Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Sámúẹ́lì 8:1-22

8  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Sámúẹ́lì ti darúgbó, ó yan+ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sípò gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ fún Ísírẹ́lì.  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé orúkọ ọmọkùnrin rẹ̀ àkọ́bí ni Jóẹ́lì,+ orúkọ èkejì sì ni Ábíjà;+ wọ́n ń ṣe ìdájọ́ ní Bíá-ṣébà.  Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kò sì rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀,+ ṣùgbọ́n wọ́n ní ìtẹ̀sí láti tẹ̀ lé èrè aláìbá ìdájọ́ òdodo mu,+ wọn a sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,+ wọn a sì yí ìdájọ́ po.+  Nígbà tí ó ṣe, gbogbo àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì+ kó ara wọn jọpọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ Sámúẹ́lì ní Rámà,  wọ́n sì wí fún un pé: “Wò ó! Ìwọ fúnra rẹ ti darúgbó, ṣùgbọ́n àwọn ọmọkùnrin tìrẹ kò rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ. Wàyí o, yan ọba+ sípò fún wa láti máa ṣe ìdájọ́ wa bí ti gbogbo orílẹ̀ èdè.”  Ṣùgbọ́n ohun náà burú ní ojú Sámúẹ́lì nítorí tí wọ́n wí pé: “Fún wa ní ọba láti máa ṣe ìdájọ́ wa,” Sámúẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Jèhófà.+  Nígbà náà ni Jèhófà wí fún Sámúẹ́lì pé:+ “Fetí sí ohùn àwọn ènìyàn náà ní ti gbogbo ohun tí wọ́n sọ fún ọ;+ nítorí kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, ṣùgbọ́n èmi ni wọ́n kọ̀ ní ọba+ lórí wọn.  Ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ìgbòkègbodò iṣẹ́ wọn tí wọ́n ti ṣe láti ọjọ́ tí mo ti mú wọn gòkè wá láti Íjíbítì+ títí di òní yìí, ní ti pé wọ́n ń bá a nìṣó ní fífi mí sílẹ̀,+ wọ́n sì ń sin àwọn ọlọ́run mìíràn,+ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí ọ pẹ̀lú.  Wàyí o, fetí sí ohùn wọn. Àyàfi èyí, pé kí o kìlọ̀ fún wọn lọ́nà tí ń múni ronú jinlẹ̀, kí o sì sọ fún wọn nípa ohun tí ó tọ́ sí ọba tí yóò jẹ lé wọn lórí.”+ 10  Nítorí náà, Sámúẹ́lì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà fún àwọn ènìyàn tí ń béèrè fún ọba lọ́wọ́ rẹ̀. 11  Ó sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Èyí ni yóò jẹ́ ohun tí ó tọ́ sí+ ọba tí yóò jẹ lé yín lórí: Òun yóò mú àwọn ọmọkùnrin yín,+ yóò sì fi wọ́n sínú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀+ àti sára àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀+ gẹ́gẹ́ bí tirẹ̀, àwọn kan yóò sì ní láti máa sáré níwájú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀;+ 12  yóò sì yan àwọn olórí lórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún+ àti àwọn olórí lórí àràádọ́ta+ sípò fún ara rẹ̀, àti àwọn kan láti máa túlẹ̀ rẹ̀+ àti láti máa kárúgbìn ìkórè rẹ̀+ àti láti máa ṣe àwọn ohun èlò ogun rẹ̀+ àti àwọn ohun èlò kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀.+ 13  Òun yóò sì mú àwọn ọmọbìnrin yín ṣe olùpo òróró ìkunra àti alásè àti olùṣe búrẹ́dì.+ 14  Òun yóò sì gba àwọn pápá yín àti àwọn ọgbà àjàrà yín+ àti àwọn oko ólífì yín,+ àwọn tí ó dára jù lọ, yóò sì fi wọ́n fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ti tòótọ́. 15  Òun yóò sì gba ìdá mẹ́wàá+ láti inú àwọn pápá irúgbìn yín àti nínú àwọn ọgbà àjàrà yín, dájúdájú, òun yóò sì fi wọ́n fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ láàfin+ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. 16  Òun yóò sì gba àwọn ìránṣẹ́kùnrin yín àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin yín àti àwọn ọ̀wọ́ ẹran yín tí ó dára jù lọ, àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín, òun yóò sì máa lò wọ́n fún iṣẹ́ rẹ̀.+ 17  Òun yóò gba ìdá mẹ́wàá nínú agbo ẹran yín,+ ẹ̀yin fúnra yín yóò sì di tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́. 18  Dájúdájú, ẹ̀yin yóò sì ké jáde ní ọjọ́ yẹn nítorí ọba yín,+ ẹni tí ẹ̀yin ti yàn fún ara yín, ṣùgbọ́n Jèhófà kì yóò dá yín lóhùn ní ọjọ́ yẹn.”+ 19  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ènìyàn náà kọ̀ láti fetí sí ohùn Sámúẹ́lì,+ wọ́n sì wí pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n ọba ni yóò wá wà lórí wa. 20  Àwa, àwa pẹ̀lú, yóò sì dà bí gbogbo orílẹ̀-èdè,+ ọba wa yóò sì máa ṣe ìdájọ́ wa, yóò sì máa jáde lọ níwájú wa, yóò sì máa ja àwọn ìjà ogun wa.” 21  Sámúẹ́lì sì tẹ́tí sí gbogbo ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn náà; nígbà náà ni ó sọ wọ́n ní etí Jèhófà.+ 22  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Fetí sí ohùn wọn, kí o sì mú kí ọba jẹ fún wọn.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Sámúẹ́lì sọ fún àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì pé: “Kí olúkúlùkù máa lọ sí ìlú ńlá rẹ̀.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé