nínú àwọn ẹmẹ̀wà pẹ̀lú rẹ, kí o sì dìde, lọ, wá àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.”  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí la ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù+ kọjá, ó sì tẹ̀ síwájú la ilẹ̀ Ṣálíṣà+ kọjá, wọn kò sì rí wọn. Wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú la ilẹ̀ Ṣáálímù kọjá, ṣùgbọ́n wọn kò sí níbẹ̀. Ó sì ń tẹ̀ síwájú la ilẹ̀ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì kọjá, wọn kò sì rí wọn.  Àwọn fúnra wọn wá sí ilẹ̀ Súfì ; Sọ́ọ̀lù, ní tirẹ̀, sì sọ fún ẹmẹ̀wà rẹ̀ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Wá, sì jẹ́ kí a padà, kí baba mi má bàa jáwọ́ nínú bíbójú tó àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, kí ó sì wá máa ṣàníyàn nípa wa ní ti tòótọ́.”+  Ṣùgbọ́n ó wí fún un pé: “Wò ó, jọ̀wọ́! Ènìyàn Ọlọ́run+ kan wà ní ìlú ńlá yìí, ẹni iyì sì ni ọkùnrin náà. Gbogbo ohun tí ó bá wí ni ó ń ṣẹ láìkùnà.+ Jẹ́ kí a lọ síbẹ̀ nísinsìnyí. Bóyá ó lè sọ ọ̀nà wa tí a ó tọ̀ fún wa.”  Látàrí èyí, Sọ́ọ̀lù sọ fún ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé: “Bí àwa yóò bá sì lọ, kí ni a óò mú lọ fún ọkùnrin náà?+ nítorí pé oúnjẹ pàápàá ti di àwátì nínú àwọn kòlòbó wa, àti pé kò sí nǹkan kan láti mú lọ fún ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn.+ Kí ni ó wà pẹ̀lú wa?”  Nítorí náà, ẹmẹ̀wà náà dá Sọ́ọ̀lù lóhùn lẹ́ẹ̀kan sí i, ó sì wí pé: “Wò ó! Ìdá mẹ́rin ṣékélì+ fàdákà wà ní ọwọ́ mi, èmi yóò sì fi í fún ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́, yóò sì sọ ọ̀nà wa fún wa.”  (Ní àwọn ìgbà àtijọ́ ní Ísírẹ́lì, bí ènìyàn ṣe máa ń sọ̀rọ̀ nìyí, bí ó bá ń lọ wá Ọlọ́run: “Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ aríran.”+ Nítorí wòlíì òde òní ni a ń pè ní aríran ní àwọn ìgbà àtijọ́.) 10  Nígbà náà ni Sọ́ọ̀lù wí fún ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ dára.+ Wá, jẹ́ kí a lọ.” Wọ́n sì bá ọ̀nà wọn lọ sí ìlú ńlá náà, níbi tí ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ wà. 11  Bí wọ́n ti ń lọ sókè ní ìgòkè sí ìlú ńlá náà, àwọn fúnra wọn rí àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí ń jáde lọ láti fa omi.+ Nítorí náà, wọ́n wí fún wọn pé: “Aríran+ ha wà ní ibí yìí bí?” 12  Nígbà náà ni wọ́n dá wọn lóhùn, wọ́n sì wí pé: “Ó wà níbí. Wò ó! Ó wà níwájú yín. Ẹ ṣe wéré nísinsìnyí, nítorí pé òní ni ó wá sí ìlú ńlá yìí, nítorí ẹbọ+ wà lónìí fún àwọn ènìyàn ní ibi gíga.+ 13  Gbàrà tí ẹ bá ti wọ ìlú ńlá náà, ẹ óò rí i ní tààràtà kí ó tó gòkè lọ sí ibi gíga láti jẹun; nítorí pé àwọn ènìyàn náà kò gbọ́dọ̀ jẹun títí yóò fi dé, nítorí òun ni ẹni tí ó máa ń súre sí ẹbọ.+ Kété lẹ́yìn ìyẹn, àwọn tí a ké sí lè jẹun. Wàyí o, ẹ gòkè lọ, nítorí pé òun—nísinsìnyí gan-an ni ẹ̀yin yóò rí i.” 14  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n gòkè lọ sí ìlú ńlá náà. Bí wọ́n ti ń dé àárín ìlú ńlá náà, họ́wù, Sámúẹ́lì rèé tí ń jáde bọ̀ láti wá pàdé wọn láti gòkè lọ sí ibi gíga. 15  Ní ti Jèhófà, ó ti ṣí etí+ Sámúẹ́lì ní ọjọ́ tí ó ṣáájú ọjọ́ tí Sọ́ọ̀lù dé pé: 16  “Ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò rán ọkùnrin kan láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì+ sí ọ, kí o sì fòróró yàn+ án ṣe aṣáájú lórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì; òun yóò sì gba àwọn ènìyàn mi là kúrò lọ́wọ́ àwọn Filísínì,+ nítorí pé mo ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ àwọn ènìyàn mi níṣẹ̀ẹ́, nítorí igbe ẹkún wọn ti dé ọ̀dọ̀ mi.”+ 17  Sámúẹ́lì fúnra rẹ̀ sì rí Sọ́ọ̀lù, Jèhófà, ní tirẹ̀, sì dá a lóhùn pé: “Ọkùnrin náà rèé tí mo sọ nípa rẹ̀ fún ọ pé, ‘Òun ni ẹni tí yóò ṣèkáwọ́ àwọn ènìyàn mi.’”+ 18  Nígbà náà ni Sọ́ọ̀lù sún mọ́ Sámúẹ́lì ní àárín ẹnubodè, ó sì wí pé: “Jọ̀wọ́, sọ fún mi, Ibo gan-an ni ilé aríran wà?” 19  Sámúẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí dá Sọ́ọ̀lù lóhùn, ó sì wí pé: “Èmi ni aríran náà. Gòkè lọ ṣáájú mi sí ibi gíga, kí ẹ sì jẹun pẹ̀lú mi lónìí,+ èmi yóò sì rán yín lọ ní òwúrọ̀, gbogbo ohun tí ó sì wà ní ọkàn-àyà rẹ ni èmi yóò sọ fún ọ.+ 20  Ní ti àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí o pàdánù ní ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn,+ má ṣe jẹ́ kí ọkàn-àyà+ rẹ ṣàníyàn nípa wọn, nítorí a ti rí wọn. Ti ta sì ni gbogbo ohun tí ó fani lọ́kàn mọ́ra ní Ísírẹ́lì jẹ́?+ Kì í ha ṣe tìrẹ àti ti gbogbo ilé baba rẹ?” 21  Látàrí èyí, Sọ́ọ̀lù dáhùn, ó sì wí pé: “Èmi kì í ha ṣe ọmọ Bẹ́ńjámínì tí ó kéré jù lọ+ nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì,+ tí ìdílé mi sì jẹ́ èyí tí ìjámọ́ pàtàkì rẹ̀ kéré jù lọ nínú gbogbo ìdílé ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì?+ Nítorí náà, èé ṣe tí o fi sọ irú ohun yìí fún mi?”+ 22  Nígbà náà ni Sámúẹ́lì mú Sọ́ọ̀lù àti ẹmẹ̀wà rẹ̀, ó sì mú wọn wá sí gbọ̀ngàn ìjẹun, ó sì fún wọn ní àyè ní ipò orí+ àwọn tí a ké sí; wọ́n sì jẹ́ nǹkan bí ọgbọ̀n ọkùnrin. 23  Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì sọ fún alásè pé: “Mú ìpín tí mo fi fún ọ wá, èyí tí mo sọ fún ọ nípa rẹ̀ pé, ‘Fi í pa mọ́ sọ́dọ̀ rẹ.’” 24  Látàrí ìyẹn, alásè náà gbé ẹsẹ̀ àti ohun tí ó wà lórí rẹ̀, ó sì gbé e síwájú Sọ́ọ̀lù. Ó sì ń bá a lọ ní sísọ pé: “Ohun tí a ti fi pa mọ́ rèé. Gbé e síwájú ara rẹ. Jẹ ẹ́, nítorí wọ́n ti fi pa mọ́ dè ọ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀, kí o lè bá àwọn tí a ké sí jẹun.” Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù bá Sámúẹ́lì jẹun ní ọjọ́ yẹn. 25  Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ̀ kalẹ̀ láti ibi gíga+ náà lọ sí ìlú ńlá náà, ó sì ń bá a lọ ní bíbá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ ní orí ilé.+ 26  Lẹ́yìn náà, wọ́n dìde ní kùtùkùtù, ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ọ̀yẹ̀ là, Sámúẹ́lì tẹ̀ síwájú láti pe Sọ́ọ̀lù ní orí ilé pé: “Dìde, kí n lè rán ọ lọ.” Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù dìde, àwọn méjèèjì , òun àti Sámúẹ́lì sì jáde lọ síta. 27  Bí wọ́n ti ń sọ̀ kalẹ̀ lọ ní etí ìlú ńlá náà, Sámúẹ́lì wí fún Sọ́ọ̀lù pé: “Sọ fún ẹmẹ̀wà+ pé kí ó kọjá sí iwájú wa”—nítorí náà, ó kọjá lọ—“ní tìrẹ, dúró jẹ́ẹ́ nísinsìnyí, kí n lè jẹ́ kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé