Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Sámúẹ́lì 7:1-17

7  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ọkùnrin Kiriati-jéárímù+ wá, wọ́n sì gbé àpótí Jèhófà gòkè wá, wọ́n sì gbé e lọ sí ilé Ábínádábù+ tí ó wà lórí òkè kékeré, Élíásárì ọmọkùnrin rẹ̀ sì ni ẹni tí a sọ di mímọ́ láti ṣọ́ àpótí Jèhófà.  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, láti ọjọ́ tí Àpótí fi ń gbé ní Kiriati-jéárímù, àwọn ọjọ́ náà ń di púpọ̀ sí i, tí wọ́n fi wá jẹ́ ogún ọdún, gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣèdárò tọ Jèhófà lẹ́yìn.+  Sámúẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún gbogbo ilé Ísírẹ́lì pé: “Bí ó bá jẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà yín ni ẹ fi ń padà sọ́dọ̀ Jèhófà,+ ẹ mú àwọn ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè kúrò ní àárín yín+ àti àwọn ère Áṣítórétì+ pẹ̀lú, kí ẹ sì darí ọkàn-àyà yín sọ́dọ̀ Jèhófà láìyà bàrá, kí ẹ sì máa sin òun nìkan ṣoṣo,+ yóò sì dá yín nídè kúrò ní ọwọ́ àwọn Filísínì.”+  Látàrí ìyẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú àwọn Báálì+ àti ère Áṣítórétì+ kúrò, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sin Jèhófà nìkan ṣoṣo.  Nígbà náà ni Sámúẹ́lì wí pé: “Kó gbogbo Ísírẹ́lì+ jọpọ̀ sí Mísípà,+ kí n lè gbàdúrà+ nítorí yín sí Jèhófà.”  Nítorí náà, a kó wọn jọpọ̀ sí Mísípà, wọ́n sì ń fa omi, wọ́n sì ń dà á jáde níwájú Jèhófà, wọ́n sì gba ààwẹ̀ ní ọjọ́ yẹn.+ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ níbẹ̀ pé: “Àwa ti dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà.”+ Sámúẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìdájọ́+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Mísípà.  Àwọn Filísínì sì wá gbọ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti kó ara wọn jọpọ̀ sí Mísípà, àwọn olúwa alájùmọ̀ṣepọ̀+ àwọn Filísínì sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n gòkè lọ gbéjà ko Ísírẹ́lì. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́, àyà bẹ̀rẹ̀ sí fò wọ́n ní tìtorí àwọn Filísínì.+  Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí fún Sámúẹ́lì pé: “Má ṣe dákẹ́ nítorí wa ní kíké pe Jèhófà Ọlọ́run wa fún ìrànlọ́wọ́,+ kí ó lè gbà wá là kúrò ní ọwọ́ àwọn Filísínì.”  Nígbà náà ni Sámúẹ́lì mú ọ̀dọ́ àgùntàn kan tí ń mu ọmú, ó sì fi í rúbọ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun, odindi ọrẹ ẹbọ,+ sí Jèhófà; Sámúẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ nítorí Ísírẹ́lì,+ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí dá a lóhùn.+ 10  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí Sámúẹ́lì ń rú ọrẹ ẹbọ sísun náà, àwọn Filísínì sún mọ́ tòsí fún ìjà ogun lòdì sí Ísírẹ́lì. Jèhófà sì mú kí ààrá sán wàyí pẹ̀lú ariwo+ dídún ròkè lu àwọn Filísínì ní ọjọ́ yẹn, kí ó lè kó wọn sínú ìdàrúdàpọ̀;+ a sì ṣẹ́gun wọn níwájú Ísírẹ́lì.+ 11  Látàrí ìyẹn, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì jáde ogun láti Mísípà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn Filísínì, wọ́n sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣá wọn balẹ̀ títí dé gúúsù Bẹti-kárì. 12  Nígbà náà ni Sámúẹ́lì gbé òkúta kan,+ ó sì gbé e kalẹ̀ láàárín Mísípà àti Jẹ́ṣánà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ rẹ̀ ní Ẹbinísà. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó sọ pé: “Jèhófà ti ràn wá lọ́wọ́ títí di ìsinsìnyí.”+ 13  Bí a ṣe tẹ àwọn Filísínì lórí ba nìyẹn, wọn kò sì wá sínú ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì+ mọ́ rárá; ọwọ́ Jèhófà sì ń bá a lọ láti wà lòdì sí àwọn Filísínì ní gbogbo ọjọ́ Sámúẹ́lì.+ 14  Àwọn ìlú ńlá tí àwọn Filísínì ti gbà lọ́wọ́ Ísírẹ́lì sì ń padà sọ́wọ́ Ísírẹ́lì láti Ékírónì títí dé Gátì, Ísírẹ́lì sì dá ìpínlẹ̀ wọn nídè kúrò ní ọwọ́ àwọn Filísínì. Àlàáfíà sì wá wà láàárín Ísírẹ́lì àti àwọn Ámórì.+ 15  Sámúẹ́lì sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.+ 16  Ó sì ń rin ìrìn àjò láti ọdún dé ọdún, ó sì lọ yí ká Bẹ́tẹ́lì+ àti Gílígálì+ àti Mísípà,+ ó sì ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì+ ní gbogbo ibi wọ̀nyí. 17  Ṣùgbọ́n pípadà rẹ̀ jẹ́ sí Rámà,+ nítorí pé ibẹ̀ ni ilé rẹ̀ wà, ibẹ̀ ni ó sì ti ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mọ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Jèhófà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé